Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 1

“Ẹ Lọ, Kí Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn . . . Di Ọmọ Ẹ̀yìn”

“Ẹ Lọ, Kí Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn . . . Di Ọmọ Ẹ̀yìn”

Àkópọ̀ àwọn ohun tó wà nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì àti bó ṣe bá àkókò wa mu

1-6. Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé kò sípò táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà tí wọn ò ti lè wàásù.

 Ọ̀DỌ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà lórílẹ̀-èdè Gánà tó ń jẹ́ Rebecca, ó gbà pé ara àwọn tó yẹn kóun wàásù fún ni àwọn ọmọléèwé òun. Gbogbo ìgbà làwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì máa ń wà nínú báàgì tó ń gbé lọ síléèwé. Lákòókò oúnjẹ ọ̀sán, ó máa ń wá ẹni tó máa wàásù fún lára àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọléèwé. Ní báyìí, Rebecca ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ díẹ̀ lára wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

2 Ní Madagásíkà tó jẹ́ erékùṣù kan ní gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì kan máa ń rin nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) nínú oòrùn tó mú gan-an lọ sí abúlé kan tó wà ní àdádó. Wọ́n máa ń lọ síbẹ̀ kí wọ́n lè kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

3 Ó wu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Paraguay àtàwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún míì pé kí wọ́n lọ wàásù fáwọn èèyàn tó ń gbé ní etídò Paraguay àti Paraná, àmọ́ kò rọrùn fún wọn láti débẹ̀. Torí náà, wọ́n ṣe ọkọ̀ ojú omi kan tó lè gba èèyàn méjìlá. Inú ọkọ̀ náà làwọn akéde yìí tí ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn tó wà láwọn àgbègbè tó ṣòro láti dé yẹn.

4 Àwọn arìnrìn-àjò sábà máa ń wá sí Alaska tó wà ní ìkángun Àríwá Amẹ́ríkà nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, torí náà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lo àǹfààní yìí láti wàásù fún wọn. Nígbà táwọn ọkọ̀ òkun bá kó àwọn àlejò tó wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè débẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá sí èbúté láti pàdé wọn. Wọ́n máa ń kó àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì sọ́wọ́ ní oríṣiríṣi èdè, kó lè fa àwọn èèyàn mọ́ra. Lágbègbè yẹn kan náà, àwọn ará máa ń wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ sáwọn abúlé tó wà ní àdádó, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún wọ́n láti máa wàásù ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Aleut, Athabascan, Tsimshian àti Tlingit.

5 Larry tó ń gbé ní Texas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó jẹ́ àkànṣe, ìyẹn ibi tó ti ń gbàtọ́jú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé orí kẹ̀kẹ́ arọ ni Larry máa ń wà torí jàǹbá tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó ṣì máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Ó máa ń ṣàlàyé ìlérí tó wà nínú Bíbélì, tó jẹ́ kóun ní ìgbàgbọ́ pé nínú Ìjọba Ọlọ́run, òun máa fẹsẹ̀ òun rìn lẹ́ẹ̀kàn sí i.​—Àìsá. 35:5, 6.

6 Kí àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lè lọ sí àpéjọ kan ní àríwá orílẹ̀-èdè Myanmar, ọjọ́ mẹ́ta ni wọ́n fi rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ ojú omi láti ìlú Mandalay. Torí pé wọ́n nítara fún iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n máa ń kó àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì dání kí wọ́n lè fún àwọn tí wọ́n bá wàásù fún nínú ọkọ̀ ojú omi. Ní gbogbo ìgbà tí ọkọ̀ ojú omi náà bá dúró ní ìlú tàbí abúlé kan láti já èrò, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn máa ń sọ̀ kalẹ̀, kí wọ́n lè fún àwọn tó wà ní ìlú tàbí abúlé náà láwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì. Nígbà tí wọ́n bá fi máa pa dà sínú ọkọ̀ náà, àwọn èrò míì á ti wọlé, ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n rí àwọn míì wàásù fún.

7. Oríṣiríṣi ọ̀nà wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, kí ni wọ́n sì pinnu láti ṣe?

7 Bá a ṣe rí i nínú àwọn àpẹẹrẹ yìí, kárí ayé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fìtara “jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run.” (Ìṣe 28:23) Wọ́n ń wàásù fáwọn èèyàn láti ilé dé ilé, lójú ọ̀nà àti lórí fóònù. Bóyá inú ọkọ̀ ni wọ́n wà, tàbí inú ọgbà ìtura, tàbí lákòókò oúnjẹ níbi iṣẹ́, gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń múra tán láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Òótọ́ ni pé ọ̀nà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà wàásù lè yàtọ̀ síra, síbẹ̀ ohun kan náà ni gbogbo wọn pinnu láti ṣe, ìyẹn ni pé kí wọ́n wàásù fáwọn èèyàn níbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí wọn.​—Mát. 10:11.

8, 9. (a) Kí nìdí tó fi lè yani lẹ́nu pé iṣẹ́ ìwàásù náà ń tẹ̀ síwájú? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò, báwo la sì ṣe lè rí ìdáhùn ìbéèrè náà?

8 Ṣé ìwọ náà wà lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní orílẹ̀-èdè tó ju igba ó lé márùndínlógójì (235) báyìí? Tó o bá wà lára wọn, a jẹ́ pé ìwọ náà ń kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tó ń gbòòrò kárí ayé nìyẹn! Ó yani lẹ́nu gan-an bá a ṣe ń rí i tí iṣẹ́ ìwàásù náà ń tẹ̀ síwájú kárí ayé. Oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn ti ṣe sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti dí wa lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí, wọ́n ń ṣenúnibíni sí wa, wọ́n ń ta kò wá, àwọn ìjọba sì ń fòfin de iṣẹ́ wa. Síbẹ̀, a ò jẹ́ kíyẹn dí wa lọ́wọ́ láti máa jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.

9 Ìbéèrè kan ni pé: Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run fi ń tẹ̀ síwájú láìka ọ̀pọ̀ ìdíwọ́ tàbí àtakò látọ̀dọ̀ Sátánì? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni. Ó ṣe tán, iṣẹ́ ìwàásù tó bẹ̀rẹ̀ nígbà yẹn làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń ṣe lónìí.

Iṣẹ́ Tó Kárí Ayé

10. Iṣẹ́ wo ni Jésù lo gbogbo okun rẹ̀ láti ṣe, kí ló sì mọ̀ nípa iṣẹ́ náà?

10 Jésù Kristi tó dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ lo gbogbo okun rẹ̀ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, kódà iṣẹ́ yìí ló kà sí pàtàkì jù lọ ní gbogbo àkókò tó lò láyé. Ìgbà kan wà tó sọ pé: “Mo tún gbọ́dọ̀ kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run . . . , torí pé nítorí èyí la ṣe rán mi.” (Lúùkù 4:43) Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù, ó mọ̀ pé òun ò ní lè parí iṣẹ́ náà. Nígbà tó ku díẹ̀ kó kú, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run “ní gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10) Àmọ́, báwo la ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà, àwọn wo ló sì máa ṣe é?

“Ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”​—Mátíù 28:19

11. Iṣẹ́ pàtàkì wo ni Jésù gbé lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́, báwo ni wọ́n sì ṣe máa rí ìtìlẹyìn gbà kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ náà?

11 Lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde, ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì gbé iṣẹ́ pàtàkì kan lé wọn lọ́wọ́. Ó sọ fún wọn pé: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́. Ẹ wò ó! Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:19, 20) Ọ̀rọ̀ náà, “mo wà pẹ̀lú yín” fi hàn pé Jésù á máa ṣètìlẹyìn fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dí ọmọ ẹ̀yìn. Wọ́n máa nílò irú ìtìlẹyìn bẹ́ẹ̀, torí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ‘gbogbo orílẹ̀-èdè máa kórìíra wọn.’ (Mát. 24:9) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tún lè rí ìtìlẹyìn gbà lọ́nà míì. Kí Jésù tó lọ sọ́run, ó sọ fún wọn pé ẹ̀mí mímọ́ máa fún wọn lágbára kí wọ́n lè jẹ́ ẹlẹ́rìí òun “títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”​—Ìṣe 1:8.

12. Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ ká gbé yẹ̀wò, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè náà?

12 Ó yẹ ká gbé àwọn ìbéèrè pàtàkì kan yẹ̀wò: Ṣé àwọn àpọ́sítélì Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́? Ṣé àwùjọ àwọn Kristẹni kéréje lọ́kùnrin àti lóbìnrin yẹn jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run, kódà nígbà tí wọ́n dojú kọ inúnibíni tó le gan-an? Ṣóòótọ́ ni Ọlọ́run tì wọ́n lẹ́yìn, tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ò sì fi wọ́n sílẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn míì tó fara jọ wọ́n nínú ìwé Ìṣe. Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Kí nìdí? Jésù ṣèlérí pé iṣẹ́ tóun gbé lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lọ́wọ́ á máa bá a lọ “títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” Torí náà, iṣẹ́ tó kan gbogbo Kristẹni tòótọ́ ni, tó fi mọ́ àwa tá à ń gbé ní àkókò òpin yìí. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká ṣàyẹ̀wò ìtàn tó wà nínú ìwé Ìṣe.

Àkópọ̀ Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣe

13, 14. (a) Ta ló kọ ìwé Ìṣe, ibo ló sì ti rí àwọn nǹkan tó kọ? (b) Kí ló wà nínú ìwé Ìṣe?

13 Ta ló kọ ìwé Ìṣe? Ìwé Ìṣe ò sọ orúkọ ẹni tó kọ ọ̀, àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ìwé náà mú kó ṣe kedere pé ẹni tó kọ ọ́ náà ló kọ ìwé Ìhìn Rere Lúùkù. (Lúùkù 1:1-4; Ìṣe 1:1, 2) Torí náà, ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti gbà pé Lúùkù “oníṣègùn tó jẹ́ olùfẹ́,” tó máa ń fara balẹ̀ ṣèròyìn, ló kọ ìwé Ìṣe. (Kól. 4:14) Ìtàn ohun tó wáyé láàárín nǹkan bí ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ló wà nínú ìwé Ìṣe, ìyẹn látìgbà tí Jésù ti lọ sọ́run lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni títí di nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣẹ̀wọ̀n nílùú Róòmù. Nínú àwọn ìtàn tí Lúùkù sọ, ó lo ọ̀rọ̀ náà “wọ́n” láwọn ibì kan, ó sì lò “a” láwọn ibòmíì, èyí lè mú ká ronú pé ọ̀pọ̀ lára ohun tó kọ ló ṣojú ẹ̀. (Ìṣe 16:8-10; 20:5; 27:1) Ẹni tó máa ń fara balẹ̀ ṣèwádìí ni Lúùkù, torí náà ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹnu Pọ́ọ̀lù, Bánábà, Fílípì àtàwọn míì tó mẹ́nu kàn nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀ ló ti gbọ́ àwọn nǹkan tó kọ.

14 Kí ló wà nínú ìwé Ìṣe? Lúùkù ti kọ́kọ́ kọ̀wé nípa àwọn nǹkan tí Jésù sọ àtohun tó ṣe nínú ìwé Ìhìn Rere tó kọ. Àmọ́, nínú ìwé Ìṣe, Lúùkù ròyìn ohun táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù sọ àtohun tí wọ́n ṣe. Torí náà, ọ̀rọ̀ inú ìwé Ìṣe dá lórí àwọn ọmọlẹ́yìn tó ṣe àwọn iṣẹ́ àgbàyanu, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni tí ‘ò kàwé àti gbáàtúù’ làwọn èèyàn kà wọ́n sí. (Ìṣe 4:13) Ní kúkúrú, ohun tó wà nínú àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí ni bí ìjọ Kristẹni ṣe bẹ̀rẹ̀ àti bó ṣe ń tẹ̀ síwájú. Ìwé Ìṣe jẹ́ ká mọ ọ̀nà táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gbà wàásù àti ọwọ́ tí wọ́n fi mú iṣẹ́ náà. (Ìṣe 4:31; 5:42) Ó jẹ́ ká mọ bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere náà délé dóko. (Ìṣe 8:29, 39, 40; 13:1-3; 16:6; 18:24, 25) Ìwé Ìṣe tún tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì, ìyẹn ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi máa jẹ́ ọba rẹ̀, ó sì jẹ́ ká rí bí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń tàn kálẹ̀ lójú àtakò tó le koko.​—Ìṣe 8:12; 19:8; 28:30, 31.

15. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà jàǹfààní tá a bá ń ṣàyẹ̀wò ìwé Ìṣe?

15 Tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ìwé Ìṣe, ó dájú pé ó máa múnú wa dùn, ó sì máa fún ìgbàgbọ́ wa lókun! Tá a bá sì ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n jẹ́ onítara, tí wọ́n sì fìgboyà sin Jèhófà, ó máa wù wá láti fara wé ìgbàgbọ́ wọn. Ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ gbára dì láti parí iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́ pé “ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.” Ńṣe la dìídì ṣe ìwé tó ò ń kà yìí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìṣe.

Ìwé Yìí Á Jẹ́ Kó Túbọ̀ Rọrùn fún Ẹ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

16. Kí nìdí pàtàkì mẹ́ta tá a torí ẹ̀ ṣe ìwé yìí?

16 Kí nìdí tá a fi ṣe ìwé yìí? Ìdí pàtàkì mẹ́ta ni: (1) kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, (2) kó lè mú kí ìtara tá a ní fún iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ máa pọ̀ sí i bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò àpẹẹrẹ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àti (3) ká lè túbọ̀ mọyì ètò Jèhófà, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tó ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù àti nínú ìjọ.

17, 18. Báwo la ṣe ṣètò àwọn ohun tó wà nínú ìwé yìí, àwọn apá wo nínú ìwé náà ló sì máa mú kó túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

17 Báwo la ṣe ṣètò àwọn ohun tó wà nínú ìwé yìí? Wàá rí i pé apá mẹ́jọ la pín in sí, apá kọ̀ọ̀kan sì ṣàlàyé àwọn ibì kan nínú ìwé Ìṣe. Nínú ìwé yìí, a ò jíròrò àwọn ẹsẹ tó wà nínú ìwé Ìṣe ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la fa àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ látinú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú ìwé Bíbélì náà yọ, kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí bá a ṣe lè fáwọn ẹ̀kọ́ náà sílò nígbèésí ayé wa. Ní ìbẹ̀rẹ̀ orí kọ̀ọ̀kan, wàá rí àlàyé ṣókí nípa ohun tí orí náà dá lé àti ibi tá a ti mú ọ̀rọ̀ tó wá nínú orí náà jáde nínú ìwé Ìṣe.

18 Àwọn apá míì tún wà nínú ìwé yìí tó máa mú kó túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó o ṣe ń ronú lórí àkọsílẹ̀ Bíbélì tó wà nínú ìwé Ìṣe, wàá rí àwọn àwòrán mèremère tó ṣàlàyé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó fani mọ́ra náà, èyí sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fojú inú yàwòrán ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn orí náà ló ní àwọn àpótí tá a kọ àfikún ìsọfúnni sí. Nínú àwọn àpótí kan, wàá rí ìtàn nípa àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, kó o lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn. Àwọn àpótí míì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti wáyé, àṣà, tàbí àwọn èèyàn míì tí ìwé Ìṣe sọ̀rọ̀ nípa wọn. Àwọn àlàfo fífẹ̀ wà létí ìwé yìí tó o lè máa kọ nǹkan sí bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́.

Ẹ máa ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín lọ́nà tó fi hàn pé ẹ gbà pé ó yẹ ká ṣe iṣẹ́ náà ní kíákíá

19. Ọ̀nà wo la lè gbà máa yẹ ara wa wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?

19 Ìwé yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa yẹ ara rẹ wò. Bó ti wù kó pẹ́ tó tó o ti di akéde Ìjọba Ọlọ́run, á dáa kó o máa yẹ ara ẹ wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kó o sì máa ronú lórí ohun tó o kà sí pàtàkì jù nígbèésí ayé rẹ àti ọwọ́ tó o fi mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. (2 Kọ́r. 13:5) Bí ara ẹ pé: ‘Ṣé ọwọ́ tí mo fi mú iṣẹ́ ìwàásù fi hàn pé mo kà iṣẹ́ náà sí iṣẹ́ tó yẹ ká ṣe ní kíákíá? (1 Kọ́r. 7:29-31) Ṣé mo máa ń lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ṣé mo sì máa ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ohun tí mò ń sọ dá mi lójú? (1 Tẹs. 1:5, 6) Ṣé mo máa ń lo àkókò tó pọ̀ tó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dí ọmọ ẹ̀yìn?’​—Kól. 3:23.

20, 21. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe iṣẹ́ ìwàásù ní kíákíá, kí ló sì yẹ ká pinnu láti ṣe?

20 Ẹ jẹ́ ká máa rántí ní gbogbo ìgbà pé Jésù ti gbé iṣẹ́ pàtàkì kan lé wa lọ́wọ́, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a túbọ̀ ń rí ìdí tó fi yẹn ká ṣe iṣẹ́ náà ní kíákíá. Òpin ètò àwọn nǹkan yìí túbọ̀ ń sún mọ́lé. Kò tíì sígbà tí ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn wà nínú ewu bíi ti àsìkò wa yìí. A ò mọ iye àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ṣì máa gbọ́ ìhìn rere náà. (Ìṣe 13:48) Àmọ́ ojúṣe wa ni pé ká ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kó tó pẹ́ jù.​—1 Tím. 4:16.

21 Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká fara wé àpẹẹrẹ àwọn tó fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Bó o ṣe ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí, ǹjẹ́ kí ìwọ náà túbọ̀ máa lo ìtara àti ìgboyà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kó o sì lè dúró lórí ìpinnu rẹ pé wàá máa bá a lọ láti máa “jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run.”​—Ìṣe 28:23.