ORÍ 11
Wọ́n ní “Ìdùnnú àti Ẹ̀mí Mímọ́ ní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́”
Ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà táwọn èèyàn ta kò ó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù
Ó dá lórí Ìṣe 13:1-52
1, 2. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìrìn àjò tí Bánábà àti Sọ́ọ̀lù fẹ́ rìn, báwo ni iṣẹ́ wọn sì ṣe máa mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Ìṣe 1:8 ṣẹ?
ỌJỌ́ ayọ̀ lọjọ́ náà jẹ́ fáwọn ará ìjọ tó wà ní Áńtíókù. Nínú gbogbo àwọn wòlíì àtàwọn olùkọ́ tó wà níbẹ̀, Bánábà àti Sọ́ọ̀lù ni ẹ̀mí mímọ́ yàn láti mú ìhìn rere lọ sáwọn ibi tó jìnnà. a (Ìṣe 13:1, 2) Òótọ́ ni pé wọ́n ti rán àwọn ọkùnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn jáde lọ sáwọn ibì kan ṣáájú ìgbà yẹn, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára ibi tí wọ́n rán wọn lọ làwọn Kristẹni ti wà. (Ìṣe 8:14; 11:22) Ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n máa rán Bánábà àti Sọ́ọ̀lù lọ sáwọn ilẹ̀ tí ìhìn rere ò tíì dé, Jòhánù tó tún jẹ́ Máàkù máa wà pẹ̀lú wọn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́.
2 Ní nǹkan bí ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, Jésù ti sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Ní báyìí tí wọ́n ti yan Bánábà àti Sọ́ọ̀lù láti jẹ́ míṣọ́nnárì, ìyẹn máa mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yẹn ṣẹ! b
‘Ẹ Yà Wọ́n Sọ́tọ̀ Kí Wọ́n Lè Ṣe Iṣẹ́ Tí Mo Pè Wọ́n Sí’ (Ìṣe 13:1-12)
3. Kí ló mú kó ṣòro láti rìnrìn àjò lọ sí ọ̀nà jíjìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?
3 Lóde òní, ó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti rìnrìn àjò lọ síbi tó jìn láàárín wákàtí kan sí méjì nítorí àwọn ohun ìrìnnà bíi mọ́tò àti ọkọ̀ òfúrufú. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Nígbà yẹn, ẹsẹ̀ lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń rìnrìn àjò láwọn ojú ọ̀nà tó rí gbágungbàgun. Èèyàn lè fi odindi ọjọ́ kan rin ìrìn ọgbọ̀n (30) kìlómítà, ìrìn náà sì máa ń tánni lókun! c Torí náà, bí Bánábà àti Sọ́ọ̀lù ṣe ń fayọ̀ retí iṣẹ́ wọn tuntun yìí, ó dájú pé wọ́n á tún máa ronú pé àwọn gbọ́dọ̀ sapá gidigidi, àwọn sì máa ní láti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan.—Mát. 16:24.
4. (a) Kí ló darí àwọn tó yan Bánábà àti Sọ́ọ̀lù, ojú wo sì làwọn onígbàgbọ́ yòókù fi wo bí wọ́n ṣe yàn wọ́n? (b) Báwo la ṣe lè máa ṣètìlẹyìn fáwọn tó bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ?
4 Àmọ́, kí nìdí tí ẹ̀mí mímọ́ fi dìídì sọ pé kí wọ́n ‘ya Bánábà àti Sọ́ọ̀lù sọ́tọ̀ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run pè wọ́n sí’? (Ìṣe 13:2) Bíbélì ò sọ fún wa. Ohun tá a mọ̀ ni pé ẹ̀mí mímọ́ ló ní kí wọ́n yan àwọn ọkùnrin náà. Kò sì sóhun tó fi hàn pé àwọn wòlíì àtàwọn olùkọ́ tó wà ní Áńtíókù ta ko ìpinnu yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ṣètìlẹyìn fáwọn ọkùnrin náà. Fojú inú wo bọ́rọ̀ náà ṣe máa rí lára Bánábà àti Sọ́ọ̀lù báwọn arákùnrin wọn ṣe ‘gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, tí wọ́n sì rán wọn lọ’ láìsí pé wọ́n ń jowú wọn. (Ìṣe 13:3) Àwa náà gbọ́dọ̀ máa ṣètìlẹyìn fáwọn tó bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ, títí kan àwọn tá a yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó. Dípò tí àá fi máa jowú àwọn tó nírú àǹfààní bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa “kà wọ́n sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.”—1 Tẹs. 5:13.
5. Báwo ni Bánábà àti Sọ́ọ̀lù ṣe wàásù ìhìn rere ní erékùṣù Sápírọ́sì?
5 Lẹ́yìn tí wọ́n ti fẹsẹ̀ rìn dé Séléúkíà, ìyẹn èbúté kan nítòsí Áńtíókù, Bánábà àti Sọ́ọ̀lù wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí erékùṣù Sápírọ́sì, èyí tó jẹ́ nǹkan bí ìrìn àjò ọgọ́rùn-ún méjì (200) kìlómítà. d Ọmọ ìbílẹ̀ Sápírọ́sì ni Bánábà, torí náà inú ẹ̀ dùn gan-an pé ó láǹfààní láti wàásù ìhìn rere fáwọn ará ìlú ẹ̀. Bánábà àti Sọ́ọ̀lù ò fàkókò ṣòfò nígbà tí wọ́n dé Sálámísì, tó jẹ́ èbúté kan ní ìlà oòrùn erékùṣù náà. Ojú ẹsẹ̀ ni “wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú àwọn sínágọ́gù àwọn Júù.” e (Ìṣe 13:5) Bánábà àti Sọ́ọ̀lù rìnrìn àjò dé gbogbo erékùṣù tó wà ní Sápírọ́sì, ó sì jọ pé wọ́n ń wàásù láwọn ìlú tó wà lójú ọ̀nà bí wọ́n ṣe ń lọ. Ó ṣeé ṣe kíyẹn mú kí wọ́n rin ìrìn nǹkan bí ọgọ́jọ (160) kìlómítà.
6, 7. (a) Ta ni Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, kí nìdí tí Baa-Jésù sì fi gbìyànjú láti dí i lọ́wọ́ kó má bàa fetí sí ìhìn rere? (b) Báwo ni Sọ́ọ̀lù ṣe paná àtakò Baa-Jésù?
6 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ẹ̀sìn èké lọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní erékùṣù Sápírọ́sì ń ṣe. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn nígbà tí Bánábà àti Sọ́ọ̀lù dé Páfò tó wà létíkun ìwọ̀ oòrùn erékùṣù náà. Wọ́n rí ọkùnrin kan tí wọ́n ń pè ní “Baa-Jésù” níbẹ̀. ‘Oníṣẹ́ oṣó àti wòlíì èké ni. Ó wà pẹ̀lú Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì tó jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀, tó sì jẹ́ ọkùnrin onílàákàyè.’ f Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ará Róòmù tó jẹ́ ọ̀mọ̀ràn títí kan àwọn “ọkùnrin onílàákàyè” bíi Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, sábà máa ń lọ woṣẹ́ lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́ oṣó tàbí awòràwọ̀ kí wọ́n tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Àmọ́, ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run wọ Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì lọ́kàn, ‘ara rẹ̀ sì ti wà lọ́nà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’ Inú Baa-Jésù ò dùn rárá bó ṣe rí i pé Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere. Élímà ni orúkọ oyè Baa-Jésù, ìtumọ̀ rẹ̀ sì ni “Oníṣẹ́ oṣó.”—Ìṣe 13:6-8.
7 Baa-Jésù ta ko ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Òun ni agbaninímọ̀ràn Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, ó sì gbà pé tóun ò bá fẹ́ kí ipò náà bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́, òun ní láti “yí alákòóso ìbílẹ̀ náà kúrò nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́.” (Ìṣe 13:8) Àmọ́, Sọ́ọ̀lù ò fẹ́ lajú ẹ̀ sílẹ̀ kí oníṣẹ́ oṣó kan wá yí Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì lọ́kàn pa dà. Kí ni Sọ́ọ̀lù wá ṣe? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ni Sọ́ọ̀lù, tí wọ́n tún ń pè ní Pọ́ọ̀lù, ẹni tó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, bá tẹjú mọ́ ọn [Baa-Jésù], ó sì sọ pé: ‘Ìwọ ọkùnrin tí oríṣiríṣi jìbìtì àti ìwà ibi kún ọwọ́ rẹ̀, ìwọ ọmọ Èṣù, ìwọ ọ̀tá gbogbo ohun tó jẹ́ òdodo, ṣé o kò ní ṣíwọ́ yíyí àwọn ọ̀nà títọ́ Jèhófà po ni? Wò ó! Ọwọ́ Jèhófà wà lára rẹ, wàá fọ́ lójú, o ò ní rí ìmọ́lẹ̀ oòrùn fún àkókò kan.’ Lójú ẹsẹ̀, kùrukùru tó ṣú àti òkùnkùn bò ó, ó sì ń táràrà, ó ń wá ẹni tó máa di òun lọ́wọ́ mú lọ.” g Kí ni Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì wá ṣe? “Bí alákòóso ìbílẹ̀ náà ṣe rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó di onígbàgbọ́, torí ẹ̀kọ́ Jèhófà yà á lẹ́nu gan-an.”—Ìṣe 13:9-12.
8. Báwo la ṣe lè jẹ́ onígboyà bíi ti Pọ́ọ̀lù lóde òní?
8 Pọ́ọ̀lù ò bẹ̀rù Baa-Jésù. Bákan náà, kò yẹ káwa náà bẹ̀rù nígbà táwọn alátakò bá fẹ́ bomi paná ìgbàgbọ́ àwọn tó fẹ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ o, ó yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa “máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure, tí iyọ̀ dùn.” (Kól. 4:6) Síbẹ̀, kò yẹ ká torí pé ká má bàa mú àwọn èèyàn bínú ká wá máa fà sẹ́yìn láti wàásù fáwọn tó fẹ́ mọ̀ nípa Jèhófà. Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìbẹ̀rù mú ká fà sẹ́yìn láti tú àṣírí ẹ̀sìn èké tó ń bá a lọ láti máa “yí àwọn ọ̀nà títọ́ Jèhófà po” bíi ti Baa-Jésù. (Ìṣe 13:10) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ káwa náà máa ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù, ká máa fìgboyà wàásù fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà. Lónìí, Jèhófà lè má fún wa lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bíi ti Pọ́ọ̀lù, síbẹ̀ ó dá wa lójú pé Jèhófà máa lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti fa àwọn ẹni yíyẹ wá sínú òtítọ́.—Jòh. 6:44.
“Ọ̀rọ̀ Ìṣírí” (Ìṣe 13:13-43)
9. Báwo ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ Kristẹni lóde òní?
9 Ó dájú pé ohun kan yí pa dà nígbà táwọn ọkùnrin náà kúrò ní Páfò, tí wọ́n sì wọ ọkọ̀ òkun lọ sí Pẹ́gà ní etíkun Éṣíà Kékeré, èyí tó jẹ́ ìrìn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ó lé àádọ́ta (250) kìlómítà lójú òkun. Nínú Ìṣe 13:13, wọ́n pe àwùjọ náà ní “Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù ló ń múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn náà. Àmọ́ o, kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé Bánábà jowú Pọ́ọ̀lù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn ọkùnrin náà ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Àpẹẹrẹ rere ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà jẹ́ fáwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ Kristẹni lónìí. Dípò káwọn Kristẹni máa wá ipò ọlá, ńṣe ni wọ́n máa ń rántí ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Arákùnrin . . . ni gbogbo yín.” Jésù tún sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.”—Mát. 23:8, 12.
10. Báwo ni ìrìn àjò láti Pẹ́gà sí Áńtíókù ti Písídíà ṣe rí?
10 Nígbà tí wọ́n dé Pẹ́gà, Jòhánù Máàkù fi Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sílẹ̀, ó sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Bíbélì ò sọ ìdí tó fi pa dà lójijì bẹ́ẹ̀. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń bá ìrìn àjò wọn lọ, wọ́n gba Pẹ́gà kọjá lọ sí Áńtíókù ti Písídíà, ìyẹn ìlú kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Gálátíà. Ìrìn àjò kékeré kọ́ lèyí, torí pé Áńtíókù ti Písídíà fi nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún (1,100) mítà ga ju ojú òkun lọ. Ọ̀nà ibẹ̀ rí gbágungbàgun, ó sì léwu torí pé àwọn dánàdánà máa ń wà níbẹ̀. Ohun míì ni pé, ó jọ pé ara Pọ́ọ̀lù ò yá nígbà yẹn. h
11, 12. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù tó wà ní Áńtíókù ti Písídíà, kí ló ṣe kọ́rọ̀ ẹ̀ lè wọ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn?
11 Ní Áńtíókù ti Písídíà, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wọnú sínágọ́gù lọ́jọ́ Sábáàtì. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Lẹ́yìn kíka Òfin àti ìwé àwọn Wòlíì fún àwọn èèyàn, àwọn alága sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé: ‘Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, tí ẹ bá ní ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí fún àwọn èèyàn, ẹ sọ ọ́.’ ” (Ìṣe 13:15) Pọ́ọ̀lù wá dìde láti sọ̀rọ̀.
12 Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì àti ẹ̀yin yòókù tí ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fetí sílẹ̀.” (Ìṣe 13:16) Àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, wọn ò sì mọ̀ ipa tí Jésù kó láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Torí náà, kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe kọ́rọ̀ ẹ̀ lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn? Ńṣe ló kọ́kọ́ sọ ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ó ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe “gbé àwọn èèyàn náà ga nígbà tí wọ́n jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Íjíbítì” àti bí Ọlọ́run ṣe “fara dà á fún wọn ní aginjù” fún ogójì (40) ọdún. Pọ́ọ̀lù tún sọ báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gba Ilẹ̀ Ìlérí àti bí Jèhófà ṣe “fi ilẹ̀ wọn ṣe ogún” fún wọn. (Ìṣe 13:17-19) Àwọn kan sọ pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kà látinú Ìwé Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ara ayẹyẹ Sábáàtì ni Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, á jẹ́ pé òótọ́ ni Pọ́ọ̀lù mọ bó ṣe lè “di ohun gbogbo nítorí gbogbo èèyàn.”—1 Kọ́r. 9:22.
13. Báwo la ṣe lè jẹ́ kọ́rọ̀ wa wọ àwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn?
13 Àwa náà gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa máa wọ àwọn tá à ń wàásù fún lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá mọ ẹ̀sìn tẹ́nì kan ń ṣe, ìyẹn lè jẹ́ ká yan àkòrí tó máa fa ẹni náà mọ́ra. Bákan náà a lè tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì tó ṣeé ṣe kí ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ mọ̀. Nígbà míì, ohun táá dáa jù ni pé ká ní kí ẹni náà kà á látinú Bíbélì tiẹ̀. Ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa oríṣiríṣi nǹkan tá a lè ṣe kọ́rọ̀ wa lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn.
14. (a) Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó ń wàásù ìhìn rere nípa Jésù, báwo ló sì ṣe kìlọ̀ fáwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀? (b) Kí làwọn èèyàn náà ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù?
14 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àtọmọdọ́mọ àwọn ọba Ísírẹ́lì ni Jésù. Ó tún sọ bí Jòhánù Onírìbọmi ṣe múra ọkàn àwọn èèyàn sílẹ̀ kí wọ́n lè gba Jésù tó jẹ́ “olùgbàlà.” Lẹ́yìn ìyẹn, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ṣe pa Jésù àti bí Ọlọ́run ṣe jí i dìde. (Ìṣe 13:20-37) Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kó yé yín pé ipasẹ̀ ẹni yìí la fi ń kéde ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín . . . à ń tipasẹ̀ ẹni yìí pe gbogbo ẹni tó bá gbà gbọ́ ní aláìlẹ́bi.” Àpọ́sítélì náà wá kìlọ̀ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a sọ nínú ìwé àwọn Wòlíì má bàa ṣẹ sí yín lára, pé: ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin pẹ̀gànpẹ̀gàn, kí ẹnu yà yín, kí ẹ sì ṣègbé, nítorí mò ń ṣe iṣẹ́ kan lásìkò yín, iṣẹ́ tí ẹ ò ní gbà gbọ́ láé bí ẹnì kan bá tiẹ̀ sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ fún yín.’ ” Ohun táwọn èèyàn náà ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù wúni lórí. Bíbélì ròyìn pé: “Àwọn èèyàn bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí ní Sábáàtì tó tẹ̀ lé e.” Bákan náà, lẹ́yìn tí àpéjọ sínágọ́gù parí, “ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n ń sin Ọlọ́run tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà.”—Ìṣe 13:38-43.
“A Yíjú sí Àwọn Orílẹ̀-Èdè” (Ìṣe 13:44-52)
15. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní Sábáàtì tó tẹ̀ lé e?
15 Ní Sábáàtì tó tẹ̀ lé e, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìlú náà” ló kóra jọ láti gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù. Èyí ò dùn mọ́ àwọn Júù kan nínú, torí náà wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ òdì ta ko àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.” Òun àti Bánábà wá fìgboyà sọ fún wọn pé: “Ó pọn dandan pé ẹ̀yin ni kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún. Nígbà tí ẹ sì ti kọ̀ ọ́, tí ẹ ò ka ara yín sí ẹni tó yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, torí náà, a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí Jèhófà ti pa àwọn ọ̀rọ̀ yìí láṣẹ fún wa pé: ‘Mo ti yàn ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, kí o lè jẹ́ ìgbàlà fún gbogbo ayé.’ ”—Ìṣe 13:44-47; Àìsá. 49:6.
16. Kí làwọn Júù ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ líle táwọn míṣọ́nnárì yìí sọ fún wọn, kí ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì ṣe nígbà táwọn alátakò jù wọ́n sí ẹ̀yìn ààlà ìlú wọn?
16 Inú àwọn Kèfèrí tó gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù dùn gan-an, “gbogbo àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun sì di onígbàgbọ́.” (Ìṣe 13:48) Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ọ̀rọ̀ Jèhófà fi tàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ ohun táwọn Júù ṣe yàtọ̀. Nítorí náà, àwọn míṣọ́nnárì yìí sọ fún wọn pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn, wọ́n yàn láti kọ Mèsáyà, ìdájọ́ Ọlọ́run sì tọ́ sí wọn. Torí náà, àwọn Júù ru àwọn obìnrin olókìkí àtàwọn ọkùnrin sàràkí-sàràkí ìlú náà sókè, wọ́n wá “gbé inúnibíni dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n sì jù wọ́n sí ẹ̀yìn ààlà ìlú wọn.” Kí wá ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe? Ńṣe ni “wọ́n gbọn ekuru ẹsẹ̀ wọn dà nù sí wọn, wọ́n sì lọ sí Íkóníónì.” Ṣé ibẹ̀ yẹn wá ni ẹ̀sìn Kristẹni máa dé dúró ní Áńtíókù ti Písídíà? Rárá o! Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n fi sílẹ̀ síbẹ̀ “ń ní ìdùnnú àti ẹ̀mí mímọ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Ìṣe 13:50-52.
17-19. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fi lélẹ̀, báwo nìyẹn sì ṣe lè jẹ́ ká túbọ̀ máa láyọ̀?
17 Ẹ̀kọ́ pàtàkì la rí kọ́ látinú bí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí ṣe ń fi ayọ̀ bá iṣẹ́ wọn lọ láìka ti pé àwọn èèyàn ta kò wọ́n. Àwa náà ò ní dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró, kódà táwọn tó wà nípò àṣẹ bá fẹ́ dí wa lọ́wọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà táwọn èèyàn Áńtíókù kọ ìhìn rere, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà “gbọn ekuru ẹsẹ̀ wọn dà nù.” Ohun tí wọ́n ṣe yìí ò túmọ̀ sí pé wọ́n bínú o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n fi hàn pé ọrùn àwọn mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn náà. Àwọn míṣọ́nnárì yìí mọ̀ pé àwọn ò lè fipá mú àwọn èèyàn láti gbọ́ ìhìn rere. Ohun tí wọ́n lè ṣe ò ju pé kí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní yéé wàásù. Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn nígbà tí wọ́n pinnu láti lọ sí Íkóníónì.
18 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n fi sílẹ̀ sí Áńtíókù ńkọ́? Lóòótọ́, àárín àwọn ọ̀tá ni wọ́n wà. Àmọ́, kì í ṣe bí iye àwọn tó gbọ́ ìhìn rere ṣe pọ̀ tó ló pinnu bóyá wọ́n máa láyọ̀ àbí wọn ò ní láyọ̀. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!” (Lúùkù 11:28) Ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Áńtíókù ti Písídíà sì pinnu láti ṣe nìyẹn.
19 Bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, ẹ jẹ́ ká máa rántí ní gbogbo ìgbà pé ojúṣe wa ni láti wàásù ìhìn rere. Ó wá kù sọ́wọ́ àwọn èèyàn láti yàn bóyá wọ́n máa gbọ́ tàbí wọn ò ní gbọ́. Táwọn tá à ń wàásù fún bá kọtí ikún sí wa, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Táwa náà bá mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́, tá a sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ darí wa, àá máa láyọ̀, kódà nígbà táwọn èèyàn bá ń ta kò wá.—Gál. 5:18, 22.
a Wo àpótí náà, “ Bánábà—‘Ọmọ Ìtùnú.’”
b Lásìkò yẹn, wọ́n ti wàásù ìhìn rere dé àwọn ibi tó jìnnà, wọ́n sì ti dá ìjọ sílẹ̀ láwọn ibì kan, bí Áńtíókù ti Síríà tó wà ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé àádọ́ta (550) kìlómítà sí àríwá Jerúsálẹ́mù.
c Wo àpótí náà, “ Ìrìn Àjò Nígbà Ayé Àwọn Àpọ́sítélì.”
d Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọkọ̀ ojú omi kan lè rin ìrìn àjò nǹkan bí àádọ́jọ (150) kìlómítà lóòjọ́ tí ojú ọjọ́ bá dáa. Àmọ́, ó lè má tó bẹ́ẹ̀ tí ojú ọjọ́ ò bá dáa.
e Wo àpótí náà, “ Sínágọ́gù Àwọn Júù.”
f Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin àwọn ará Róòmù ló ń ṣàkóso erékùṣù Sápírọ́sì. Àwọn ará Róòmù ló máa ń yan gómìnà tó ń ṣákóso erékùṣù náà.
g Ibí yìí ni Bíbélì ti bẹ̀rẹ̀ sí í pe Sọ́ọ̀lù ní Pọ́ọ̀lù. Àwọn kan sọ pé, torí Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì ló ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ Róòmù yìí. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò yí orúkọ náà pa dà lẹ́yìn tó kúrò ní Sápírọ́sì, èyí jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe torí Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì ló ṣe ń jẹ́ orúkọ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dìídì pinnu láti máa jẹ́ orúkọ yìí torí pé “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè” ni. Yàtọ̀ síyẹn, ó jọ pé ọ̀rọ̀ kan wà lédè Gíríìkì tó ní ìtumọ̀ tí ò dáa, tó sì jọ Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ orúkọ Pọ́ọ̀lù lédè Hébérù. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ yìí ló mú kí Pọ́ọ̀lù pinnu pé òun ò ní jẹ́ Sọ́ọ̀lù mọ́.—Róòmù 11:13.