ORÍ 6
Sítéfánù “Kún fún Oore Ọlọ́run àti Agbára”
Ohun tá a rí kọ́ látinú bí Sítéfánù ṣe fìgboyà jẹ́rìí níwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn
Ó dá lórí Ìṣe 6:8–8:3
1-3. (a) Ipò tó ń dẹ́rù bani wo ni Sítéfánù bára ẹ̀, àmọ́ kí ló ṣe? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
SÍTÉFÁNÙ wà níwájú àwọn adájọ́ nínú gbọ̀ngàn ńlá kan tó ṣeé ṣe kó wà nítòsí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọkùnrin mọ́kànléláàádọ́rin (71) jókòó sórí àwọn àga tí wọ́n tò yípo, kí wọ́n lè gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ni wọ́n ń pè wọ́n. Èèyàn jàǹkànjàǹkàn, tó lẹ́nu nílùú làwọn ọkùnrin yìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò sì já mọ́ nǹkan kan lójú ọ̀pọ̀ lára wọn. Kódà, Àlùfáà Àgbà Káyáfà ló pe ìpàdé náà, òun sì ni alága ìgbìmọ̀ yìí nígbà tí wọ́n dájọ́ ikú fún Jésù Kristi lóṣù mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn. Ṣéyẹn wá dẹ́rù ba Sítéfánù?
2 Ohun kan wà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìrísí ojú Sítéfánù lákòókò yìí. Àwọn adájọ́ náà tẹjú mọ́ ọn, wọ́n sì rí i pé ojú rẹ̀ “dà bí ojú áńgẹ́lì.” (Ìṣe 6:15) Iṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run làwọn áńgẹ́lì máa ń jẹ́, torí náà kò sídìí fún wọn láti máa bẹ̀rù. Bọ́rọ̀ Sítéfánù ṣe rí náà nìyẹn, ọkàn ẹ̀ balẹ̀. Kódà, àwọn adájọ́ tó kórìíra ẹ̀ yẹn rí i bẹ́ẹ̀. Kí ló mú kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀ tó bẹ́ẹ̀?
3 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ làwa Kristẹni òde òní lè rí kọ́ látinú ìdáhùn ìbéèrè yìí. Ó tún yẹ ká mọ ohun tó gbé Sítéfánù dérú ipò tó nira yẹn. Báwo ló ṣe gbèjà ìgbàgbọ́ ẹ̀ ṣáájú àsìkò yẹn? Báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀ lóde òní?
“Wọ́n Ru Àwọn Èèyàn . . . Sókè” (Ìṣe 6:8-15)
4, 5. (a) Kí nìdí tí Sítéfánù fi jẹ́ ẹni tó wúlò gan-an nínú ìjọ? (b) Ọ̀nà wo ni Sítéfánù gbà “kún fún oore Ọlọ́run àti agbára”?
4 A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ẹni ọ̀wọ́n ni Sítéfánù jẹ́ nínú ìjọ Kristẹni tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀. Nínú orí karùn-ún ìwé yìí, a rí i pé ó wà lára àwọn ọkùnrin méje tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì múra tán láti ṣe iṣẹ́ táwọn àpọ́sítélì gbé fún wọn. A máa túbọ̀ mọyì ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Sítéfánù, tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún un. Nínú Ìṣe 6:8, a kà pé Ọlọ́run fún un lágbára láti ṣe àwọn “ohun ìyanu ńlá àti àwọn iṣẹ́ àmì,” bíi tàwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì. Bíbélì tún sọ pé ó “kún fún oore Ọlọ́run àti agbára.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí?
5 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “oore Ọlọ́run” tún lè túmọ̀ sí “oore ọ̀fẹ́.” Ó dájú pé onínúure èèyàn ni Sítéfánù, ó níwà jẹ́jẹ́, èyí tó máa ń mú káwọn èèyàn sún mọ́ ọn. Ó máa ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tá á mú káwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ fẹ́ ṣe ohun tó ń sọ, ó máa ń mú kó dá wọn lójú pé òótọ́ lòun ń sọ látọkàn wá àti pé nǹkan tóun ń kọ́ wọn lè ṣàǹfààní fún wọn. Èèyàn lè rí agbára ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí Jèhófà lára rẹ̀ torí pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ mú kó gbà fún ẹ̀mí Ọlọ́run láti máa darí òun. Dípò kí àwọn ẹ̀bùn tó ní máa gùn ún gàràgàrà, Jèhófà ló ń fìyìn fún, ó sì hàn gbangba pé ọ̀rọ̀ àwọn tó ń wàásù fún jẹ ẹ́ lógún. Abájọ tí ẹ̀rù ẹ̀ fi ń ba àwọn tó ń ṣàtakò sí i!
6-8. (a) Ẹ̀sùn méjì wo làwọn tó ta ko Sítéfánù fi kàn án, kí sì nìdí? (b) Kí nìdí tí àpẹẹrẹ Sítéfánù fi lè ran àwa Kristẹni lọ́wọ́ lónìí?
6 Àwọn ọkùnrin kan dìde láti bá Sítéfánù ṣe awuyewuye, àmọ́ “wọn ò lè dúró níwájú rẹ̀ nítorí ọgbọ́n àti ẹ̀mí tó fi ń sọ̀rọ̀.” a Nígbà tí wọ́n rí i pé wọn ò lè borí ọmọ ẹ̀yìn Kristi tó rọra ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an yìí, wọ́n “sún àwọn kan ní bòókẹ́lẹ́” láti fẹ̀sùn kàn án. Wọ́n tún “ru àwọn èèyàn àti àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin sókè” débi pé wọ́n fipá mú Sítéfánù lọ síwájú Sàhẹ́ndìrìn. (Ìṣe 6:9-12) Ẹ̀sùn méjì táwọn alátakò náà fi kàn án ni pé: Ó ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti Mósè. Ọ̀nà wo ló gbà ṣe bẹ́ẹ̀?
7 Àwọn ẹlẹ́rìí èké náà sọ pé Sítéfánù sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run torí pé ó sọ̀rọ̀ lòdì sí “ibi mímọ́ yìí,” ìyẹn tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 6:13) Wọ́n tún sọ pé ó sọ̀rọ̀ lòdì sí Mósè torí pé ó sọ̀rọ̀ lòdì sí Òfin Mósè, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ yí òfin tó ti ọ̀dọ̀ Mósè wá pa dà. Ẹ̀sùn tó lágbára lèyí, torí pé lákòókò yẹn, ọwọ́ kékeré kọ́ làwọn Júù fi mú tẹ́ńpìlì, ohun tí Òfin Mósè sọ àti ọ̀pọ̀ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí wọ́n ti fi kún Òfin náà. Torí náà, ohun táwọn alátakò yẹn ń sọ ni pé èèyàn burúkú ni Sítéfánù, ikú sì tọ́ sí i!
8 Ó bani nínú jẹ́ pé irú ọgbọ́nkọ́gbọ́n bí èyí làwọn ẹlẹ́sìn sábà máa ń dá láti fa wàhálà fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Títí di báyìí, àwọn ẹlẹ́sìn tó ń ta ko àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lo àwọn aláṣẹ ìjọba láti ṣenúnibíni sí wa. Kí ló yẹ ká ṣe tí wọ́n bá parọ́ mọ́ wa tàbí tí wọ́n bá fẹ̀sùn èké kàn wá? A lè rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ lára Sítéfánù.
Sítéfánù Fìgboyà Jẹ́rìí Nípa “Ọlọ́run Ògo” (Ìṣe 7:1-53)
9, 10. Kí làwọn alátakò sọ nípa ọ̀rọ̀ tí Sítéfánù sọ níwájú Sàhẹ́ndìrìn, kí ló sì yẹ ká fi sọ́kàn?
9 Bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí, ńṣe lọkàn Sítéfánù balẹ̀, tójú ẹ̀ sì dà bí ojú áńgẹ́lì nígbà tó gbọ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Torí náà, Káyáfà yíjú sí i, ó sì bi í pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà rí?” (Ìṣe 7:1) Ó ti wá kan Sítéfánù láti sọ̀rọ̀ báyìí. Ó sì fìgboyà sọ̀rọ̀!
10 Lónìí, àwọn èèyàn kan ta ko ohun tí Sítéfánù sọ. Wọ́n ní ọ̀rọ̀ tó sọ gùn lóòótọ́, síbẹ̀ kò sọ ohunkóhun nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Àmọ́, ká sòótọ́, àpẹẹrẹ àtàtà ni Sítéfánù jẹ́ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa “gbèjà” ìhìn rere. (1 Pét. 3:15) Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ńṣe ni wọ́n fẹ̀sùn kan Sítéfánù pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run torí pé ó sọ̀rọ̀ lòdì sí tẹ́ńpìlì, wọ́n sì tún sọ pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Mósè torí pé ó sọ̀rọ̀ lòdì sí Òfin. Ìdáhùn Sítéfánù ṣe àkópọ̀ apá mẹ́tà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó sì fara balẹ̀ tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì níbẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà yẹ̀ wò níkọ̀ọ̀kan.
11, 12. (a) Kí nìdí tí Sítéfánù fi lo àpẹẹrẹ Ábúráhámù? (b) Kí nìdí tí Sítéfánù fi mẹ́nu kan Jósẹ́fù nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀?
11 Ìgbà ayé àwọn baba ńlá. (Ìṣe 7:1-16) Sítéfánù bẹ̀rẹ̀ látorí ohun pàtàkì táwọn Júù gbà gbọ́, ó sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó wá tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà, “Ọlọ́run ògo,” kọ́kọ́ fara han Ábúráhámù ní Mesopotámíà. (Ìṣe 7:2) Kódà, Sítéfánù jẹ́ kó yé wọn pé àjèjì ni Ábúráhámù jẹ́ ní Ilẹ̀ Ìlérí. Kò ní tẹ́ńpìlì tàbí Òfin Mósè. Báwo lèèyàn á ṣe wá sọ pé ó dìgbà tẹ́nì kan bá ń jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì, tó sì ń tẹ̀ lé Òfin Mósè kó tó lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run.
12 Èèyàn pàtàkì ni Jósẹ́fù tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù jẹ́ lójú àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Sítéfánù. Torí náà, Sítéfánù rán wọn létí pé àwọn arákùnrin Jósẹ́fù gan-an, tí wọ́n jẹ́ baba fáwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ṣe inúnibíni sí ọkùnrin olódodo náà wọ́n sì tà á sóko ẹrú. Síbẹ̀, Ọlọ́run lò ó láti gba Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ìyàn. Níbi tí Sítéfánù bọ́rọ̀ dé yìí, ó rí i pé ohun tí wọ́n ṣe sí Jósẹ́fù jọ ohun táwọn Júù ṣe sí Jésù Kristi, àmọ́ ó ṣì fi apá ibẹ̀ yẹn sílẹ̀ káwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ má bàa tètè tú ká.
13. Báwo ni ohun tí Sítéfánù sọ nípa Mósè ṣe fi hàn pé ẹ̀sùn èké ni wọ́n fi kàn án, kókó pàtàkì wo nìyẹn sì fi hàn?
13 Ìgbà ayé Mósè. (Ìṣe 7:17-43) Sítéfánù sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Mósè. Ìyẹn bọ́gbọ́n mu torí pé Sadusí ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn, wọn ò sì gba apá tó kù nínú Bíbélì gbọ́, àyàfi èyí tí Mósè kọ. Yàtọ̀ síyẹn, rántí pé wọ́n fẹ̀sùn kan Sítéfánù pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Mósè. Ohun tí Sítéfánù sọ fi hàn pé ẹ̀sùn èké ni wọ́n fi kàn án, torí ó hàn nínú ohun tó sọ pé ó ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Mósè àti Òfin. (Ìṣe 7:38) Sítéfánù jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tí Mósè gbìyànjú láti gbà là kẹ̀yìn sí i nígbà tó pé ọmọ ogójì (40) ọdún. Ní ohun tó lé ní ogójì (40) ọdún lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sọ ọ́ kò ó lójú pé òun kọ́ ni aṣáájú tí Ọlọ́run yàn. b Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Sítéfánù bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ dé orí kókó pàtàkì kan, ìyẹn ni pé ó ti mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run lára láti máa ta ko àwọn tí Jèhófà bá yàn láti darí wọn.
14. Kókó pàtàkì wo ni Sítéfánù fẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀ nígbà tó lo àpẹẹrẹ Mósè?
14 Sítéfánù rán àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ létí pé Mósè ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wòlíì kan bíi tòun máa dìde ní Ísírẹ́lì. Ta ni wòlíì náà máa jẹ́, ṣé àwọn èèyàn sì máa gba tiẹ̀? Sítéfánù ò sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ó fẹ́ dáhùn ìbéèrè náà níparí ọ̀rọ̀ ẹ̀. Ó wá sọ̀rọ̀ nípa kókó pàtàkì míì, ìyẹn ni pé: Mósè rí i pé ilẹ̀ èyíkéyìí ni Ọlọ́run lè sọ di mímọ́, bí ilẹ̀ tígbó ti ń jó níbi ti Jèhófà ti bá a sọ̀rọ̀. Torí náà, ṣó wá yẹ ká fi ìjọsìn Jèhófà mọ sínú ilé kan ṣoṣo, bíi ti tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù? Sítéfánù máa tó dáhùn ìbéèrè yìí.
15, 16. (a) Kí nìdí tí Sítéfánù fi mẹ́nu ba àgọ́ ìjọsìn nínú ọ̀rọ̀ tó ń sọ? (b) Báwo ni Sítéfánù ṣe lo tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì nínú ìjíròrò rẹ̀?
15 Àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì. (Ìṣe 7:44-50) Sítéfánù rán àwọn tó ń gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀ létí pé kí tẹ́ńpìlì èyíkéyìí tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni Ọlọ́run ti sọ pé kí Mósè kọ́ àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn ilé ìjọsìn tó dà bí àgọ́ tó sì ṣeé gbé kiri. Kò sí ìkankan lára àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Sítéfánù tó lè sọ pé àgọ́ ìjọsìn kéré sí tẹ́ńpìlì, ó ṣe tán Mósè fúnra ẹ̀ jọ́sìn níbẹ̀.
16 Nígbà tó yá, tí Sólómọ́nì kọ́ tẹ́ńpìlì sí Jerúsálẹ́mù, Ọlọ́run mí sí i láti kọ́ni ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nínú àdúrà. Sítéfánù sọ pé, “Ẹni Gíga Jù Lọ kì í gbé àwọn ilé tí a fi ọwọ́ kọ́.” (Ìṣe 7:48; 2 Kíró. 6:18) Jèhófà lè lo tẹ́ńpìlì láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, àmọ́ tí ò bá sí tẹ́ńpìlì, ìyẹn ò dá ohun tó bá fẹ́ ṣe dúró. Torí náà, kò sídìí tó fi yẹ káwọn tó ń sìn ín máa ronú pé ó dìgbà táwọn bá rí ilé téèyàn kọ́ káwọn tó lè máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́? Sítéfánù parí ọ̀rọ̀ tó ti ń sọ bọ̀ lọ́nà tó lágbára. Ó fa ọ̀rọ̀ yọ nínú ìwé Àìsáyà, ó ní: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Irú ilé wo lẹ fẹ́ kọ́ fún mi? ni Jèhófà wí. Àbí ibo ni ibi ìsinmi mi? Ọwọ́ mi ni ó ṣe gbogbo nǹkan yìí, àbí òun kọ́?”—Ìṣe 7:49, 50; Àìsá. 66:1, 2.
17. (a) Ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀ Sítéfánù gbà fi irú ẹni táwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ jẹ́ hàn, (b) Báwo ló ṣe fi hàn pé òun ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun?
17 Bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí Sítéfánù sọ níwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn, ṣéwọ náà ò gbà pé ó fi irú ẹni táwọn tó fẹ̀sùn kàn án jẹ́ hàn lọ́nà tó ṣe kedere? Ó fi hàn pé kò sóhun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ pé kó má mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kọ́ ló sì ń pinnu ohun tó máa ṣe. Àwọn èèyàn yẹn ò lóye ohun tí Òfin àti tẹ́ńpìlì wà fún, àmọ́ wọ́n ka ẹwà tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù àtàwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn sì pàtàkì! Torí náà, ńṣe ló dà bí ìgbà tí Sítéfánù ń bi wọ́n pé: Ṣebí ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà fi hàn pé ẹ̀ ń bọlá fún Òfin àti tẹ́ńpìlì ni pé kẹ́ ẹ máa ṣègbọràn sí Jèhófà? Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ Sítéfánù jẹ́rìí sí i pé kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, torí ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ṣègbọràn sí Jèhófà.
18. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fara wé Sítéfánù?
18 Kí la lè rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ Sítéfánù? Ó lóye Ìwé Mímọ́ dáadáa. Ó yẹ káwa náà máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ká lè máa “lo ọ̀rọ̀ òtítọ́ bó ṣe yẹ.” (2 Tím. 2:15) Ẹ̀kọ́ míì tá a tún rí kọ́ lára Sítéfánù ni pé ká mọ béèyàn ṣe ń fọgbọ́n sọ̀rọ̀. Àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ ò fẹ́ gbọ́ òtítọ́. Síbẹ̀, jálẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tó bá wọn sọ, kò mẹ́nu kan ohun tó máa bí wọn nínú, ibi tí ọ̀rọ̀ wọn ti jọra ló tẹnu mọ́. Ó tún pọ́n àwọn èèyàn náà lé, kódà ó pe àwọn àgbàlagbà tó wà láàárín wọn ní “bàbá.” (Ìṣe 7:2) Ó yẹ káwa náà máa fi “ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀” ṣàlàyé òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—1 Pét. 3:15.
19. Báwo ni Sítéfánù ṣe fìgboyà kéde ìdájọ́ Jèhófà sórí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn?
19 Àmọ́ o, ìbẹ̀rù pé ká má ṣẹ àwọn èèyàn ò gbọ́dọ̀ mú ká dẹwọ́ láti máa wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; bẹ́ẹ̀ la ò sì gbọ́dọ̀ bomi la ọ̀rọ̀ ìdájọ́ Jèhófà tá à ń kéde fáwọn èèyàn. Àpẹẹrẹ àtàtà lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sítéfánù jẹ́ fún wa. Ó rí i pé gbogbo àlàyé tóun ṣe níwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun kò tu irun kankan lára àwọn onídàájọ́ náà, torí pé ọkàn wọn ti yigbì. Torí náà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, ó fígboyà parí ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó sọ pé wọ́n dà bí àwọn baba ńlá wọn tí wọ́n kẹ̀yìn sí Jósẹ́fù, Mósè àti gbogbo àwọn wòlíì. (Ìṣe 7:51-53) Ó ṣe tán, àwọn onídàájọ́ tó wà nínú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn yìí ló pa Mèsáyà, ẹni tí Mósè àti gbogbo àwọn wòlíì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó ń bọ̀. Dájúdájú, wọ́n ti ṣàìgbọràn sí Òfin Mósè lọ́nà tó burú gan-an!
“Jésù Olúwa, Gba Ẹ̀mí Mi” (Ìṣe 7:54–8:3)
20, 21. Kí ni ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Sítéfánù, báwo ni Jèhófà sì ṣe fún un lókun?
20 Òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Sítéfánù sọ fáwọn onídàájọ́ yẹn múnú bí wọn gan-an. Ó ká wọn lára débí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wa eyín wọn pọ̀ sí Sítéfánù. Ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin olóòótọ́ yẹn ti rí i pé wọn ò ní ṣàánú òun, bí wọn ò ṣe ṣàánú Jésù Ọ̀gá òun.
21 Sítéfánù ní láti jẹ́ onígboyà kó tó lè fara da ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i láìpẹ́, ó sì dájú pé ìran tí Jèhófà fi hàn án fún un lókun gan-an. Sítéfánù rí ògo Ọlọ́run, ó sì rí Jésù tó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Jèhófà! Bí Sítéfánù ṣe ń ṣàpèjúwe ìràn náà, ńṣe làwọn tó ń gbẹ́jọ́ rẹ̀ fọwọ́ bo etí wọn. Kí nìdí? Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù ti sọ fún ìgbìmọ̀ yẹn kan náà pé òun ni Mèsáyà àti pé òun máa tó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Baba òun. (Máàkù 14:62) Ìran tí Sítéfánù rí fi hàn pé òótọ́ lohun tí Jésù sọ àti pé lóòótọ́ ni ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn kórìíra Mèsáyà, tí wọ́n sì pa á! Ni gbogbo wọn bá ṣùrù bo Sítéfánù, tí wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa. c
22, 23. Àwọn ọ̀nà wo ni ikú Sítéfánù gbà jọ ti Jésù, báwo làwa Kristẹni òde òní sì ṣe lè nígboyà bíi ti Sítéfánù?
22 Irú ikú tí Jésù kú náà ni Sítéfánù kú, ọkàn ẹ̀ balẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó sì dárí ji àwọn tó pa á. Ó sọ pé: “Jésù Olúwa, gba ẹ̀mí mi,” torí ó ṣeé ṣe kó ṣì máa rí Ọmọ èèyàn àti Jèhófà nínú ìran. Ó dájú pé Sítéfánù mọ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Jésù sọ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.” (Jòh. 11:25) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Sítéfánù gbóhùn sókè ó sì gbàdúrà sí Ọlọ́run ní tààràtà pé: “Jèhófà, má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.” Lẹ́yìn tó sọ bẹ́ẹ̀ tán, ó sùn nínú ikú.—Ìṣe 7:59, 60.
23 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ló mú kí Sítéfánù jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi àkọ́kọ́ tí wọ́n pa nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. (Wo àpótí náà, “ Wọ́n Pa Sítéfánù Torí Pé Ó Jẹ́ ‘Ẹlẹ́rìí’ Jésù.”) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé wọ́n ṣì máa pa àwọn míì náà nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Títí dìgbà tiwa yìí, àwọn alátakò ẹ̀sìn, àwọn tó ń fìgbónára ṣe òṣèlú, àtàwọn alátakò míì tó burú gan-an ṣì ń bá a lọ láti máa pa àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Síbẹ̀, àwa náà lè jẹ́ onígboyà bíi ti Sítéfánù. Jésù ti di Ọba báyìí, ó sì ń lo agbára àrà ọ̀tọ̀ tí Bàbá rẹ̀ gbé lé e lọ́wọ́. Kò sóhun tó máa dí i lọ́wọ́ láti jí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ dìde.—Jòh. 5:28, 29.
24. Báwo ni Sọ́ọ̀lù ṣe lọ́wọ́ sí ikú Sítéfánù, ọ̀nà wo ni ikú Sítéfánù sì máa gbà ṣe àwọn èèyàn láǹfààní?
24 Ọ̀dọ́kùnrin kan wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n pa Sítéfánù, Sọ́ọ̀lù lorúkọ ẹ̀. Ó fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe pa Sítéfánù, kódà ibi ẹsẹ̀ ẹ̀ ni wọ́n kó aṣọ àwọn tó ń sọ Sítéfánù lókùúta sí. Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni tó lè gan-an sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àmọ́, ikú Sítéfánù ṣì máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Àpẹẹrẹ ẹ̀ máa fún àwọn Kristẹni míì lókun káwọn náà lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí dójú ikú. Yàtọ̀ síyẹn, tí Sọ́ọ̀lù tó wá di Pọ́ọ̀lù nígbà tó yá bá rántí bóun ṣe lọ́wọ́ sí ikú Sítéfánù, ó máa dùn ún gan-an. (Ìṣe 22:20) Torí àwọn nǹkan tó ṣe yẹn, ó sọ nígbà tó yá pé: “Asọ̀rọ̀ òdì ni mí tẹ́lẹ̀, mo máa ń ṣe inúnibíni, mo sì jẹ́ aláfojúdi.” (1 Tím. 1:13) Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ gbàgbé bí Sítéfánù ṣe fi ìtara àti ìgboyà sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ yẹn. Kódà, ara àwọn ọ̀rọ̀ tí Sítéfánù sọ ni Pọ́ọ̀lù fi bẹ̀rẹ̀ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ àtàwọn ìwé tó kọ. (Ìṣe 7:48; 17:24; Héb. 9:24) Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù kọ́ bó ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìgboyà Sítéfánù, tó jẹ́ ọkùnrin tó “kún fún oore Ọlọ́run àti agbára.” Ẹ ò rí i pé ó yẹ káwa náà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sítéfánù.
a Àwọn kan lára àwọn alátakò náà wà nínú àwùjọ tí wọ́n ń pè ní “Sínágọ́gù Àwọn Olómìnira.” Ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ Júù táwọn ará Róòmù ti kó lẹ́rú rí, tí wọ́n wá dá wọn sílẹ̀, tàbí kí wọ́n jẹ́ ara àwọn ẹrú tó di aláwọ̀ṣe Júù lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀. Àwọn kan lára wọn wá láti Sìlíṣíà, ìyẹn agbègbè tí Sọ́ọ̀lù ará Tásù ti wá. Àkọsílẹ̀ náà ò sọ bóyá Sọ́ọ̀lù wà lára àwọn ará Sìlíṣíà tó gbógun ti Sítéfánù.
b Àwọn nǹkan kan wà tí Sítéfánù sọ tá ò lè rí níbòmíì nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ̀rọ̀ nípa bí Mósè ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ní Íjíbítì, ọjọ́ orí ẹ̀ nígbà tó kọ́kọ́ sá kúrò ní Íjíbítì àti bó ṣe pẹ́ tó ní Mídíánì.
c Ó jọ pé òfin ilẹ̀ Róòmù ò fún ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn láṣẹ láti dájọ́ ikú fúnni. (Jòh. 18:31) Torí náà, ó dà bíi pé àwọn jàǹdùkú tínú ń bí ló pa Sítéfánù, kì í ṣe ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ló dájọ́ ikú fún un.