Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 8 • ÌṢE 21:18–28:31

‘Wọ́n Wàásù Ìjọba Ọlọ́run Láìsí Ìdíwọ́’

‘Wọ́n Wàásù Ìjọba Ọlọ́run Láìsí Ìdíwọ́’

ÌṢE 28:31

Nínú apá yìí, a máa rí bí àwọn jàǹdùkú ṣe gbéjà ko àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, bí wọ́n ṣe mú un lọ sẹ́wọ̀n, bó ṣe fara dà á nígbà tó wà lẹ́wọ̀n àti bó ṣe jẹ́jọ́ níwájú oríṣiríṣi àwọn aláṣẹ Róòmù. Síbẹ̀, kò yéé wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Bó o ṣe ń ṣàyẹ̀wò apá tó wúni lórí tó gbẹ̀yìn ìwé Ìṣe, máa bi ara ẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ajíhìnrere tó nígboyà, tó sì ń fìtara wàásù yìí?’