ORÍ 23
“Ẹ Gbọ́ Ẹjọ́ Tí Mo Fẹ́ Rò fún Yín”
Pọ́ọ̀lù gbèjà ìgbàgbọ́ ẹ̀ níwájú àwọn jàǹdùkú tínú ń bí àti níwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn
Ó dá lórí Ìṣe 21:18–23:10
1, 2. Kí ló gbé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dé Jerúsálẹ́mù, àwọn ìṣòro wo ló sì ní nígbà tó wà níbẹ̀?
LẸ́Ẹ̀KAN sí i, Pọ́ọ̀lù tún rìn gba ìlú Jerúsálẹ́mù, níbi tí èrò pọ̀ sí, táwọn èèyàn sì ń rìn lọ rìn bọ̀. Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn Jèhófà ti lọ ń jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà yẹn, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù máa ń fi ìlú wọn yangàn. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló ṣì ń rin kinkin mọ́ òfin Mósè, wọn ò sì ṣe tán láti fara mọ́ ọ̀nà tuntun tí Jèhófà ní kí wọ́n máa gbà jọ́sìn òun. Torí náà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní Éfésù, ó pinnu pé òun máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará tó wà ní Jerúsálẹ́mù kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tara, kó sì tún èrò tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ ṣe. (Ìṣe 19:21) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó léwu láti lọ síbẹ̀, kò jẹ́ kí ohunkóhun yí ìpinnu òun pa dà.
2 Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù ní Jerúsálẹ́mù? Ó máa dojú kọ ìṣòro látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan tí wọ́n ti gbọ́ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa ẹ̀, tíyẹn sì ń kó ìdààmú bá wọn. Àmọ́, àwọn ọ̀tá Kristi ló máa ṣenúnibíni sí i jù. Àwọn ọ̀tá yìí máa parọ́ mọ́ ọn, wọ́n máa lù ú, wọ́n sì máa fikú halẹ̀ mọ́ ọn. Àwọn ìṣòro yìí tún máa fún Pọ́ọ̀lù láǹfààní láti gbèjà ohun tó gbà gbọ́. Àpẹẹrẹ rere ni Pọ́ọ̀lù jẹ́ fún àwa Kristẹni lónìí, torí láìka àwọn ìṣòro yìí sí, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó nígboyà, ó sì fi hàn pé òun nígbàgbọ́. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe ṣe é.
“Wọ́n Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Yin Ọlọ́run Lógo” (Ìṣe 21:18-20a)
3-5. (a) Pọ́ọ̀lù àtàwọn wo ló jọ ṣèpàdé ní Jerúsálẹ́mù, kí ni wọ́n sì jíròrò níbẹ̀? (b) Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìpàdé tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn alàgbà ṣe ní Jerúsálẹ́mù?
3 Lọ́jọ́ kejì tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n bá a rìnrìn àjò dé Jerúsálẹ́mù, wọ́n lọ rí àwọn alàgbà tó ń múpò iwájú nínú ìjọ. Àkọsílẹ̀ yìí ò sọ̀rọ̀ nípa ìkankan lára àwọn àpọ́sítélì tó ṣì wà láyé nígbà yẹn, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti lọ wàásù láwọn apá ibòmíì. Àmọ́, ẹ̀rí fi hàn pé Jémíìsì arákùnrin Jésù ṣì wà níbẹ̀. (Gál. 2:9) Kódà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló ṣe alága ìpàdé tí “gbogbo àwọn alàgbà” bá Pọ́ọ̀lù ṣe.—Ìṣe 21:18.
4 Pọ́ọ̀lù kí àwọn alàgbà, “ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ó ṣe.” (Ìṣe 21:19) Ó dájú pé àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù sọ máa fún àwọn arákùnrin yẹn lókun gan-an. Inú tiwa náà máa ń dùn lónìí tá a bá gbọ́ ìròyìn nípa báwọn ará wa ṣe ń tẹ̀ síwájú láwọn ilẹ̀ míì.—Òwe 25:25.
5 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ, ó jọ pé ó mẹ́nu kan àwọn ọrẹ tó mú wá láti ilẹ̀ Yúróòpù. Ó dájú pé inú àwọn ará yẹn máa dùn gan-an láti mọ̀ pé àwọn ará tó ń gbé láwọn apá ibi tó jìnnà gan-an nífẹ̀ẹ́ àwọn tó bẹ́ẹ̀. Nígbà táwọn alàgbà náà gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, àkọsílẹ̀ yẹn sọ pé: “Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo”! (Ìṣe 21:20a) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń fara da àjálù tàbí àìsàn tó le gan-an. Tá a bá ràn wọ́n lọ́wọ́ tá a sì fún wọn níṣìírí tó bọ́ sákòókò, ara máa tù wọ́n gan-an.
Ọ̀pọ̀ Ṣì “Ní Ìtara fún Òfin” (Ìṣe 21:20b, 21)
6. Ìṣòro wo ni wọ́n fi tó Pọ́ọ̀lù létí?
6 Àwọn alàgbà yẹn wá sọ fún Pọ́ọ̀lù pé ìṣòro kan wà ní Jùdíà, orí ẹ̀ sì lọ̀rọ̀ náà dá lé. Wọ́n ní: “Arákùnrin, wo bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn onígbàgbọ́ tó wà láàárín àwọn Júù ṣe pọ̀ tó, gbogbo wọn ló sì ní ìtara fún Òfin. Àmọ́ wọ́n ti gbọ́ àhesọ nípa rẹ pé ò ń kọ́ gbogbo Júù tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n kẹ̀yìn sí Mósè, tí ò ń sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe dádọ̀dọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí tẹ̀ lé àwọn àṣà wọn.” a—Ìṣe 21:20b, 21.
7, 8. (a) Èrò tí kò tọ́ wo ni ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà ní? (b) Kí nìdí tí èrò tí kò tọ́ táwọn kan lára àwọn Júù tó di Kristẹni ní ò fi sọ wọ́n di apẹ̀yìndà?
7 Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ Kristẹni ṣì fi ń rin kinkin mọ́ Òfin Mósè, nígbà tó jẹ́ pé ó ti lé ní ogún ọdún sẹ́yìn tí Jèhófà ti fòpin sí Òfin náà? (Kól. 2:14) Lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tí wọ́n pàdé ní Jerúsálẹ́mù ti fi lẹ́tà ránṣẹ́ sáwọn ìjọ láti ṣàlàyé fún wọn pé kò pọn dandan fáwọn tó di onígbàgbọ́ láàárín àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè láti dádọ̀dọ́ tàbí pa Òfin Mósè mọ́. (Ìṣe 15:23-29) Àmọ́, lẹ́tà yẹn ò sọ̀rọ̀ nípa àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ò mọ̀ pé Òfin Mósè ò wúlò mọ́.
8 Ṣé èrò tí kò tọ́ táwọn Júù yìí ní wá túmọ̀ sí pé wọn kì í ṣe Kristẹni mọ́? Rárá o. Kì í kúkú ṣe pé wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ abọ̀rìṣà tí wọ́n wá tún pa dà sídìí àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà náà. Ó ṣe tán, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló fún àwọn Júù tó di onígbàgbọ́ yẹn ní Òfin tí wọ́n ṣì kà sí pàtàkì yìí. Òfin yẹn ò ní ìbẹ́mìílò nínú, kò sì sí nǹkan tó burú nínú ẹ̀. Àmọ́, májẹ̀mú yìí dá lórí Òfin Mósè, nígbà tó sì jẹ́ pé májẹ̀mú tuntun làwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé báyìí. Jèhófà ó retí pé kí wọ́n pa òfin Mósè mọ́ kí òun tó tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. Àwọn Júù tó di Kristẹni tí wọ́n ń rin kinkin mọ́ Òfin Mósè ò gbára lé Jèhófà, wọn ò fẹ́ tẹ̀ lé ètò tuntun tí Jèhófà ṣe, wọn ò sì lóye pé àwọn ò sí lábẹ́ májẹ̀mú Òfin mọ́. Ó yẹ kí wọ́n ṣàtúnṣe èrò wọn kó lè wà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa májẹ̀mú Òfin. b—Jer. 31:31-34; Lúùkù 22:20.
“Kò Sí Òótọ́ Kankan Nínú Àwọn Ọ̀rọ̀ Àhesọ” Náà (Ìṣe 21:22-26)
9. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa Òfin Mósè?
9 Ṣé òótọ́ lohun táwọn kan ń sọ pé Pọ́ọ̀lù ń kọ́ àwọn Júù tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè “pé kí wọ́n má ṣe dádọ̀dọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí tẹ̀ lé àwọn àṣà wọn”? Òótọ́ ni pé Pọ́ọ̀lù ń wàásù fáwọn Kèfèrí, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kò pọn dandan pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé Òfin Mósè. Bákan náà, Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kò yẹ kí ẹnikẹ́ni sọ fáwọn Kèfèrí tó di onígbàgbọ́ pé wọ́n gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́ kí wọ́n lè fi hàn pé wọ́n ń tẹ̀ lé Òfin Mósè. (Gál. 5:1-7) Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù wàásù ìhìn rere fáwọn Júù tó wà láwọn ìlú tó ṣèbẹ̀wò sí. Ó dájú pé ó máa ṣàlàyé fáwọn tó bá fetí sọ́rọ̀ ẹ̀ pé ikú Jésù ti fòpin sí Òfin Mósè àti pé Jèhófà ò retí pé wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé Òfin kóun tó tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn.—Róòmù 2:28, 29; 3:21-26.
10. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn tó ń rin kinkin mọ́ Òfin àti ìdádọ̀dọ́?
10 Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn tí wọ́n ṣì ń fẹ́ láti máa tẹ̀ lé àwọn àṣà Júù kan, irú bíi pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn oúnjẹ kan tàbí ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sábáàtì. (Róòmù 14:1-6) Kò sì ṣe òfin kankan nípa ìdádọ̀dọ́. Kódà, ó dádọ̀dọ́ Tímótì káwọn Júù má bàa fojú sí i lára, torí pé Gíríìkì ni bàbá rẹ̀. (Ìṣe 16:3) Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá òun máa dádọ̀dọ́ tàbí òun ò ní dádọ̀dọ́. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Gálátíà pé: “Ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́ kò ṣàǹfààní, ìgbàgbọ́ tó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ìfẹ́ ló ṣàǹfààní.” (Gál. 5:6) Torí náà, tẹ́nì kan bá dádọ̀dọ́ torí pé ó fẹ́ ṣe ohun tí Òfin sọ tàbí tó bá ń sọ pé dandan ni kéèyàn dádọ̀dọ́ kó bàa lè rójú rere Jèhófà, ńṣe lẹni náà ń fi hàn pé òun ò nígbàgbọ́.
11. Kí làwọn alàgbà sọ pé kí Pọ́ọ̀lù ṣe, àmọ́ kí ló dájú pé Pọ́ọ̀lù ò ní fọwọ́ sí? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
11 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àhesọ táwọn èèyàn yẹn sọ kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, ọ̀rọ̀ náà ò tíì tán lọ́kàn àwọn Júù tó di Kristẹni náà. Èyí ló mú kí àwọn alàgbà náà sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ọkùnrin mẹ́rin wà lọ́dọ̀ wa tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́. Mú àwọn ọkùnrin yìí dání, kí o wẹ ara rẹ mọ́ pẹ̀lú wọn lọ́nà Òfin, kí o sì bójú tó ìnáwó wọn, kí wọ́n lè fá orí wọn. Nígbà náà, gbogbo èèyàn á mọ̀ pé kò sí òótọ́ kankan nínú àwọn ọ̀rọ̀ àhesọ tí wọ́n ń gbọ́ nípa rẹ, àmọ́ pé ò ń rìn létòlétò àti pé ìwọ náà ń pa Òfin mọ́.” c—Ìṣe 21:23, 24.
12. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun ò rin kinkin mọ́ èrò òun, tó sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù?
12 Pọ́ọ̀lù lè sọ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ àhesọ tí wọ́n sọ nípa òun ló fa wàhálà, pé àwọn Júù tó di onígbàgbọ́ yẹn gan-an ni, torí pé wọ́n rin kinkin mọ́ Òfin Mósè. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù gbà láti ṣe ohun táwọn alàgbà yẹn sọ torí kò ta ko ìlànà Ọlọ́run. Ó ti kọ́kọ́ kọ̀wé sáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Nítorí àwọn tó wà lábẹ́ òfin, mo dà bí ẹni tó wà lábẹ́ òfin, bó tiẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi ò sí lábẹ́ òfin, kí n lè jèrè àwọn tó wà lábẹ́ òfin.” (1 Kọ́r. 9:20) Torí náà, Pọ́ọ̀lù gbà láti ṣe ohun táwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ní kó ṣe, èyí sì mú kó dà bí “ẹni tó wà lábẹ́ òfin.” Àpẹẹrẹ rere lohun tó ṣe yìí jẹ́ fún wa lónìí, káwa náà máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà, ká má máa sọ pé èrò tiwa nìkan ló tọ̀nà.—Héb. 13:17.
“Kò Yẹ Kó Wà Láàyè!” (Ìṣe 21:27–22:30)
13. (a) Kí nìdí táwọn Júù kan fi dá wàhálà sílẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì? (b) Ta ni ò jẹ́ kí wọ́n pa Pọ́ọ̀lù?
13 Nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ ní tẹ́ńpìlì rárá. Nígbà tó ku ọjọ́ díẹ̀ káwọn ọkùnrin yẹn parí ìwẹ̀mọ́ náà, àwọn Júù tí wọ́n wá láti Éṣíà rí Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì fẹ̀sùn èké kàn án pé ó ń mú àwọn Kèfèrí wá sínú tẹ́ńpìlì, bí wọ́n ṣe dá wàhálà sílẹ̀ nìyẹn. Ọpẹ́lọpẹ́ ọ̀gágun Róòmù tó dá sọ̀rọ̀ náà, ńṣe ni wọn ì bá lu Pọ́ọ̀lù pa. Àmọ́ dípò tí ọ̀gágun yẹn á fi jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù máa lọ, ṣe ló ní káwọn ọmọ ogun fi Pọ́ọ̀lù sátìmọ́lé. Ó sì máa ju ọdún mẹ́rin lọ lẹ́yìn ìyẹn kí wọ́n tó dá a sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, kékeré lèyí jẹ́ tá a bá fi wé ohun tójú Pọ́ọ̀lù ṣì máa rí. Nígbà tí ọ̀gágun náà béèrè ohun tó fà á tí wọ́n fi ń lu Pọ́ọ̀lù, oríṣiríṣi ẹ̀sùn ni wọ́n fi kàn án. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ò yé ọ̀gágun yẹn rárá, torí bí gbogbo wọn ṣe ń pariwo. Wàhálà náà wá pọ̀ débi pé ṣe ni wọ́n gbé Pọ́ọ̀lù kúrò níbẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun Róòmù náà fẹ́ wọ àgọ́ wọn, Pọ́ọ̀lù sọ fún ọ̀gágun náà pé: “Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀.” (Ìṣe 21:39) Ọ̀gágun náà sì gbà pé kó bá wọn sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù wá fìgboyà gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ̀.
14, 15. (a) Àlàyé wo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fáwọn Júù? (b) Kí ni ọ̀gágun Róòmù náà ṣe kó lè mọ ìdí táwọn Júù fi ń bínú sí Pọ́ọ̀lù?
14 Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó ní: “Ẹ gbọ́ ẹjọ́ tí mo fẹ́ rò.” (Ìṣe 22:1) Èdè Hébérù ni Pọ́ọ̀lù fi bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀, èyí sì mú kí wọ́n fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀. Láìfi nǹkan kan pa mọ́, ó ṣàlàyé ohun tó mú kí òun di ọmọlẹ́yìn Kristi. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ, ó fọgbọ́n mẹ́nu kan àwọn kókó kan táwọn Júù yẹn lè lọ ṣèwádìí nípa ẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́. Ọ̀dọ̀ ọkùnrin olókìkí kan tó ń jẹ́ Gàmálíẹ́lì ni Pọ́ọ̀lù ti kẹ́kọ̀ọ́, ó ti ṣenúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, ó sì ṣeé ṣe káwọn kan lára àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ mọ̀. Àmọ́ nígbà tó ń lọ sílùú Damásíkù, Jésù Kristi tó ti jíǹde fi ìran kan hàn án, ó sì bá a sọ̀rọ̀. Àwọn tó ń bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò rí ìmọ́lẹ̀ kan tó tàn yòò, wọ́n sì gbọ́ ohùn kan, àmọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń gbọ́ ò yé wọn. (Ìṣe 9:7; 22:9) Wọ́n wá mú Pọ́ọ̀lù lọ sí Damásíkù, torí pé ìmọ́lẹ̀ yẹn ti fọ́ ọ lójú. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ananáyà, táwọn Júù tó wà lágbègbè yẹn mọ̀ dáadáa wo Pọ́ọ̀lù sàn, ó sì pa dà ríran.
15 Pọ́ọ̀lù tún ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ, ó sọ pé nígbà tóun dé Jerúsálẹ́mù, Jésù fara han òun nínú tẹ́ńpìlì. Ohun tó sọ yìí bí àwọn Júù yẹn nínú gan-an, wọ́n sì ń pariwo pé: “Ẹ mú irú ọkùnrin yìí kúrò láyé, torí kò yẹ kó wà láàyè!” (Ìṣe 22:22) Ọ̀gágun náà wá ní kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù lọ sínú àgọ́ àwọn sójà kí wọ́n má bàa pa á. Torí pé ọ̀gágun náà fẹ́ mọ ìdí táwọn Júù yẹn fi ń bínú sí Pọ́ọ̀lù, ó ní kí wọ́n na Pọ́ọ̀lù lẹ́gba kí wọ́n lè wádìí ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹ̀. Pọ́ọ̀lù wá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọmọ ilẹ̀ Róòmù lòun, kó lè fi ohun tí òfin ilẹ̀ Róòmù sọ gbèjà ara ẹ̀. Lóde òní, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà máa ń lo ohun tí òfin sọ láti gbèjà ìgbàgbọ́ wa. (Wo àwọn àpótí náà, “ Òfin Àwọn Ará Róòmù Àtàwọn ” àti “ Ọmọ Ilẹ̀ Róòmù Bá A Ṣe Ń Gbèjà Ìgbàgbọ́ Wa Lóde Òní.”) Nígbà tí ọ̀gágun náà gbọ́ pé ọmọ ilẹ̀ Róòmù ni Pọ́ọ̀lù, ó rí i pé ó yẹ kóun wá ọ̀nà míì tóun á fi wádìí ọ̀rọ̀ yẹn. Torí náà lọ́jọ́ kejì, ó pe ìpàdé ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn tó jẹ́ ilé ẹjọ́ gíga jù lọ àwọn Júù, ó sì mú Pọ́ọ̀lù lọ síwájú wọn.
“Farisí Ni Mí” (Ìṣe 23:1-10)
16, 17. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nílé ẹjọ́ Sàhẹ́ndìrìn? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ nígbà tí wọ́n gbá a lẹ́nu?
16 Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í gbèjà ara ẹ̀ níwájú Sàhẹ́ndìrìn, ó ní: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, mo ti hùwà níwájú Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ láìkù síbì kan títí di òní yìí.” (Ìṣe 23:1) Pọ́ọ̀lù ò tíì sọ jùyẹn lọ tí ohun kan fi ṣẹlẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ni Ananáyà àlùfáà àgbà bá pàṣẹ fún àwọn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n gbá a lẹ́nu.” (Ìṣe 23:2) Ẹ ò rí i pé wọ́n dójú ti Pọ́ọ̀lù gan-an! Èyí fi hàn pé ẹ̀tanú làwọn èèyàn náà ń ṣe, torí pé wọ́n sọ Pọ́ọ̀lù di òpùrọ́ láìtíì gbọ́ tẹnu ẹ̀! Ìyẹn ló mú kí Pọ́ọ̀lù fèsì pé: “Ọlọ́run yóò gbá ọ, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun. Ṣebí torí kí o lè fi Òfin ṣèdájọ́ mi lo ṣe jókòó, kí ló dé tí ìwọ fúnra rẹ tún ń rú Òfin bí o ṣe ní kí wọ́n gbá mi?”—Ìṣe 23:3.
17 Bí wọ́n ṣe gbá Pọ́ọ̀lù lẹ́nu ò tiẹ̀ jọ àwọn èèyàn náà lójú, àmọ́ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, ó yà wọ́n lẹ́nu! Ni wọ́n bá bi í pé: “Ṣé ò ń bú àlùfáà àgbà Ọlọ́run ni?” Ohun tí Pọ́ọ̀lù fi dá wọn lóhùn kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrẹ̀lẹ̀ àti bó ṣe yẹ kéèyàn bọ̀wọ̀ fún Òfin. Ó ní: “Ẹ̀yin ará, mi ò mọ̀ pé àlùfáà àgbà ni. Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ alákòóso àwọn èèyàn rẹ láìdáa.’ ” d (Ìṣe 23:4, 5; Ẹ́kís. 22:28) Pọ́ọ̀lù wá gbé ọ̀rọ̀ ẹ̀ gba ibòmíì. Ó kíyè sí i pé àwọn Farisí àtàwọn Sadusí ló wà nílé ẹjọ náà, ó wá sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, Farisí ni mí, mo sì jẹ́ ọmọ àwọn Farisí. Torí ìrètí àjíǹde àwọn òkú ni wọ́n ṣe ń dá mi lẹ́jọ́.”—Ìṣe 23:6.
18. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé Farisí lòun, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀ tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa?
18 Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé Farisí lòun? Ìdí ni pé “ọmọ àwọn Farisí” ni, ìyẹn ni pé Farisí làwọn òbí ẹ̀. Torí náà, ojú Farisí lọ̀pọ̀ èèyàn á ṣì máa fi wò ó. e Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé òun nígbàgbọ́ nínú àjíǹde bíi tàwọn Farisí? Àwọn kan sọ pé àwọn Farisí gbà gbọ́ pé téèyàn bá kú, ọkàn ẹ̀ ṣì máa wà láàyè, àti pé táwọn olódodo bá kú, wọ́n máa ń gbé ara míì wọ̀. Àmọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù gbà gbọ́ kọ́ nìyẹn. Àjíǹde tí Jésù fi kọ́ni ló gbà gbọ́ ní tiẹ̀. (Jòh. 5:25-29) Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù ṣì gbà pẹ̀lú àwọn Farisí pé àwọn tó ti kú lè pa dà wà láàyè, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Sadusí ò gbà gbọ́ pé ẹni tó ti kú lè pa dà wà láàyè. Àwa náà lè ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù tá a bá ń wàásù fáwọn ẹlẹ́sìn míì tí wọ́n sọ pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. A lè sọ pé àwa náà gba Ọlọ́run gbọ́. Lóòótọ́, ó lè jẹ́ ọlọ́run míì ni wọ́n gbà gbọ́, nígbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run tó ni Bíbélì làwa gbà gbọ́. Síbẹ̀, ṣe la jọ gbà pé Ọlọ́run wà.
19. Kí nìdí tí ìpàdé tí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ń ṣe fi dà rú?
19 Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ da àárín ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn rú. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ariwo ńlá sọ, lára àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ àwọn Farisí dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn kíkankíkan, wọ́n ń sọ pé: ‘A ò rí ohun àìtọ́ kankan tí ọkùnrin yìí ṣe, àmọ́ tí ẹ̀mí tàbí áńgẹ́lì bá bá a sọ̀rọ̀—.’ ” (Ìṣe 23:9) Àwọn Sadusí ò gbà pé áńgẹ́lì wà, torí náà inú bí wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ pé áńgẹ́lì bá Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀! (Wo àpótí náà, “ Àwọn Sadusí Àtàwọn Farisí.”) Awuyewuye náà le débi pé ọ̀gágun Róòmù yẹn tún gba Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. (Ìṣe 23:10) Síbẹ̀, ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù ṣì wà nínú ewu. Àmọ́, kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì yìí? A máa rí àlàyé púpọ̀ sí i nínú orí tó kàn.
a Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn Júù tó di Kristẹni pọ̀ tóyẹn ní Jerúsálẹ́mù, ó ní láti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìjọ ló ń pàdé nínú ilé àdáni.
b Lọ́dún díẹ̀ lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn Hébérù, láti fi ṣàlàyé bí májẹ̀mú tuntun ti ṣe pàtàkì tó. Nínú lẹ́tà yẹn, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé májẹ̀mú tuntun ti sọ májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá baba ńlá wọn dá di èyí tí kò bágbà mu mọ́. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹn fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ń rin kinkin mọ́ Òfin Mósè lókun, ó tún mú kó rọrùn fáwọn Júù tó di Kristẹni yẹn láti ṣàlàyé fáwọn tó ṣì ń tẹ̀ lé Òfin Mósè pé kò pọn dandan kéèyàn máa tẹ̀ lé òfin náà mọ́.—Héb. 8:7-13.
c Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé àwọn ọkùnrin náà ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di Násírì. (Nọ́ń. 6:1-21) Òótọ́ ni pé Òfin Mósè tó ní káwọn èèyàn máa jẹ́ irú ẹ̀jẹ́ yìí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ mọ́. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ronú pé kò sóhun tó burú nínú káwọn ọkùnrin yẹn mú ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ fún Jèhófà ṣẹ. Torí náà, kò sóhun tó burú bí Pọ́ọ̀lù ṣe bójú tó ìnáwó wọn tó sì tẹ̀ lé wọn. A ò mọ irú ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ gan-an, àmọ́ èyí ó wù kó jẹ́, kò dájú pé Pọ́ọ̀lù á fọwọ́ sí i pé kí wọ́n fi ẹran rúbọ sí Jèhófà (báwọn Násírì ti máa ń ṣe), torí wọ́n gbà gbọ́ pé ìyẹn á wẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn mọ́. Ẹbọ pípé tí Kristi fi ara rẹ̀ rú ti fòpin sírú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ táwọn èèyàn fi ń ṣètùtù. Ohun yòówù kí Pọ́ọ̀lù ṣe, ó dájú pé kò ní gbà láti ṣe ohunkóhun tó lè kó bá ẹ̀rí ọkàn ẹ̀.
d Àwọn kan sọ pé Pọ́ọ̀lù ò ríran dáadáa ni kò ṣe dá àlùfáà àgbà mọ̀. Tàbí kó jẹ́ pé ó pẹ́ tó ti wá sí Jerúsálẹ́mù kẹ́yìn, kò sì mọ ẹni tó jẹ́ àlùfáà àgbà nígbà yẹn. Ó sì lè jẹ́ pé èrò tó pọ̀ níbẹ̀ ni ò jẹ́ kó ríran rí ẹni tó sọ pé kí wọ́n gbá òun lẹ́nu.
e Lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn àpọ́sítélì àtàwọn alágbà ń jíròrò lórí bóyá ó yẹ káwọn Kèfèrí máa tẹ̀ lé Òfin Mósè tàbí kò yẹ, wọ́n pe àwọn Kristẹni kan tó wà níbẹ̀ ní “àwọn kan tó wá látinú ẹ̀ya ìsìn àwọn Farisí, àmọ́ tí wọ́n ti di onígbàgbọ́.” (Ìṣe 15:5) Ó jọ pé ìdí tí wọ́n fi pè wọ́n bẹ́ẹ̀ ni pé Farisí ni wọ́n kí wọ́n tó di Kristẹni.