ORÍ 28
“Títí Dé Ibi Tó Jìnnà Jù Lọ ní Ayé”
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá a lọ láti máa ṣe iṣẹ́ táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni
1. Báwo lọ̀rọ̀ àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti tàwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ṣe jọra?
WỌ́N ń fìtara wàásù, wọ́n sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ darí wọn torí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ń bá a lọ láti máa wàásù bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ń ṣenúnibíni sí wọn. Ọ̀pọ̀ nǹkan rere ni Ọlọ́run sì ṣe fún wọn. Bọ́rọ̀ àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe rí nìyẹn, bó sì ṣe rí fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní náà nìyẹn.
2, 3. Kí ló mú kí ìwé Ìṣe ṣàrà ọ̀tọ̀?
2 Ọ̀pọ̀ ìtàn tó ń gbé ìgbàgbọ́ ẹni ró tó sì ń tani jí ló wà nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì. Ó dájú pé àwọn ìtàn náà ti fún ẹ lókun! Nínú gbogbo ìwé ìtàn tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì ṣàrà ọ̀tọ̀, torí pé òun nìkan ni Ọlọ́run mí sí.
3 Ìwé Ìṣe sọ̀rọ̀ nípa èèyàn márùndínlọ́gọ́rún (95), ilẹ̀ méjìlélọ́gbọ̀n (32), ìlú mẹ́rìnléláàádọ́ta (54) àtàwọn erékùṣù mẹ́sàn-án. Ó sọ ìtàn nípa oríṣiríṣi èèyàn, bí àpẹẹrẹ ó sọ nípa àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́nu láwùjọ, àwọn tó ń ṣenúnibíni lọ́nà tó rorò, àwọn ẹlẹ́sìn èké àtàwọn olóṣèlú tó jẹ́ agbéraga. Àmọ́ ní pàtàkì jù lọ, ó sọ nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tí wọ́n fìtara wàásù ìhìn rere bo tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro dojú kọ wọ́n.
4. Kí nìdí tí àwa àtàwọn èèyàn bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, Tàbítà àtàwọn ẹlẹ́rìí olóòótọ́ míì lọ́gọ́rùn-ún ọdún kìíní fi dà bí ọmọ ìyá?
4 Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún báyìí táwọn olóòótọ́ yìí ti gbé láyé. Àwọn bí àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù tí wọ́n fìtara ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wọn, Lúùkù oníṣègùn tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n, Bánábà tó jẹ́ ọ̀làwọ́, Sítéfánù tó jẹ́ onígboyà, Tàbítà tó lọ́kàn rere, Lìdíà tó nífẹ̀ẹ́ àlejò àti ọ̀pọ̀ àwọn míì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí olóòótọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti gbé láyé, ṣe ni wọ́n dà bí ọmọ ìyá wa. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù ní kí wọ́n ṣe làwa náà ń ṣe lónìí. (Mát. 28:19, 20) Àǹfààní ńlá ló sì jẹ́ pé à ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ yìí!
5. Ibo làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù?
5 Ronú nípa àṣẹ tí Jésù pa fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ní agbára láti wàásù “ní Jerúsálẹ́mù.” (Ìṣe 1:1–8:3) Lẹ́yìn náà, wọ́n wàásù “ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà.” (Ìṣe 8:4–13:3) Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìhìn rere náà lọ “títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”—Ìṣe 13:4–28:31.
6, 7. Bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù, àwọn àǹfààní wo la ní táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ò ní?
6 Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní yìí ò rí odindi Bíbélì lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bíi tiwa. Nǹkan bí ọdún 41 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n tó kọ ìwé Ìhìn Rere Mátíù tán. Pọ́ọ̀lù ti kọ díẹ̀ lára àwọn lẹ́tà rẹ̀ kí wọ́n tó kọ ìwé Ìṣe tán ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ò ní odindi Ìwé Mímọ́ tàbí oríṣiríṣi ìwé tí wọ́n lè fún àwọn tó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Káwọn Júù kan tó di Kristẹni, inú sínágọ́gù ni wọ́n ti máa ń ka Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù fún wọn. (2 Kọ́r. 3:14-16) Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́, torí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá há sórí ni wọ́n máa fi wàásù fáwọn míì.
7 Lónìí, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa ló ní Bíbélì tiẹ̀, a sì tún ní ọ̀pọ̀ ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. À ń wàásù ìhìn rere ní oríṣiríṣi èdè, a sì ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ogójì (240) lọ.
Ẹ̀mí Mímọ́ Mú Kí Wọ́n Lágbára
8, 9. (a) Kí ni ẹ̀mí mímọ́ mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lè ṣe? (b) Àwọn nǹkan wo ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń ran ẹrú olóòótọ́ lọ́wọ́ láti ṣe?
8 Nígbà tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́rìí òun, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín.” Ó dájú pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tàbí agbára ìṣiṣẹ́ rẹ̀ máa ran àwọn ọmọ èyìn Jésù lọ́wọ́ kí wọ́n lè wàásù ní gbogbo ayé. Lóòótọ́, ẹ̀mí mímọ́ ran Pétérù àti Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ kí wọ́n lè wo àwọn èèyàn sàn, wọ́n lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, kódà wọ́n jí òkú dìde! Àmọ́, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún ran àwọn Kristẹni yẹn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fáwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn míì láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ tòótọ́ tó máa jẹ́ kí wọ́n ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 17:3.
9 Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù “sọ oríṣiríṣi èdè, bí ẹ̀mí ṣe mú kí wọ́n máa sọ̀rọ̀.” Ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n lè máa jẹ́rìí nípa “àwọn ohun àgbàyanu Ọlọ́run.” (Ìṣe 2:1-4, 11) Lónìí, a kì í sọ oríṣiríṣi èdè lọ́nà ìyanu. Àmọ́, ẹ̀mí Ọlọ́run ń ran ẹrú olóòótọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì jáde ní èdè tó pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù Ilé Ìṣọ́ àti Jí! là ń tẹ̀ jáde lóṣooṣù. Bákan náà, àwọn ìwé àtàwọn fídíò tó dá lórí Bíbélì tó wà lórí ìkànnì jw.org ló ti wà ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ báyìí. Gbogbo nǹkan yìí ló ń mú ká lè máa kéde “àwọn ohun àgbàyanu Ọlọ́run” fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n.—Ìfi. 7:9.
10. Kí ni ẹrú olóòótọ́ ti ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì látọdún 1989?
10 Látọdún 1989 ni ẹrú olóòótọ́ ti ń rí i dájú pé a túmọ̀ Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sí èdè tó pọ̀. Ní báyìí, a ti túmọ̀ Bíbélì yìí sí èdè tó lé ní igba (200), ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ẹ̀dà la sì ti tẹ̀ jáde. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ẹ̀dà ni a ṣì ń tẹ̀ jáde. Jèhófà ló mú ká ṣàṣeyọrí yìí, òun ló fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè tẹ Bíbélì ní oríṣiríṣi èdè, kó sì lè dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tó pọ̀.
11. Báwo la ṣe ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
11 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni ló ń yọ̀ǹda ara wọn láti máa túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa ní ilẹ̀ tó lé ní àádọ́jọ (150). Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu, torí pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló ń darí wa. Òun ló ń ràn wá lọ́wọ́ tá a fi ń “jẹ́rìí kúnnákúnná” nípa Jèhófà Ọlọ́run kárí ayé, tá a sì ń sọ̀rọ̀ nípa Mèsáyà Ọba tí Ọlọ́run yàn àti Ìjọba tó ti ń ṣàkóso lọ́run báyìí!—Ìṣe 28:23.
12. Kí ló ran Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni tó kù lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù?
12 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wàásù fáwọn Júù àtàwọn Kèfèrí ní Áńtíókù ti Písídíà, “gbogbo àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun . . . di onígbàgbọ́.” (Ìṣe 13:48) Lápá ìparí ìwé Ìṣe, Lúùkù sọ pé Pọ́ọ̀lù ‘ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ń kọ́ni ní fàlàlà láìsí ìdíwọ́.’ (Ìṣe 28:31) Ibo ni àpọ́sítélì yìí ti ń wàásù? Ìlú Róòmù ni, ibẹ̀ sì ni ojúkò ìjọba alágbára tó ń ṣàkóso ayé nígbà yẹn! Ì báà jẹ́ nípasẹ̀ àsọyé Bíbélì tàbí láwọn ọ̀nà míì, ẹ̀mí mímọ́ ló ran àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lọ́wọ́ tó sì darí gbogbo iṣẹ́ ìwàásù wọn.
Wọ́n Ń Fara Dà Á Láìka Inúnibíni Sí
13. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa?
13 Nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, wọ́n bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ káwọn nígboyà. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Wọ́n kún fún ẹ̀mí mímọ́, ẹ̀mí mímọ́ sì mú kí wọ́n lágbára láti máa fìgboyà sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ìṣe 4:18-31) Àwa náà máa ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ọgbọ́n àti agbára ká lè máa wàásù nìṣó láìka inúnibíni sí. (Jém. 1:2-8) À ń bá iṣẹ́ náà lọ torí pé Ọlọ́run ń bù kún wa, ó sì ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́. Kò sóhun tó lè dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró, ì báà jẹ́ inúnibíni tó ń pọ̀ sí i tàbí àtakò tó le gan-an. Tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa, ó yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́, ọgbọ́n àti ìgboyà tí àá fi máa wàásù ìhìn rere.—Lúùkù 11:13.
14, 15. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn “ìpọ́njú tó wáyé nítorí Sítéfánù”? (b) Lákòókò tiwa, báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn ará Siberia ṣe mọ òtítọ́?
14 Sítéfánù fìgboyà wàásù káwọn ọ̀tá tó pa á. (Ìṣe 6:5; 7:54-60) Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe “inúnibíni tó lágbára” sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, gbogbo wọn tú ká, wọ́n sì lọ sí Jùdíà àti Samáríà. Àwọn àpọ́sítélì nìkan ló wá kù. Àmọ́, ìyẹn ò dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró. Fílípì lọ sí Samáríà kó lè lọ “wàásù nípa Kristi” níbẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ sì yọrí sí rere. (Ìṣe 8:1-8, 14, 15, 25) Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ìpọ́njú tó wáyé nítorí Sítéfánù mú kí wọ́n tú ká ń lọ títí dé Foníṣíà, Sápírọ́sì àti Áńtíókù, àmọ́ àwọn Júù nìkan ni wọ́n ń wàásù fún. Síbẹ̀, àwọn kan lára wọn tó wá láti Sápírọ́sì àti Kírénè wá sí Áńtíókù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì sọ̀rọ̀, wọ́n ń kéde ìhìn rere Jésù Olúwa.” (Ìṣe 11:19, 20) Lákòókò yẹn, inúnibíni mú kí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tàn káàkiri.
15 Lóde òní, ohun kan tó jọ ìyẹn ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Soviet Union. Láàárín ọdún 1950 sí ọdún 1959, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Siberia. Bí wọ́n ṣe tú wọn ká sáwọn ibi àdádó tó wà níbẹ̀ mú kí ìhìn rere náà tàn káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ náà. Kò sí báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ṣe fẹ́ rí owó tí wọ́n á fi rìnrìn àjò lọ síbi tó jìnnà tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) kìlómítà kí wọ́n lè lọ wàásù ìhìn rere! Àmọ́, ìjọba fúnra ẹ̀ ló kó wọn sínú ọkọ̀ tó sì gbé wọn lọ sórílẹ̀-èdè náà. Arákùnrin kan sọ pé: “Ibi tọ́rọ̀ náà wá já sí ni pé àwọn aláṣẹ fúnra wọn ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ olóòótọ́ ọkàn tó wà ní Siberia láti mọ òtítọ́.”
Jèhófà Bù Kún Wọn Lọ́pọ̀lọpọ̀
16, 17. Àwọn ẹ̀rí wo ló wà nínú ìwé Ìṣe tó fi hàn pé Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ìwàásù náà?
16 Ó hàn lóòótọ́ pé Jèhófà bù kún àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni míì gbìn, wọ́n sì bomi rin, àmọ́ “Ọlọ́run ló mú kó máa dàgbà.” (1 Kọ́r. 3:5, 6) Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣe jẹ́ ká rí i dájú pé, Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ìwàásù táwọn Kristẹni yẹn ń ṣe torí ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń di Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń gbilẹ̀ nìṣó, iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń pọ̀ sí i gidigidi ní Jerúsálẹ́mù.” (Ìṣe 6:7) Báwọn Kristẹni ṣe ń wàásù láwọn ilẹ̀ tó pọ̀ sí i, “ìjọ tó wà jákèjádò Jùdíà àti Gálílì àti Samáríà wọnú àkókò àlàáfíà, à ń gbé e ró; ó ń gbèrú sí i bó ṣe ń rìn nínú ìbẹ̀rù Jèhófà [ìyẹn ọ̀wọ̀ fún Jèhófà] àti nínú ìtùnú ẹ̀mí mímọ́.”—Ìṣe 9:31.
17 Ní Áńtíókù ti Síríà, àwọn Júù àtàwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ látọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí tó jẹ́ onígboyà. Bíbélì sọ pé: “Yàtọ̀ síyẹn, ọwọ́ Jèhófà wà lára wọn, ọ̀pọ̀ èèyàn di onígbàgbọ́, wọ́n sì yíjú sí Olúwa.” (Ìṣe 11:21) Bíbélì tún sọ pé “ọ̀rọ̀ Jèhófà ń gbilẹ̀, ó sì ń tàn kálẹ̀” nílùú yẹn. (Ìṣe 12:24) Bí Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni míì sì ṣe ń fìtara wàásù láàárín àwọn Kèfèrí, “ọ̀rọ̀ Jèhófà ń gbilẹ̀ nìṣó, ó sì ń borí lọ́nà tó lágbára.”—Ìṣe 19:20.
18, 19. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé “ọwọ́ Jèhófà” wà lára wa? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé Jèhófà máa ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́.
18 Ó hàn lóòótọ́ pé, “ọwọ́ Jèhófà” wà lára wa lónìí. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wá sínú òtítọ́, tí wọ́n ń ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run tí wọ́n sì ń ṣèrìbọmi. Bákan náà, torí pé Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ tó sì ń bù kún wa la ṣe ń fara da àtakò àti inúnibíni tó le gan-an, tá a sì ń ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa bíi ti Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni míì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Ìṣe 14:19-21) Gbogbo ìgbà la lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run, torí ó máa ń fi “ọwọ́ ayérayé rẹ̀” ràn wá lọ́wọ́ nínú gbogbo àdánwò wa. (Diu. 33:27) Ẹ jẹ́ ká máa fi sọ́kàn pé Jèhófà ò ní pa àwọn èèyàn rẹ̀ tì láé nítorí orúkọ ńlá rẹ̀.—1 Sám. 12:22; Sm. 94:14.
19 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé Jèhófà máa ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́: Torí pé Arákùnrin Harald Abt ń bá a lọ láti máa wàásù, ìjọba Násì jù ú sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen nígbà Ogún Àgbáyé Kejì. Ní May 1942, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Gestapo lọ bá Elsa ìyàwó ẹ̀ nílé, wọ́n mú ọmọbìnrin wọn kékeré lọ, wọ́n sì fàṣẹ ọba mú Elsa. Wọ́n rán an lọ sí onírúurú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Arábìnrin Elsa Abt sọ pé: “Láwọn ọdún tí mo lò ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lórílẹ̀-èdè Jámánì, mo kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ẹ̀kọ́ náà ni pé ẹ̀mí Jèhófà lè fún èèyàn lókun nígbà tó bá dojú kọ àdánwò tó le koko! Káwọn ọlọ́pàá tó wá mú mi, mo ti ka lẹ́tà arábìnrin kan tó sọ pé nígbà téèyàn bá wà nínú ìṣòro, ẹ̀mí Jèhófà máa ń mú kí ọkàn ẹni balẹ̀. Mo rò pé àsọdùn lọ̀rọ̀ arábìnrin yẹn. Àmọ́ nígbà tí àdánwò dé bá èmi fúnra mi, mo wá rí i pé òótọ́ ni. Bó ṣe sọ yẹn gan-an ló rí. Tí ò bá tíì ṣẹlẹ̀ séèyàn rí, èèyàn á rò pé kò lè rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi ni.”
Máa Bá A Lọ Láti Máa Jẹ́rìí Kúnnákúnná!
20. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó wà látìmọ́lé, báwo lèyí sì ṣe lè fún àwọn kan lára àwọn ará wa níṣìírí?
20 Nínú ẹsẹ tó kẹ́yìn nínú ìwé Ìṣe, a rí i pé Pọ́ọ̀lù ṣì ń fìtara “wàásù Ìjọba Ọlọ́run.” (Ìṣe 28:31) Àtìmọ́lé ló wà nígbà yẹn, torí náà kò lómìnira láti máa wàásù láti ilé dé ilé nílùú Róòmù. Síbẹ̀, ó ń bá a lọ láti máa wàásù fún gbogbo àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ ẹ̀. Lónìí, àwọn kan lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ò lè jáde nílé mọ́, àwọn kan wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn, àwọn míì sì wà láwọn ilé tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn arúgbó, àwọn aláìsàn tàbí àwọn aláìlera. Síbẹ̀, ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà ṣì lágbára, ó sì máa ń wù wọ́n pé kí wọ́n jẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọ́run. A máa ń rántí wọn nínú àdúrà wa, a sì tún lè bẹ Jèhófà Baba wa ọ̀run pé kó jẹ́ kí wọ́n rí àwọn tó máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ àti nípa àwọn ohun àgbàyanu tó fẹ́ ṣe.
21. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe iṣẹ́ ìwàásù ní kíákíá láìfi falẹ̀?
21 Ọ̀pọ̀ lára wa là ń wàásù láti ilé dé ilé, tá a sì ń lo oríṣiríṣi ọ̀nà míì tá à ń gbà sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe ojúṣe wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, kó lè ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́rìí “dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” Ká máa rántí pé iṣẹ́ tó yẹ ká ṣe ní kíákíá ni, torí “àmì” tá à ń rí báyìí ti túbọ̀ fi hàn pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà. (Mát. 24:3-14) A ò gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ náà falẹ̀ rárá. Ní báyìí, a ní “ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.”—1 Kọ́r. 15:58.
22. Kí ló yẹ ká pinnu pé a máa ṣe bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ Jèhófà?
22 Bá a ṣe ń dúró de “ọjọ́ ńlá Jèhófà tó ń bani lẹ́rù,” ẹ jẹ́ ká pinnu pé a máa jẹ́ olóòótọ́, àá sì máa fìgboyà wàásù. (Jóẹ́lì 2:31) A ṣì máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn bíi tàwọn ará Bèróà tí wọ́n “gba ọ̀rọ̀ náà tọkàntọkàn.” (Ìṣe 17:10, 11) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá iṣẹ́ náà lọ títí dìgbà tí Jèhófà máa sọ fún wa pé: “O káre láé, ẹrú rere àti olóòótọ́!” (Mát. 25:23) Tá a bá ń fìtara wàásù, tá a sì ń bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ó dájú pé títí ayé ni inú wa á máa dùn pé àwa náà láǹfààní láti “jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run!”