Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 24

“Mọ́kàn Le!”

“Mọ́kàn Le!”

Àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Pọ́ọ̀lù, àmọ́ Pọ́ọ̀lù gbèjà ara ẹ̀ níwájú Fẹ́líìsì

Ó dá lórí Ìṣe 23:11–24:27

1, 2. Kí nìdí tí ò fi ya Pọ́ọ̀lù lẹ́nu nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí i ní Jerúsálẹ́mù?

 NÍ Jerúsálẹ́mù, wọ́n gba Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú tínú ń bí. Àmọ́ wọ́n tún jù ú sẹ́wọ̀n lẹ́yìn ìyẹn. Bí wọ́n ṣe ń ṣenúnibíni sí àpọ́sítélì tó nítara yìí ò yà á lẹ́nu rárá. Ẹ̀mí mímọ́ ti jẹ́ kó mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé “ẹ̀wọ̀n àti ìpọ́njú” ń dúró dè é ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 20:22, 23) Pọ́ọ̀lù ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sóun ní pàtó, àmọ́ ó mọ̀ pé òun á ṣì máa jìyà nítorí orúkọ Jésù.​—Ìṣe 9:16.

2 Kódà, àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ wòlíì sọ fún Pọ́ọ̀lù pé wọ́n máa dè é wọ́n sì máa “fà á lé ọwọ́ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.” (Ìṣe 21:4, 10, 11) Kò tíì pẹ́ tàwùjọ àwọn Júù kan fẹ́ pa Pọ́ọ̀lù, ni ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn náà tún fẹ́ ‘fà á ya’ nígbà tí wọ́n ń jiyàn nítorí ohun tó sọ. Ní báyìí, àwọn ọmọ ogun Róòmù ti fi àpọ́sítélì náà sátìmọ́lé, àmọ́ ọ̀pọ̀ àdánwò ló ṣì máa rí, torí wọ́n ṣì máa fi oríṣiríṣi ẹ̀sùn kàn án. (Ìṣe 21:31; 23:10) Ẹ ò rí i pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nílò ìṣírí!

3. Ibo la ti ń rí ìṣírí gbà ká lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ?

3 A mọ̀ pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí, “gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tím. 3:12) Torí náà, léraléra làwa náà máa nílò ìṣírí ká lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ. À ń rí àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tó bọ́ sákòókò gbà nípasẹ̀ àwọn ìwé wa àtàwọn ìpàdé tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń ṣètò. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà! (Mát. 24:45) Jèhófà ti ṣèlérí pé òun ò ní jẹ́ káwọn ọ̀tá pa àwọn èèyàn òun run, òun ò sì ní jẹ́ kí wọ́n dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró. (Àìsá. 54:17; Jer. 1:19) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá ńkọ́? Ṣé ó rí ìṣírí tó nílò gbà kó lè máa jẹ́rìí kúnnákúnná láìka inúnibíni sí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe rí ìṣírí gbà, kí ló sì ṣe lẹ́yìn náà?

“Ọ̀tẹ̀ Oníbùúra” Kan Já sí Pàbó (Ìṣe 23:11-34)

4, 5. Ìṣírí wo ni Pọ́ọ̀lù rí gbà, báwo ló sì ṣe bọ́ sákòókò?

4 Lálẹ́ ọjọ́ kejì tí wọ́n gba àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn, ó rí ìṣírí tó nílò gbà. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Olúwa dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì sọ pé: ‘Mọ́kàn le! Nítorí pé bí o ṣe ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa mi ní Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ lo ṣe máa jẹ́rìí ní Róòmù.’ ” (Ìṣe 23:11) Ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Jésù sọ fún Pọ́ọ̀lù yìí jẹ́ kó dá a lójú pé kò ní kú sí Jerúsálẹ́mù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣì máa láǹfààní láti jẹ́rìí nípa Jésù nílùú Róòmù.

“Ó ju ogójì (40) ọkùnrin lára wọn tó lúgọ dè é.”​—Ìṣe 23:21

5 Ìṣírí tí Pọ́ọ̀lù rí gbà yìí bọ́ sákòókò gan-an ni. Lọ́jọ́ kejì, ó ju ogójì (40) ọkùnrin lọ tí wọ́n “fi ègún de ara wọn, pé àwọn ò ní jẹ, àwọn ò sì ní mu títí àwọn á fi pa Pọ́ọ̀lù.” “Ọ̀tẹ̀ oníbùúra” yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn Júù yẹn ti pinnu láti pa Pọ́ọ̀lù. Wọ́n gbà pé ohun burúkú máa ṣẹlẹ̀ sáwọn táwọn ò bá rí Pọ́ọ̀lù pa. (Ìṣe 23:12-15) Àwọn èèyàn yìí wá ṣètò láti mú Pọ́ọ̀lù pa dà wá sílé ẹjọ́ Sàhẹ́ndìrìn, àwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbààgbà náà sì fọwọ́ sí ètò tí wọ́n ṣe yẹn, torí kí wọ́n lè bi Pọ́ọ̀lù ní ìbéèrè síwájú sí i, kí wọ́n sì rí àrídájú àwọn ọ̀rọ̀ kan nípa ẹ̀. Àmọ́ ṣe làwọn tó dìtẹ̀ yẹn fẹ́ dènà de Pọ́ọ̀lù kí wọ́n lè pa á.

6. Báwo ni àṣírí àwọn tó gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Pọ́ọ̀lù ṣe tú, kí làwọn ọ̀dọ́ sì lè rí kọ́ lára mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù yìí?

6 Àmọ́ ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù gbọ́ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sì sọ fún Pọ́ọ̀lù. Pọ́ọ̀lù wá ní kó lọ sọ fún ọ̀gágun Róòmù tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Kíláúdíù Lísíà. (Ìṣe 23:16-22) Ó dájú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tó nígboyà bíi ti mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù tí Bíbélì ò dárúkọ ẹ̀ yìí. Torí pé wọ́n ń fi ire àwọn èèyàn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, wọ́n jẹ́ olóòótọ́, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú.

7, 8. Kí ni Kíláúdíù Lísíà ṣe kí wọ́n má bàa pa Pọ́ọ̀lù?

7 Nígbà tí Kíláúdíù Lísíà tó ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ọmọ ogun gbọ́ pé wọ́n fẹ́ dènà de Pọ́ọ̀lù kí wọ́n lè pa á, kíá ló pàṣẹ lóru ọjọ́ yẹn pé káwọn sójà, àwọn tó ń fi ọ̀kọ̀ jà àtàwọn ẹlẹ́ṣin tí wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́rin (470) lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù dé Kesaríà láìséwu. Ó ní tí wọ́n bá sì ti débẹ̀ kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù lọ sọ́dọ̀ Gómìnà Fẹ́líìsì. a Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ń gbé ìlú Kesaríà tó jẹ́ ibùjókòó ìjọba Róòmù ní Jùdíà, àmọ́ àwọn Kèfèrí ló pọ̀ jù níbẹ̀. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù yàtọ̀ sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Kesaríà, torí kò sí wàhálà ní Kesaríà, gbogbo nǹkan sì ń lọ létòlétò, àmọ́ ẹ̀tanú ló kún Jerúsálẹ́mù, àwọn ẹlẹ́sìn kórìíra ara wọn, wọ́n sì máa ń bára wọn jà. Ìlú Kesaríà ni oríléeṣẹ́ àwọn ọmọ ogun Róòmù wà.

8 Ní ìbámu pẹ̀lú òfin ìlú Róòmù, Lísíà fi lẹ́tà tó ṣàlàyé bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ àti ibi tí wọ́n bá ẹjọ́ náà dé ránṣẹ́ sí Fẹ́líìsì. Ó sọ nínú lẹ́tà náà pé nígbà tóun gbọ́ pé ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ni Pọ́ọ̀lù, òun gbà á lọ́wọ́ àwọn Júù ‘tí wọ́n fẹ́ pa á.’ Lísíà sọ pé òun ò rí i pé Pọ́ọ̀lù jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kankan “tó yẹ fún ikú tàbí fún ìdè,” àmọ́ torí pé wọ́n gbìmọ̀ láti pa á lòun ṣe ní kí wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ Fẹ́líìsì kí gómìnà lè gbọ́rọ̀ látẹnu àwọn tó fẹ̀sùn kàn án, kó sì ṣèdájọ́ tó bá yẹ lórí ọ̀rọ̀ náà.​—Ìṣe 23:25-30.

9. (a) Báwo ni wọ́n ṣe fi ẹ̀tọ́ Pọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù dù ú? (b) Kí ló lè mú ká lo ẹ̀tọ́ tá a ní lábẹ́ òfin?

9 Ṣé gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ ni Lísíà kọ sínú lẹ́tà yẹn? Rárá o. Ó jọ pé ṣe ló fẹ́ kí gómìnà yẹn rí òun bí èèyàn dáadáa. Kì í ṣe torí pé ó mọ̀ pé ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ni Pọ́ọ̀lù ló ṣe gbà á sílẹ̀. Bákan náà, Lísíà ò sọ pé òun ti ní kí wọ́n fi “ẹ̀wọ̀n méjì dè é,” kò sì sọ pé òun ti pàṣẹ pé “kí wọ́n nà án láti wádìí lọ́wọ́ rẹ̀.” (Ìṣe 21:30-34; 22:24-29) Ohun tó sì ṣe yìí fi hàn pé ó fi ẹ̀tọ́ Pọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù dù ú. Lónìí, Sátánì ń lo àwọn ẹlẹ́sìn èké tí wọ́n ń lo ìtara lọ́nà òdì láti ṣenúnibíni sáwa èèyàn Jèhófà, wọ́n sì lè fàwọn ẹ̀tọ́ wa dù wá. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin láti dáàbò bò ara wọn.

“Mo Ṣe Tán Láti Gbèjà Ara Mi” (Ìṣe 23:35–24:21)

10. Àwọn ẹ̀sùn tó lágbára wo ni wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù?

10 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní Kesaríà, wọ́n ní “kí wọ́n máa ṣọ́ ọ ní ààfin Hẹ́rọ́dù,” títí dìgbà táwọn tó fẹ̀sùn kàn án á fi dé láti Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 23:35) Ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn náà ni wọ́n dé. Àwọn tó wá ni Àlùfáà Àgbà Ananáyà, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan tó ń jẹ́ Tẹ́túlọ́sì àtàwọn àgbààgbà kan. Tẹ́túlọ́sì kọ́kọ́ yin Fẹ́líìsì torí nǹkan tó ń ṣe fáwọn Júù, ó sì jọ pé ńṣe ló sọ̀rọ̀ tó dùn kó bàa le rí ojú rere Fẹ́líìsì. b Lẹ́yìn náà, ó fàbọ̀ sórí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, ó sọ pé: “Alákòóbá ni ọkùnrin yìí, ṣe ló ń dáná ọ̀tẹ̀ sí ìjọba láàárín gbogbo àwọn Júù káàkiri ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, òun sì ni òléwájú nínú ẹ̀ya ìsìn àwọn ará Násárẹ́tì. Ó tiẹ̀ tún fẹ́ sọ tẹ́ńpìlì di ẹlẹ́gbin, ìdí nìyẹn tí a fi mú un.” Àwọn Júù tó kù náà wá ‘gbe Tẹ́túlọ́sì lẹ́yìn láti ta ko Pọ́ọ̀lù, wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí.’ (Ìṣe 24:5, 6, 9) Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù lágbára gan-an. Wọ́n sọ pé ó sún àwọn èèyàn láti dìtẹ̀ sí ìjọba, ó jẹ́ òléwájú nínú ẹ̀ya ìsìn eléwu àti pé ó sọ tẹ́ńpìlì di aláìmọ́, wọ́n sì lè torí àwọn ẹ̀sùn yìí dájọ́ ikú fúnni.

11, 12. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé irọ́ làwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun?

11 Lẹ́yìn tí Tẹ́túlọ́sì sọ̀rọ̀ tán, wọ́n ní kí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀. Ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ ni pé: “Mo ṣe tán láti gbèjà ara mi.” Pọ́ọ̀lù sọ pé irọ́ làwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò sọ tẹ́ńpìlì di aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò mú káwọn èèyàn dìtẹ̀ sí ìjọba. Ó ṣàlàyé pé, “ọ̀pọ̀ ọdún” lòun ti wá sí Jerúsálẹ́mù kẹ́yìn, bóun sì ṣe wá yìí, “ọrẹ àánú” lòun mú wá fáwọn Kristẹni tó ṣeé ṣe kí ìyàn àti inúnibíni ti sọ di aláìní. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé kóun tó wọnú tẹ́ńpìlì, òun “wà ní mímọ́ lọ́nà Òfin” àti pé òun ti sapá gidigidi ‘kí ẹ̀rí ọkàn òun lè mọ́ níwájú Ọlọ́run àti èèyàn.’​—Ìṣe 24:10-13, 16-18.

12 Lóòótọ́, Pọ́ọ̀lù gbà pé òun ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ sí Ọlọ́run àwọn baba ńlá òun ní “ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní ẹ̀ya ìsìn.” Àmọ́, ó tẹnu mọ́ ọn pé òun gba “gbogbo ohun tó wà nínú Òfin gbọ́ àti ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé àwọn Wòlíì.” Ó tún sọ pé bíi tàwọn kan lára àwọn tó fẹ̀sùn kan òun, òun ní ìrètí pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” Pọ́ọ̀lù wá ní káwọn tó fẹ̀sùn kan òun sọ tẹnu wọn, ó ní: “Kí àwọn ọkùnrin tó wà níbí yìí fúnra wọn sọ ohun àìtọ́ tí wọ́n rí nígbà tí mo dúró níwájú Sàhẹ́ndìrìn, àyàfi ohun kan ṣoṣo yìí tí mo ké jáde nígbà tí mo dúró láàárín wọn, pé: ‘Torí àjíǹde àwọn òkú ni wọ́n ṣe ń dá mi lẹ́jọ́ lónìí níwájú yín!’ ”​—Ìṣe 24:14, 15, 20, 21.

13-15. Àwọn nǹkan wo ni Pọ́ọ̀lù ṣe tó jẹ́ ká gbà pé àpẹẹrẹ àtàtà ló jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká fìgboyà jẹ́rìí níwájú àwọn aláṣẹ ìjọba?

13 Ó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó dáa tí Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ìjọba torí ìjọsìn wa, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wá pé a máa ń dá wàhálà sílẹ̀, pé a máa ń ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba tàbí tí wọ́n bá tiẹ̀ sọ pé “ẹgbẹ́ tó ń da ìlú rú” ni wá. Pọ́ọ̀lù ò sọ̀rọ̀ láti fa ojú gómìnà mọ́ra, kò sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ dídún tó jẹ́ ẹ̀tàn bíi ti Tẹ́túlọ́sì. Pọ́ọ̀lù fara balẹ̀ ó sì bọ̀wọ̀ fáwọn tó ń bá sọ̀rọ̀. Bákan náà, ó fọgbọ́n gbé ọ̀rọ̀ ẹ̀ kalẹ̀, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere tó sì jẹ́ òótọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé “àwọn Júù kan láti ìpínlẹ̀ Éṣíà” fẹ̀sùn kan òun pé òun ń sọ tẹ́ńpìlì di aláìmọ́. Àmọ́ wọn ò sí níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Pọ́ọ̀lù wá sọ pé ó yẹ kóun rí wọn, kí wọ́n sì tún ọ̀rọ̀ yẹn sọ lójú òun.​—Ìṣe 24:18, 19.

14 Ohun tó dáa jù tí Pọ́ọ̀lù ṣe ni pé kò bẹ̀rù láti sọ ohun tó gbà gbọ́. Kódà, ó tún fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ tó ní pé àjíǹde wà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ yìí ló dá wàhálà sílẹ̀ nígbà tó wà nílé ẹjọ Sàhẹ́ndìrìn. (Ìṣe 23:6-10) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń gbèjà ara ẹ̀, ó tẹnu mọ́ ìrètí àjíǹde. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ nípa Jésù àti àjíǹde rẹ̀ ni ìwàásù Pọ́ọ̀lù dá lé, àwọn alátakò ẹ̀ ò sì gba ìyẹn gbọ́. (Ìṣe 26:6-8, 22, 23) Èyí jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ nípa bóyá àjíǹde wà tàbí kò sí ló dá wàhálà sílẹ̀, èyí tó sì ń ká wọn lára jù ni ọ̀rọ̀ nípa Jésù àti àjíǹde rẹ̀.

15 Àwa náà lè fìgboyà jẹ́rìí bíi ti Pọ́ọ̀lù, a sì lè rí okun gbà látinú ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Àmọ́ ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.” Ṣó yẹ ká máa ṣàníyàn nípa ohun tá a máa sọ? Rárá o, torí Jésù ti fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Tí wọ́n bá sì ń mú yín lọ láti fà yín léni lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn ṣáájú nípa ohun tí ẹ máa sọ; àmọ́ ohunkóhun tí a bá fún yín ní wákàtí yẹn ni kí ẹ sọ, torí kì í ṣe ẹ̀yin lẹ̀ ń sọ̀rọ̀, ẹ̀mí mímọ́ ni.”​—Máàkù 13:9-13.

“Ẹ̀rù Ba Fẹ́líìsì” (Ìṣe 24:22-27)

16, 17. (a) Nígbà tí Fẹ́líìsì ń gbọ́ ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù, kí ló ṣe? (b) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tẹ́rù fi ba Fẹ́líìsì, kí sì nìdí tó fi ń ránṣẹ́ pe Pọ́ọ̀lù?

16 Kì í ṣe pé Gómìnà Fẹ́líìsì ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́ nípa ohun táwọn Kristẹni gbà gbọ́. Àkọsílẹ̀ yẹn sọ pé: “Fẹ́líìsì mọ̀ nípa Ọ̀nà yìí [ìyẹn orúkọ tí wọ́n fi ń pe àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní] dáadáa, ó sún ẹjọ́ àwọn ọkùnrin náà síwájú, ó sọ pé: ‘Nígbàkigbà tí Lísíà ọ̀gágun bá wá síbí, màá ṣe ìpinnu lórí ọ̀ràn yín.’ Ó wá pàṣẹ fún ọ̀gá àwọn ọmọ ogun pé kí wọ́n fi ọkùnrin náà sí àhámọ́, àmọ́ kí wọ́n fún un ní òmìnira díẹ̀, kí wọ́n sì gba àwọn èèyàn rẹ̀ láyè láti máa bá a ṣe ohun tó bá fẹ́ ṣe.”​—Ìṣe 24:22, 23.

17 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, nígbà tí Fẹ́líìsì àtìyàwó rẹ̀ Dùrùsílà tó jẹ́ Júù jọ wà pa pọ̀, ó ránṣẹ́ pe Pọ́ọ̀lù, ó sì “fetí sí i bó ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.” (Ìṣe 24:24) Àmọ́, nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “òdodo àti ìkóra-ẹni-níjàánu pẹ̀lú ìdájọ́ tó ń bọ̀, ẹ̀rù ba Fẹ́líìsì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn nǹkan tó gbọ́ yẹn ń da ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ láàmú, torí àwọn nǹkan burúkú tó ti ṣe. Ó wá sọ fún Pọ́ọ̀lù pé kó máa lọ, ó ní: “Ṣì máa lọ ná, màá ránṣẹ́ pè ẹ́ nígbà míì tí mo bá ráyè.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Fẹ́líìsì ránṣẹ́ pe Pọ́ọ̀lù lẹ́yìn ìgbà yẹn, àmọ́ torí ó fẹ́ kí Pọ́ọ̀lù fún òun ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ló ṣe ní kó wá, kì í ṣe torí pé ó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.​—Ìṣe 24:25, 26.

18. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi bá Fẹ́líìsì àtìyàwó ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa “òdodo àti ìkóra-ẹni-níjàánu pẹ̀lú ìdájọ́ tó ń bọ̀”?

18 Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi bá Fẹ́líìsì àtìyàwó ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa “òdodo àti ìkóra-ẹni-níjàánu pẹ̀lú ìdájọ́ tó ń bọ̀”? Ẹ rántí pé àwọn nǹkan tá à ń retí pé kẹ́nì kan máa ṣe táá fi hàn pé ó ní “ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù” ni wọ́n fẹ́ mọ̀. Pọ́ọ̀lù mọ̀ wọ́n sẹ́ni tó ń ṣèṣekúṣe, tó ń hùwà ìkà, tí kì í sì í ṣe ìdájọ́ òdodo, torí náà ó fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run ń retí lọ́dọ̀ àwọn tó bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí jẹ́ kí Fẹ́líìsì àtìyàwó ẹ̀ rí ìyàtọ̀ gedegbe tó wà láàárín àwọn ìlànà Ọlọ́run àti ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé. Ó sì yẹ kí ìyẹn ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí i pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa jíhìn fún Ọlọ́run nípa ohun tó ń rò, ọ̀rọ̀ tó ń sọ àti ìwà tó ń hù. Bákan náà, ó yẹ kí wọ́n rí i pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni ẹjọ́ tí Ọlọ́run máa dá fún wọn kì í ṣe ẹjọ́ tí Fẹ́líìsì máa dá fún Pọ́ọ̀lù. Abájọ ‘tẹ́rù fi ba Fẹ́líìsì’!

19, 20. (a) Kí la lè ṣe tó bá jọ pé àwọn tá a wàásù fún nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àmọ́ tí wọn ò ṣe tán láti yí ìgbésí ayé wọn pa dà kó lè bá ẹ̀kọ́ òtítọ́ mu? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé ọ̀rẹ́ ojú lásán ni Fẹ́líìsì ń bá Pọ́ọ̀lù ṣe?

19 A lè bá àwọn èèyàn bíi Fẹ́líìsì pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwáásù. Tá a bá kọ́kọ́ bá wọn sọ̀rọ̀, ó lè jọ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, àmọ́ wọn ò ṣe tán láti yí ìgbésí ayé wọn pa dà kó lè bá ẹ̀kọ́ òtítọ́ mu. Ó yẹ ká ṣọ́ra tá a bá fẹ́ ran irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa náà lè fọgbọ́n sọ àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run fún wọn. Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ wọ̀ wọ́n lọ́kàn, kí wọ́n sì yí ìgbésí ayé wọn pa dà. Àmọ́, tó bá ti ṣe kedere pé wọn ò fẹ́ tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run kí wọ́n sì fi àwọn ìwà burúkú wọn sílẹ̀, a ò ní fipá mú wọn láti yí pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa wá àwọn tó ṣe tán láti sọ òtítọ́ di tiwọn lọ.

20 Ohun tí àkọsílẹ̀ yẹn sọ jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn Fẹ́líìsì gan-an, ó ní: “Lẹ́yìn ọdún méjì, Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì rọ́pò Fẹ́líìsì; àmọ́ torí pé Fẹ́líìsì ń wá ojú rere àwọn Júù, ó fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ nínú àhámọ́.” (Ìṣe 24:27) Ó dájú pé ọ̀rẹ́ ojú lásán ni Fẹ́líìsì ń bá Pọ́ọ̀lù ṣe. Fẹ́líìsì mọ̀ pé àwọn Kristẹni kì í ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọn kì í sì í sún àwọn ẹlòmíì láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 19:23) Bákan náà, ó mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù ò rú òfin ìlú Róòmù kankan. Síbẹ̀, Fẹ́líìsì fi Pọ́ọ̀lù sátìmọ́lé kó lè rí “ojú rere àwọn Júù.”

21. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù lẹ́yìn tí Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì di gómìnà, kí ló sì dájú pé á máa fún Pọ́ọ̀lù lókun?

21 Bá a ṣe rí i nínú ẹsẹ tó gbẹ̀yìn nínú Ìṣe orí 24, Pọ́ọ̀lù ṣì wà lẹ́wọ̀n nígbà tí Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì di gómìnà lẹ́yìn Fẹ́líìsì. Bó ṣe di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú Pọ́ọ̀lù kiri látọ̀dọ̀ aláṣẹ kan lọ sọ́dọ̀ aláṣẹ míì nìyẹn, kí wọ́n lè gbọ́ tẹnu ẹ̀. Ní tòótọ́, wọ́n mú àpọ́sítélì tó nígboyà yìí lọ “síwájú àwọn ọba àti àwọn gómìnà.” (Lúùkù 21:12) Bá a ṣe máa rí i, nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí fún alákòóso tó lágbára jù lọ nígbà yẹn. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ohun tójú Pọ́ọ̀lù rí, ìgbàgbọ́ ẹ̀ ò jó rẹ̀yìn rárá. Ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún un pé kó “Mọ́kàn le!” á máa wà lọ́kàn ẹ̀, á sì máa fún un lókun.

b Tẹ́túlọ́sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Fẹ́líìsì torí pé “àlàáfíà púpọ̀” wà lórílẹ̀-èdè wọn nígbà tó jẹ́ gómìnà. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé kó tó di pé àwọn èèyàn ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba Róòmù, rògbòdìyàn tó wà ní Jùdíà nígbà tí Fẹ́líìsì fi jẹ́ gómìnà pọ̀ ju èyí tó wà nígbà táwọn gómìnà tó jẹ ṣáájú rẹ̀ fi wà lórí oyè. Ohun míì tó tún jẹ́ ẹ̀tàn nínú ohun tí Tẹ́túlọ́sì sọ ni pé nígbà táwọn Júù rí àwọn àtúnṣe tí Fẹ́líìsì ti ṣe, ‘wọ́n dúpẹ́ wọ́n tọ́pẹ́ dá.’ Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló kórìíra Fẹ́líìsì torí pé ó ń ni wọ́n lára, tó sì hùwà ìkà sí wọn nígbà tó dí wọn lọ́wọ́ láti ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba.​—Ìṣe 24:2, 3.