ORÍ 2
“Ẹ Ó sì Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Mi”
Bí Jésù ṣe múra àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n lè múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù
Ó dá lórí Ìṣe 1:1-26
1-3. Báwo ni Jésù ṣe lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ìbéèrè wo ló sì yẹ ká dáhùn?
ÀWỌN àpọ́sítélì gbádùn àwọn ọ̀sẹ̀ alárinrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí náà débi pé wọn ò fẹ́ kó tán! Àjíǹde Jésù sọ ìbànújẹ́ wọn dayọ̀. Ó ti pé ogójì (40) ọjọ́ báyìí tí Jésù ti ń fara hàn wọ́n léraléra, tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, tó sì ń fún wọn níṣìírí. Àmọ́ ọjọ́ tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ló fara hàn wọ́n kẹ́yìn.
2 Níbi tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì dúró sí lórí Òkè Ólífì, wọ́n tẹ́tí sí gbogbo ohun tó bá wọn sọ. Bíi pé kó má parí ọ̀rọ̀ ẹ̀ mọ́ ló rí lójú wọn. Àmọ́, nígbà tó parí ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì tọrọ ìbùkún Ọlọ́run sórí wọn. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gòkè lọ sọ́run! Wọ́n tẹjú mọ́ ọn bó ṣe ń wọnú àwọsánmà lọ. Àmọ́ nígbà tó yá, wọn ò rí i mọ́, síbẹ̀ wọ́n tẹjú mọ́ sánmà.—Lúùkù 24:50; Ìṣe 1:9, 10.
3 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kí ìgbésí ayé àwọn àpọ́sítélì Jésù yí pa da. Kí ni wọ́n máa ṣe ní báyìí tí Ọ̀gá wọn, Jésù Kristi, ti lọ sọ́run? Ó dájú pé Ọ̀gá wọn ti kọ́ wọn dáadáa kó tó fa iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́. Báwo ló ṣe kọ́ wọn láwọn nǹkan tó yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ pàtàkì yìí, ọwọ́ wo làwọn náà sì fi mú iṣẹ́ náà? Báwo ni iṣẹ́ yìí sì ṣe kan àwa Kristẹni lónìí? A máa rí àwọn ìdáhùn tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ ní orí kìíní nínú ìwé Ìṣe.
“Ọ̀pọ̀ Ẹ̀rí Tó Dájú” (Ìṣe 1:1-5)
4. Báwo ni Lúùkù ṣe bẹ̀rẹ̀ ìwé Ìṣe?
4 Ọ̀rọ̀ tí Lúùkù sọ níbẹ̀rẹ̀ ìwé Ìṣe jẹ́ ká rí i pé Tìófílọ́sì ló kọ ọ́ sí, ìyẹn ọkùnrin kan náà tó kọ́ ìwé Ìhìn Rere Lúùkù sí. a Èyí jẹ́ kó ṣe kedere pé ńṣe ló ń bá ọ̀rọ̀ lọ níbi tó bọ́rọ̀ dé. Ó kọ́kọ́ ṣàkópọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ níparí ìwé Ìhìn Rere, ó ṣàlàyé ẹ̀ lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀, ó wá fi àwọn ọ̀rọ̀ tuntun míì kún un.
5, 6. (a) Kí ló máa mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù túbọ̀ lágbára? (b) Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni gbà gbé ìgbàgbọ́ wọn ka “ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó dájú” lónìí?
5 Kí ló máa mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù túbọ̀ lágbára? Ìṣe 1:3 sọ pé: “[Jésù] fara hàn wọ́n láàyè nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó dájú.” Nínú Bíbélì, Lúùkù “oníṣègùn tó jẹ́ olùfẹ́” nìkan ló lo ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí “ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó dájú.” (Kól. 4:14) Àwọn oníṣègùn ló sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí, ó sì túmọ̀ sí ẹ̀rí tó ṣeé gbára lé. Irú ẹ̀rí tí Jésù fúnni nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ó fara han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, nígbà míì ó lè jẹ́ ọ̀kan tàbí méjì lára wọn, ó sì lè jẹ́ gbogbo àwọn àpọ́sítélì, ìgbà kan tiẹ̀ wà tó fara han àwọn tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) lọ lára àwọn tó gba ọ̀rọ̀ ẹ̀ gbọ́. (1 Kọ́r. 15:3-6) Ẹ̀rí tó dájú nìyẹn lóòótọ́!
6 Bákan náà lónìí, orí “ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó dájú” làwọn Kristẹni tòótọ́ gbé ìgbàgbọ́ wọn kà. Ṣé ẹ̀rí tiẹ̀ wà tó fi hàn pé Jésù gbé ayé rí, pé ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, àti pé ó jíǹde? Ó dájú pé ẹ̀rí wà! Àwọn ẹ̀rí tó dájú tá a nílò wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, inú rẹ̀ la ti lè rí ohun táwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn sọ. Tá a bá fara balẹ̀ ka àwọn àkọsílẹ̀ yìí, tá a sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ ká lè fi ohun tá a kọ́ sílò, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára. Má gbàgbé pé tí ẹ̀rí tó dájú bá wà, ó lè mú kéèyàn ní ojúlówó ìgbàgbọ́ dípò táá kàn fi fara mọ́ ohun kan láìsí ẹ̀rí. Tá a bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun, a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tòótọ́.—Jòhánù 3:16.
7. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó bá di ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ kíkọ́ni?
7 Jésù tún “sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run” fáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó fi hàn pé Mèsáyà máa ní láti jìyà kó sì kú. (Lúùkù 24: 13-32, 46, 47) Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà àti Ọba Lọ́la, ó tẹnu mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba Ọlọ́run ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwàásù Jésù, ohun táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lónìí ń tẹnu mọ́ náà nìyẹn bí wọ́n ṣe ń wàásù.—Mát. 24:14; Lúùkù 4:43.
“Dé Ibi Tó Jìnnà Jù Lọ ní Ayé” (Ìṣe 1:6-12)
8, 9. (a) Èrò òdì méjì wo ló wà lọ́kàn àwọn àpọ́sítélì Jésù? (b) Báwo ni Jésù ṣe ran àwọn àpọ́sítélì lọ́wọ́ láti yí èrò wọn pa dà, kí lèyí sì kọ́ àwa Kristẹni lónìí?
8 Nígbà táwọn àpọ́sítélì pé jọ sórí Òkè Ólífì, Jésù bá wọn ṣèpàdé tó ṣe kẹ́yìn pẹ̀lú wọn kó tó kúrò láyé. Wọ́n fi ìtara bi í pé: “Olúwa, ṣé àkókò yìí lo máa dá ìjọba pa dà fún Ísírẹ́lì?” (Ìṣe 1:6) Èrò òdì méjì tó ti wà lọ́kàn àwọn àpọ́sítélì fara hàn nínú ìbéèrè yìí. Àkọ́kọ́ ni pé, wọ́n rò pé Jèhófà máa dá Ìjọba ẹ̀ pa dà fún Ísírẹ́lì tara. Ìkejì sì ni pé, wọ́n ń retí pé kí Ìjọba tí Ọlọ́run ṣèlérí náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tàbí ní “àkókò yìí.” Báwo ni Jésù ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yí èrò wọn pa dà lórí ọ̀rọ̀ yìí?
9 Jésù ti ní láti mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa tó yí èrò àkọ́kọ́ yẹn pa dà. Kódà, lọ́jọ́ mẹ́wàá sígbà yẹn wọ́n máa rí bí Ọlọ́run ṣe máa dá orílẹ̀-èdè tuntun kan sílẹ̀, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Àjọṣe tí Ọlọ́run ní pẹ̀lú Ísírẹ́lì tara ò ní pẹ́ dópin. Ní ti èrò kejì, Jésù fìfẹ́ rán wọn létí pé: “Kì í ṣe tiyín láti mọ ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí ìkáwọ́ rẹ̀.” (Ìṣe 1:7) Olùṣètò Àkókò tó ga jù lọ ni Jèhófà. Kí Jésù tó kú, òun fúnra ẹ̀ sọ pé Ọmọ kò mọ “ọjọ́ àti wákàtí” tí òpin máa dé, “àfi Baba nìkan.” (Mát. 24:36) Torí náà, táwọn Kristẹni lónìí bá ń ṣàníyàn láìyẹ nípa ìgbà tí òpin ètò àwọn nǹkan yìí máa dé, ńṣe ni wọ́n ń da ara wọn láàmú lórí ohun tí kò yẹ.
10. Báwo la ṣe lè fara wé àwọn àpọ́sítélì Jésù, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
10 Àwọn àpọ́sítélì Jésù ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, torí náà kò yẹ ká fojú tí kò dáa wò wọ́n torí èrò tí wọ́n ní. Ó ṣe tán, wọ́n fìrẹ̀lẹ̀ gba ìtọ́ni. Yàtọ̀ síyẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé èrò tí ò dáa tó ló fa ìbéèrè tí wọ́n bi Jésù, ìbéèrè náà tún fi ohun kan tó dáa hàn nípa wọn. Léraléra ni Jésù ti sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́nà.” (Mát. 24:42; 25:13; 26:41) Ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé wọ́n wà lójúfò nípa tẹ̀mí, wọ́n sì ń retí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ti ṣe tán láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ohun kan náà ló sì yẹ ká máa ṣe lónìí. Kódà, “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tá a wà yìí ló mú kó túbọ̀ ṣe pàtàkì pé ká ṣe bẹ́ẹ̀.—2 Tím. 3:1-5.
11, 12. (a) Iṣẹ́ wo ni Jésù gbé fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (b) Kí nìdí tí Jésù fi sọ̀rọ̀ ẹ̀mí mímọ́ nígbà tó ń gbé iṣẹ́ náà fún wọn?
11 Jésù rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ létí ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wọn. Ó sọ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Ìlú Jerúsálẹ́mù táwọn èèyàn ti pa Jésù, ni wọ́n á ti kọ́kọ́ lọ wàásù pé ó ti jíǹde. Látibẹ̀, ìwàásù náà á dé gbogbo àgbègbè Jùdíà, lẹ́yìn náà Samáríà, àti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.
12 Lẹ́yìn tí Jésù ti fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa rán ẹ̀mí mímọ́ sí wọn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù, bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn. Ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbà tó lé ní ogójì (40) tí gbólóhùn náà “ẹ̀mí mímọ́,” fara hàn nínú ìwé Ìṣe nìyẹn. Léraléra ni ìwé Bíbélì tó sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere yìí jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí bá a ṣe lè ṣèfẹ́ Jèhófà láìjẹ́ pé ó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà déédéé pé kí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́! (Lúùkù 11:13) Àkókò yìí gan-an la sì nílò rẹ̀ jù lọ.
13. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run gbé fáwa èèyàn rẹ̀ ṣe gbòòrò tó lónìí, kí sì nìdí tó fi yẹ ká fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ náà?
13 Ohun tí gbólóhùn náà, “ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé” túmọ̀ sí nígbà yẹn ti yí pa dà báyìí. Àmọ́, bá a ṣe rí i ní orí kìíní ìwé yìí, tọkàntọkàn làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù, torí a mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ kí onírúurú èèyàn gbọ́ ìhìn rere nípa Ìjọba náà. (1 Tím. 2:3, 4) Ṣé tọkàntọkàn nìwọ náà fi ń ṣe iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí? Ó dájú pé kò sí iṣẹ́ míì tó lè tẹ́ni lọ́rùn, tó sì lè fini lọ́kàn balẹ̀ bíi ti iṣẹ́ ìwàásù! Jèhófà máa fún ẹ ní agbára tó o nílò kó o lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. Kó o lè di ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ yìí, ìwé Ìṣe máa jẹ́ kó o mọ oríṣiríṣi ọ̀nà tó o lè gbà ṣe é àti irú èrò tó yẹ kó o ní bó o ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà.
14, 15. (a) Kí làwọn áńgẹ́lì náà sọ nípa bí Kristi ṣe máa pa dà wá, kí nìyẹn sì túmọ̀ sí? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Báwo ni Kristi ṣe pa dà wá “ní irú ọ̀nà kan náà” tó gbà lọ?
14 Bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí, nígbà tí Jésù ń kúrò láyé, àwọsánmà gbà á kúrò lójú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọn ò sì rí i mọ́. Àmọ́, àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá náà ṣì dúró, wọ́n ń wo ojú sánmà. Nígbà tó yá, áńgẹ́lì méjì yọ sí wọn, wọ́n sì tún èrò wọn ṣe. Wọ́n sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn Gálílì, kí ló dé tí ẹ dúró tí ẹ̀ ń wojú sánmà? Jésù yìí tí a gbà sókè kúrò lọ́dọ̀ yín sínú sánmà yóò wá ní irú ọ̀nà kan náà bí ẹ ṣe rí i tó ń lọ sínú sánmà.” (Ìṣe 1:11) Ṣóhun táwọn áńgẹ́lì yẹn ń sọ ni pé irú ara tí Jésù gbé lọ sọ́run náà ló máa gbé pa dà wá bí àwọn onísìn kan ṣe sọ? Rárá o. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
15 Àwọn áńgẹ́lì yẹn ò sọ pé bí Jésù ṣe rí nígbà tó lọ náà ló ṣe máa rí nígbà tó bá pa dà wá; ohun tí wọ́n sọ ni pé ó máa pa dà wá “ní irú ọ̀nà kan náà.” b Tó bá rí bẹ́ẹ̀, irú ọ̀nà wo ló gbà lọ? Àwọsánmà ti gbà á kúrò lójú àwọn ọmọlẹ́yìn káwọn áńgẹ́lì náà tó sọ̀rọ̀. Ìwọ̀nba àwọn àpọ́sítélì yẹn ló mọ̀ pé Jésù ti kúrò láyé, tó sì ti lọ sọ́dọ̀ Baba rẹ̀ lókè ọ̀run. Bó ṣe máa rí náà nìyẹn nígbà tí Kristi bá pa dà wá. Ó sì ti rí bẹ́ẹ̀ báyìí. Lónìí, ìwọ̀nba àwọn tó lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, tí wọ́n sì ń fọkàn sí bó ṣe ń ṣẹ lásìkò wà yìí nìkan ló mọ̀ pé Jésù ti pa dà wá nínú agbára Ìjọba. (Lúùkù 17:20) Ó yẹ ká máa fọkàn sí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù ti wà níhìn-ín, ká sì máa sọ ọ́ fáwọn èèyàn, kí wọ́n lé rí i pé ó yẹ káwọn tètè wá sin Jèhófà kó tó pẹ́ jù.
Ìṣe 1:13-26)
“Fi Ẹni Tí O Yàn . . . Hàn” (16-18. (a) Kí la rí kọ́ nínú Ìṣe 1:13, 14, nípa báwọn Kristẹni ṣe máa ń kóra jọ láti jọ́sìn? (b) Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Màríà ìyá Jésù? (d) Kí nìdí táwọn ìpàdé Kristẹni fi ṣe pàtàkì lónìí?
16 Ohun táwọn àpọ́sítélì yẹn gbọ́ fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, “inú wọn sì dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń pa dà sí Jerúsálẹ́mù.” (Lúùkù 24:52) Àmọ́, báwo ni wọ́n á ṣe máa fi àwọn nǹkan tí Kristi kọ́ wọn sílò? Ní ẹsẹ 13 àti 14 nínú Ìṣe orí 1, a rí i pé wọ́n pàdé nínú “yàrá òkè,” a sì ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan ìyanu tó ṣẹlẹ̀ nírú ìpàdé bẹ́ẹ̀. Àwọn ilé tí wọ́n ń kọ́ ní Palẹ́sìnì nígbà yẹn sábà máa ń ní yàrá lókè, ìta sì ni àtẹ̀gùn tí wọ́n máa ń gbà dénú àwọn yàrá náà máa ń wà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “yàrá òkè” tí Ìṣe 12:12 sọ pé ó wà nílé ìyá Máàkù ni ibí yìí ń sọ. Èyí ó wù kó jẹ́, yàrá yìí jẹ́ ibì kan tó mọ níwọ̀n, táwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ti lè pàdé. Àmọ́, àwọn wo ló wà nínú yàrá náà, kí ni wọ́n sì ṣe níbẹ̀?
17 Kíyè sí i pé kì í ṣe àwọn àpọ́sítélì tàbí àwọn ọkùnrin nìkan ló wà nínú yàrá náà. “Àwọn obìnrin kan” náà wà níbẹ̀, kódà Màríà ìyá Jésù wà lára wọn. Ibí yìí ni Bíbélì ti mẹ́nu kan Màríà ní tààràtà kẹ́yìn. Ó sì bọ́gbọ́n mu láti gbà pé kò ní máa wá ipò ọlá níbẹ̀, àmọ́ ńṣe láá máa fìrẹ̀lẹ̀ jọ́sìn Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀. Ó dájú pé inú ẹ̀ máa dùn gan-an bó ṣe rí i táwọn ọmọkùnrin ẹ̀ mẹ́rin tó kù, tí wọn ò tíì di onígbàgbọ́ nígbà tí Jésù wà láyé ti wà di onígbàgbọ́, tí wọ́n sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀. (Mát. 13:55; Jòhánù 7:5) Látìgbà tí Jésù tó jẹ́ ọmọ ìyá wọn ti kú tó sì ti jíǹde ni wọ́n ti yí pa dà.—1 Kọ́r. 15:7.
18 Jẹ́ ká wo ìdí míì táwọn àpọ́sítélì náà fi kóra jọ, Bíbélì sọ pé: “Gbogbo wọn tẹra mọ́ àdúrà pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan.” (Ìṣe 1:14) Irú ìkórajọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ apá tó ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn àwa Kristẹni. A máa ń kóra jọ ká lè fún ara wa níṣìírí, ká lè gba ìtọ́ni ká sì gbọ́rọ̀ ìyànjú, ní pàtàkì jù lọ, a máa ń pàdé pọ̀ ká lè jọ́sìn Jèhófà, Baba wa ọ̀run. Àdúrà àtàwọn orin ìyìn tá a máa ń kọ nírú àkókò bẹ́ẹ̀ máa ń múnú Ọlọ́run dùn gan-an, wọ́n sì ṣe pàtàkì sí wa. Ǹjẹ́ ká má ṣe kọ àwọn àpéjọ mímọ́, tó ń gbéni ró yìí sílẹ̀ láé!—Héb. 10:24, 25.
19-21. (a) Kí la rí kọ́ látinú iṣẹ́ ribiribi tí Pétérù gbé ṣe nínú ìjọ? (b) Kí nìdí tí ẹlòmíì fi gbọ́dọ̀ rọ́pò Júdásì, kí la sì lè rí kọ́ nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà bójú tó ọ̀rọ̀ náà?
19 Ohun tó yẹ káwọn ọmọlẹ́yìn Kristi yẹn ṣe báyìí ni pé kí wọ́n ṣètò ara wọn láti jọ́sìn, àpọ́sítélì Pétérù ò sì gbẹ́yìn láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí. (Ẹsẹ 15-26) Ẹ ò rí i pé ó fi ni lọ́kàn balẹ̀ gan-an láti rí i pé Pétérù tó sẹ́ Jésù nígbà mẹ́tà lọ́sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn, ti wá tẹ̀ síwájú débi tó fi lè nírú àǹfààní yìí. (Máàkù 14:72) Gbogbo wa la lè dẹ́ṣẹ̀, torí náà ó yẹ ká máa rán ara wa létí pé ‘ẹni rere ni Jèhófà, ó sì ṣe tán láti dárí ji’ ẹni tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.—Sm. 86:5.
20 Pétérù mọ̀ pé ó yẹ kí ẹlòmíì rọ́pò Júdásì, ìyẹn àpọ́sítélì tó da Jésù. Àmọ́ ta ló máa jẹ́? Ẹni náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń tẹ̀ lé Jésù ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí àjíǹde Jésù. (Ìṣe 1:21, 22) Ìyẹn sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jésù ṣèlérí pé: “Ẹ̀yin tí ẹ ti tẹ̀ lé mi máa jókòó sórí ìtẹ́ méjìlá (12), ẹ sì máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì.” (Mát. 19:28) Ó dájú pé Jèhófà fẹ́ káwọn àpọ́sítélì méjìlá tí wọ́n tẹ̀ lé Jésù nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ di “òkúta ìpìlẹ̀ méjìlá” Jerúsálẹ́mù Tuntun. (Ìfi. 21:2, 14) Torí náà, Ọlọ́run jẹ́ kí Pétérù rí i pé Júdásì ni àsọtẹ́lẹ̀ náà, “kí ẹlòmíì gba iṣẹ́ àbójútó rẹ̀,” ṣẹ sí lára.—Sm. 109:8.
21 Báwo ni wọ́n ṣe yan ẹni tó rọ́pò Júdásì? Ńṣe ni wọ́n ṣẹ́ kèké, àṣà yìí sì wọ́pọ̀ lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. (Òwe 16:33) Àmọ́, ìyẹn ni ìgbà tó kẹ́yìn tí Bíbélì fi hàn pé wọ́n ṣẹ́ kèké lọ́nà yìí. Ó dájú pé bí Ọlọ́run ṣe tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọlẹ́yìn nígbà tó yá ló wá fòpin sí i pátápátá. Àmọ́, kí ni ìdí tí wọ́n fi ṣẹ́ kèké yẹn? Àwọn àpọ́sítélì gbàdúrà pé: “Jèhófà, ìwọ ẹni tó mọ ọkàn gbogbo èèyàn, fi ẹni tí o yàn lára àwọn ọkùnrin méjì yìí hàn.” (Ìṣe 1:23, 24) Ńṣe ni wọ́n fẹ́ kí Jèhófà fúnra ẹ̀ yan ẹni náà. Màtáyásì, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àádọ́rin (70) tí Jésù rán jáde láti lọ wàásù, ni Ọlọ́run yàn. Bí Màtáyásì ṣe di ọ̀kan lára “àwọn Méjìlá” náà nìyẹn. c—Ìṣe 6:2.
22, 23. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹrí ba ká sì máa ṣègbọràn sáwọn tó jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ lónìí?
22 Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣe nǹkan létòlétò. Títí di báyìí, à ń yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ. Àwọn alàgbà máa ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ pé ó yẹ kí ẹnì kan ṣe kó tó lè di alábòójútó, wọ́n á sì gbàdúrà pé kí Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tọ́ wọn sọ́nà. Torí náà, àwọn ará ìjọ gbà pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń yan àwọn tó jẹ́ alábòójútó. Ní tiwa, à ń bá a lọ láti máa tẹrí ba fáwọn alábòójútó yìí, a sì ń ṣègbọràn sí wọn, èyí sì ń mú kí ìṣọ̀kan túbọ̀ máa wà nínú ìjọ.—Héb. 13:17.
23 Ní báyìí, ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn ti túbọ̀ lágbára torí pé wọ́n rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde, àwọn àtúnṣe tí wọ́n ṣe sì ti mú kí nǹkan wà létòlétò nínú ìjọ. Torí náà, wọ́n ti múra tán láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó wà nílẹ̀ fún wọn láti ṣe. Orí tó kàn máa jíròrò ohun mánigbàgbé tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà.
a Nínú ìwé Ìhìn Rere tí Lúùkù kọ, ó pe ọkùnrin yìí ní “Tìófílọ́sì ọlọ́lá jù lọ,” èyí mú káwọn kan gbà pé Tìófílọ́sì ní láti jẹ́ èèyàn pàtàkì kan tí ò tíì di onígbàgbọ́ nígbà yẹn. (Lúùkù 1:3) Àmọ́, nígbà tó ń kọ ìwé Ìṣe, ó pè é ní “Tìófílọ́sì.” Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Tìófílọ́sì ka ìwé Ìhìn Rere Lúùkù ló di onígbàgbọ́; torí náà Lúùkù ò fi èdè àpọ́nlé kún orúkọ rẹ̀ mọ́, ńṣe ló kàn bá a sọ̀rọ̀ bí arákùnrin rẹ̀.
b Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Bíbélì lò níbí yìí ni troʹpos, tó túmọ̀ sí “irú ọ̀nà,” kì í ṣe mor·pheʹ, tó túmọ̀ sí “ìrísí.”
c Nígbà tó yá, a yan Pọ́ọ̀lù láti jẹ́ “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” àmọ́ kò sígbà kan tí wọ́n kà á mọ́ àwọn Méjìlá náà. (Róòmù 11:13; 1 Kọ́r. 15:4-8) Pọ́ọ̀lù ò kúnjú ìwọ̀n láti ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ yẹn torí pé kò sí lára àwọn tó tẹ̀ lé Jésù nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé.