ORÍ 3
Wọ́n “Kún fún Ẹ̀mí Mímọ́”
Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọlẹ́yìn ní Pẹ́ńtíkọ́sì
Ó dá lórí Ìṣe 2:1-47
1. Ṣàlàyé bí nǹkan ṣe máa ń rí nígbà Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì.
ŃṢE ni inú àwọn èèyàn ń dùn ní gbogbo ojú ọ̀nà tó wà nílùú Jerúsálẹ́mù. a Bí èéfín ṣe ń rú jáde látorí pẹpẹ tó wà nínú tẹ́ńpìlì, bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọ Léfì ń kọrin Hálẹ́lì (Sáàmù 113 sí 118), ó sì ṣeé ṣe káwọn aráàlú máa bá wọn kọ orin náà. Àwọn àlejò pọ̀ gan-an lójú ọ̀nà. Ibi tó jìnnà sí Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ti wá, irú bí Élámù, Mesopotámíà, Kapadókíà, Pọ́ńtù, Íjíbítì àti Róòmù. b Kí ni wọ́n wá ṣe? Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì, tí wọ́n tún ń pè ní “ọjọ́ àkọ́pọ́n èso,” ni wọ́n wá ṣe. (Nọ́ń. 28:26) Àjọyọ̀ yìí ni wọ́n fi máa ń parí ìkórè ọkà báálì, tí wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í kórè wíìtì. Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ yẹn máa ń jẹ́!
2. Ohun ìyanu wo ló ṣẹlẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?
2 Ní nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ọjọ́ àjọyọ̀ yẹn lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ohun àgbàyanu kan ṣẹlẹ̀ tó ṣì ń ya ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu títí di àkókò wa yìí. Lójijì, “ariwo kan dún láti ọ̀run, ó dà bíi ti atẹ́gùn líle tó ń rọ́ yìì,” tàbí bí “ìró ẹfúùfú líle.” (Ìṣe 2:2; Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ariwo yìí kún inú ilé tí nǹkan bí ọgọ́fà (120) àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wà. Lẹ́yìn ìyẹn, ohun ìyanu kan tún ṣẹlẹ̀. Wọ́n rí àwọn ohun tó jọ iná tó rí bí ahọ́n, ó sì ń bà lé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà. c Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà “kún fún ẹ̀mí mímọ́,” wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ oríṣiríṣi èdè àjèjì! Bí wọ́n ṣe ń kúrò nínú ilé náà, ńṣe lẹnu ń ya gbogbo àwọn àlejò tó rí wọn láwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù, nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn àpọ́sítélì náà ń bá wọn sọ̀rọ̀! Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ń gbọ́ tí “wọ́n ń sọ èdè rẹ̀.”—Ìṣe 2:1-6.
3. (a) Kí ló mú kí Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni jẹ́ ọjọ́ pàtàkì nínú ìtàn ìjọsìn tòótọ́? (b) Báwo ni Pétérù ṣe lo “kọ́kọ́rọ́ Ìjọba ọ̀run” lọ́jọ́ yẹn?
3 Ọjọ́ pàtàkì lọjọ́ yẹn jẹ́ nínú ìtàn ìjọsìn tòótọ́, torí pé ọjọ́ yẹn ni Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í yàn àwọn tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ìyẹn ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. (Gál. 6:16) Kò tán síbẹ̀ o. Nígbà tí Pétérù ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ yẹn, ó lo àkọ́kọ́ lára kọ́kọ́rọ́ mẹ́ta tí Jésù pè ní “àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba ọ̀run.” Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kọ́kọ́rọ́ yìí máa mú kó ṣeé ṣe fún àwùjọ èèyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ní àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (Mát. 16:18, 19) Kọ́kọ́rọ́ àkọ́kọ́ yìí mú kó ṣeé ṣe fáwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe láti gba ìhìn rere, kí Ọlọ́run sì fẹ̀mí yàn wọ́n. d Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n di ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí, wọ́n á sì máa retí ìgbà tí wọ́n máa di ọba àti àlùfáà nínú Ìjọba Mèsáyà. (Ìfi. 5:9, 10) Tó bá yá, àwọn ará Samáríà àtàwọn Kèfèrí náà máa nírú àǹfààní yẹn. Kí làwa Kristẹni òde òní lè rí kọ́ látinú ohun pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?
“Gbogbo Wọn Wà Níbì Kan Náà” (Ìṣe 2:1-4)
4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni ìjọ Kristẹni òde òní bẹ̀rẹ̀?
4 Látorí ọgọ́fà (120) ọmọ ẹ̀yìn, tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró, tí wọ́n sì “wà níbì kan náà” nínú yàrá òkè, ni ìjọ Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 2:1) Lẹ́yìn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ṣèrìbọmi, wọ́n sì di ara ìjọ Kristẹni. Bí ètò kan tó ṣì ń tẹ̀ síwájú títí di báyìí ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn! Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ìyẹn àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni òde òní, ló ń “wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè,” kí òpin ètò àwọn nǹkan yìí tó dé.—Mát. 24:14.
5. Àǹfààní wo làwọn èèyàn ń rí bí wọ́n ṣe ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti lóde òní?
5 Àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni á máa rí okun gbà níbẹ̀, bóyá wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí ara àwọn “àgùntàn mìíràn” tó dara pọ̀ mọ́ wọn nígbà tó yá. (Jòh. 10:16) Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun mọrírì bí àwọn ará ṣe ń ti ara wọn lẹ́yìn nígbà tó kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Àárò yín ń sọ mí, kí n lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, kí ẹ lè fìdí múlẹ̀; àbí, ká kúkú sọ pé, ká jọ fún ara wa ní ìṣírí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, tiyín àti tèmi.”—Róòmù 1:11, 12.
6, 7. Báwo ni ìjọ Kristẹni òde òní ṣe ń tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa fún wọn pé kí wọ́n wàásù fáwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè?
6 Ohun tí ìjọ Kristẹni wà fún ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà ló ṣì wà fún lóde òní. Jésù gbé iṣẹ́ kan fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Iṣẹ́ náà máa múnú wọn dùn, síbẹ̀ wọ́n máa kojú ìṣòro tí wọ́n bá ń ṣe é. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mát. 28:19, 20.
7 Ìjọ Kristẹni ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Ọlọ́run ń lò láti ṣe iṣẹ́ yẹn lóde òní. Lóòótọ́, kò rọrùn láti wàásù fáwọn èèyàn tí èdè wọn yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, áwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ. Tó o bá ń lọ sípàdé ìjọ déédéé, tó o sì ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn, ó yẹ kí inú rẹ máa dùn. Ìwọ náà wà lára ìwọ̀nba èèyàn tó wà láyé lónìí, tí wọ́n láǹfààní láti máa jẹ́rìí kúnnákúnná nípa orúkọ Jèhófà!
8. Báwo ni ìjọ Kristẹni ṣe ń ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà níbẹ̀ láǹfààní?
8 Ká lè máa láyọ̀ bá a ṣe ń fara da àkókò tó le gan-an tá à ń gbé yìí, Jèhófà Ọlọ́run ti fún wa ní ẹgbẹ́ ará kárí ayé láti ràn wá lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù pé: “Ẹ . . . jẹ́ ká gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn kan, àmọ́ ká máa gba ara wa níyànjú, ní pàtàkì jù lọ bí ẹ ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Héb. 10:24, 25) Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìjọ Kristẹni, torí pé a máa ń fún ara wa níṣìírí níbẹ̀. Torí náà, máa sún mọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kó o sì máa lọ sípàdé déédéé.
Ìṣe 2:5-13)
“Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Wọn Ń Gbọ́ Tí Wọ́n Ń Sọ Èdè Rẹ̀” (9, 10. Kí làwọn kan ṣe kí wọ́n lè wàásù fáwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwọn?
9 Fojú inú wo bí inú ọ̀pọ̀ àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe ṣe máa dùn tó ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ó ṣeé ṣe kí èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn gbọ́ èdè Gíríìkì tàbí èdè Hébérù. Àmọ́, “ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ń gbọ́ tí [àwọn ọmọ ẹ̀yìn] ń sọ èdè rẹ̀.” (Ìṣe 2:6) Ó dájú pé ìhìn rere náà máa wọ àwọn èèyàn yẹn lọ́kàn gan-an torí pé èdè ìbílẹ̀ wọn làwọn ọmọ ẹ̀yìn náà fi ń bá wọn sọ̀rọ̀. Àmọ́ o, Ọlọ́run ò fún àwọn Kristẹni òde òní lẹ́bùn láti máa sọ èdè míì lọ́nà ìyanu. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ti yọ̀ǹda ara wọn láti mú ìhìn rere náà lọ sọ́dọ̀ onírúurú èèyàn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwọn. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é? Àwọn kan ti kọ́ èdè míì kí wọ́n lè lọ sìn níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àjèjì ládùúgbò wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ lọ sílẹ̀ òkèèrè pàápàá. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n ti rí i pé àwọn tí wọ́n ń wàásù fún máa ń mọyì gbogbo ohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n lè kọ́ èdè náà.
10 Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Christine, tí òun àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méje míì kọ́ èdè Gujarati. Nígbà tó rí i pé ọ̀dọ́bìnrin kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ gbọ́ èdè Gujarati, ó fi èdè ìbílẹ̀ ọ̀dọ́bìnrin náà kí i. Inú ọ̀dọ́bìnrin náà dùn gan-an, ó sì fẹ́ mọ ìdí tí Christine fi ń sapá láti kọ́ èdè Gujarati. Torí náà, Christine lo àǹfààní yẹn láti wàásù fún un. Ọ̀dọ́bìnrin yẹn wá sọ fún Christine pé: “Kò sí ẹ̀sìn míì tó lè fún àwọn ọmọ ìjọ wọn níṣìírí pé kí wọ́n lọ kọ́ irú èdè tó ṣòro bẹ́ẹ̀. Ó ní láti jẹ́ pé ohun pàtàkì kan wà tẹ́ ẹ fẹ́ sọ fáwọn èèyàn.”
11. Ọ̀nà wo la lè gbà múra sílẹ̀ ká lè wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fáwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa?
11 Òótọ́ ni pé gbogbo wa kọ́ la lè kọ́ èdè míì. Síbẹ̀, a lè múra sílẹ̀ ká lè wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fáwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe é ni pé ká lo ètò orí kọ̀ǹpútà náà JW Language®. A lè lò ó láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń kí àwọn èèyàn ní èdè táwọn èèyàn gbọ́ ládùúgbò wa. A tún lè lò ó láti kọ́ bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa lọ́nà táá fi wu àwọn tí kò gbọ́ èdè wa láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bákan náà, a lè ní kí wọ́n lọ sórí ìkànnì jw.org, a sì lè fi oríṣiríṣi fídíò àtàwọn ìwé hàn wọ́n lórí ìkànnì náà lédè wọn. Tá a bá ń lo àwọn nǹkan yìí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ọ̀rọ̀ tiwa náà máa dà bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ńṣe ni inú wọn ń dùn nígbà tí wọ́n wàásù ìhìn rere fáwọn tó ń sọ èdè àjèjì, torí ‘ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èèyàn náà gbọ́ tí wọ́n ń sọ èdè rẹ̀.’
“Pétérù Dìde Dúró” (Ìṣe 2:14-37)
12. (a) Kí ni wòlíì Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun ìyanu tó ṣẹlẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni? (b) Kí nìdí tí kò fi yani lẹ́nu pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Jóẹ́lì sọ ṣẹ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?
12 “Pétérù dìde dúró” láti bá àwọn èèyàn tó wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè yẹn sọ̀rọ̀. (Ìṣe 2:14) Ó ṣàlàyé fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé Ọlọ́run ló fún àwọn ní agbára láti sọ onírúurú èdè lọ́nà ìyanu, kí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jóẹ́lì sọ lè ṣẹ, pé: “Èmi yóò tú ẹ̀mí mi sára onírúurú èèyàn.” (Jóẹ́lì 2:28) Kí Jésù tó lọ sọ́run, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Màá béèrè lọ́wọ́ Baba, ó sì máa fún yín ní olùrànlọ́wọ́ míì,” olùrànlọ́wọ́ yìí ni Jésù wá pè ní “ẹ̀mí,” ìyẹn ẹ̀mí mímọ́.—Jòh. 14:16, 17.
13, 14. Báwo ni Pétérù ṣe mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn, báwo la sì ṣe lè fara wé e?
13 Pétérù sojú abẹ níkòó nígbà tó ń parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájú pé, Jésù yìí tí ẹ kàn mọ́gi ni Ọlọ́run fi ṣe Olúwa àti Kristi.” (Ìṣe 2:36) Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù ò sí níbẹ̀ nígbà tí wọ́n kan Jésù mọ́ òpó igi oró. Síbẹ̀, gbogbo wọn ló jẹ̀bi bí wọ́n ṣe pa Jésù. Àmọ́, ẹ kíyè sí i pé Pétérù bá àwọn Júù bíi tiẹ̀ yẹn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Pétérù ò bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀ torí kó lè dá wọn lẹ́bi, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló fẹ́ kí wọ́n ronú pìwà dà. Ṣé àwọn èèyàn náà bínú sí ọ̀rọ̀ tí Pétérù bá wọn sọ? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lọ̀rọ̀ náà “gún wọn dé ọkàn.” Wọ́n wá béèrè pé: “Kí ni ká ṣe?” Ó dájú pé bí Pétérù ṣe bá wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ló jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀ wọ púpọ̀ nínú wọn lọ́kàn, tí wọ́n sì ronú pìwà dà.—Ìṣe 2:37.
14 Àwa náà lè ṣe bíi ti Pétérù, ká máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn, kì í ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu làá máa ta kò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ká wá ibi tí ọ̀rọ̀ wa ti jọra. Tá a bá ti ríbi tí ọ̀rọ̀ wa ti jọra, a wá lè fọgbọ́n bá wọn fèrò wérò látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá gbé ọ̀rọ̀ wa ka ohun tí àwa àtàwọn tá à ń wàásù fún jọ gbà gbọ́, á rọrùn fún wọn láti tẹ́tí sí wa.
“Kí A . . . Batisí Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Yín” (Ìṣe 2:38-47)
15. (a) Kí ni Pétérù sọ, kí làwọn èèyàn náà sì ṣe? (b) Kí nìdí tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó gbọ́ ìhìn rere ní Pẹ́ńtíkọ́sì fi kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi lọ́jọ́ kan náà?
15 Lọ́jọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Pétérù sọ fáwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tí ìhìn rere wọ̀ lọ́kàn pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín.” (Ìṣe 2:38) Lẹ́yìn tó sọ̀rọ̀ yìí tán, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn jáde wá láti ṣe batisí, ó sì lè jẹ́ láwọn odò tó wà ní Jerúsálẹ́mù tàbí nítòsí rẹ̀ ni wọ́n ti ṣe é. e Ṣéyẹn ò ti yá jù? Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kọ́ wa pé ńṣe ló yẹ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ọmọ wa máa kánjú ṣèrìbọmi? Rárá o. Ká má gbàgbé pé ẹni tó ń fi tọkàntọkàn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làwọn Júù àtàwọn Júù aláwọ̀ṣe tó ṣe batisí ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, wọ́n sì jẹ́ ara orílẹ̀-èdè tó ti ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti máa ń fi ìtara jọ́sìn Ọlọ́run, àpẹẹrẹ kan ni bí wọ́n ṣe máa ń rin ọ̀nà tó jìn lọ síbi àjọyọ̀ ọdọọdún yìí. Lẹ́yìn tí wọ́n ti lóye òtítọ́ tó ṣe pàtàkì nípa bí Ọlọ́run ṣe lo Jésù Kristi láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, wọ́n ti ṣe tán láti máa sin Ọlọ́run nìṣó, bí ọmọlẹ́yìn Kristi tá a ti batisí.
16. Báwo làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe fi hàn pé àwọn lẹ́mìí ìfara-ẹni-rúbọ?
16 Ó dájú pé Jèhófà bù kún àwọn èèyàn yẹn. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Gbogbo àwọn tó di onígbàgbọ́ wà pa pọ̀, wọ́n sì jọ ń lo gbogbo ohun tí wọ́n ní, wọ́n ń ta àwọn ohun ìní àti dúkìá wọn, wọ́n sì ń pín owó tí wọ́n rí níbẹ̀ fún gbogbo wọn, bí ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nílò bá ṣe pọ̀ tó.” f (Ìṣe 2:44, 45) Ó dájú pé, gbogbo Kristẹni tòótọ́ ló yẹ kó fara wé ẹ̀mí ìfẹ́ àti ti ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n ní.
17. Kí làwọn nǹkan téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi?
17 Kí Kristẹni kan tó lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ kó sì ṣèrìbọmi, ó pọn dandan kó ṣe àwọn nǹkan kan tí Ìwé Mímọ́ sọ. Ẹni náà gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Jòh. 17:3) Ó gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́, kó ronú pìwà dà, kó sì fi hàn pé tọkàntọkàn lòun kábàámọ̀ àwọn ìwà tí kò dáa tó ti hù. (Ìṣe 3:19) Bákan náà ó ní láti yí pa dà, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn iṣẹ́ rere tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Róòmù 12:2; Éfé. 4:23, 24) Lẹ́yìn ìyẹn, á wá gbàdúrà sí Ọlọ́run láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún un, á sì ṣèrìbọmi.—Mát. 16:24; 1 Pét. 3:21.
18. Àǹfààní wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tó ti ṣèrìbọmi ní?
18 Ṣé ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi tó ti yara ẹ̀ sí mímọ́ tó sì ti ṣèrìbọmi ni ẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó o mọyì àǹfààní tó o ní. Bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n kún fún ẹ̀mí mímọ́, Jèhófà lè lo ìwọ náà lọ́nà tó jọni lójú láti jẹ́rìí kúnnákúnná, kó o sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀!
a Wo àpótí náà, “ Jerúsálẹ́mù—Ojúkò Ẹ̀sìn Àwọn Júù.”
b Wo àwọn àpótí wọ̀nyí, “ Róòmù—Olú Ìlú Ilẹ̀ Ọba Kan,” “ Àwọn Júù Tó Wà ní Mesopotámíà àti Íjíbítì,” àti “ Ẹ̀sìn Kristẹni Nílùú Pọ́ńtù.”
c Iná gidi kọ́ ni “ahọ́n” tó bà lé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà, kàkà bẹ́ẹ̀ Bíbélì sọ pé ó “jọ iná,” èyí fi hàn pé ńṣe ni ohun tó bà lé wọn dà bí iná tó ń jó.
d Wo àpótí náà, “ Àwọn Wo Ni Aláwọ̀ṣe?.”
e Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn nígbà táwọn èèyàn ẹgbẹ̀rún méje àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé méjì (7,402) ṣèrìbọmi nínú odò mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní àpéjọ àgbáyé kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nílùú Kiev, lórílẹ̀-èdè Ukraine ní August 7, 1993. Wákàtí méjì àti ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n fi ṣe ìrìbọmi náà.