APÁ 7 • ÌṢE 18:23–21:17
Wọ́n Ń Kọ́ni “ní Gbangba àti Láti Ilé dé Ilé”
Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká sì máa mú ọ̀rọ̀ wa bá ipò onírúurú èèyàn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mu? Ọ̀nà pàtàkì wo la gbà ń wàásù ìhìn rere? Báwo la ṣe lè fi hàn pé ó ṣe pàtàkì ká máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ju ká tẹ́ ara wa lọ́rùn lọ? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí nínú àkọsílẹ̀ tó ń múnú ẹni dùn nípa ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí Pọ́ọ̀lù rìn kẹ́yìn.