ORÍ 20
“Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Gbilẹ̀ Nìṣó, Ó sì Ń Borí” Lójú Àtakò
Ohun tí Àpólò àti Pọ́ọ̀lù ṣe kí ìhìn rere lè máa tẹ̀ síwájú
Ó dá lórí Ìṣe 18:23–19:41
1, 2. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ní Éfésù? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí yìí?
INÚ ń bí àwọn ará ìlú Éfésù, bí wọ́n ṣe ń pariwo bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn ń sáré gìrìgìrì. Àwọn jàǹdùkú ti kóra jọ, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í da ìlú rú! Wọ́n mú méjì lára àwọn tó ń bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò, wọ́n sì ń wọ́ wọn lọ. Àwọn tó ń tajà nínú àwọn ṣọ́ọ̀bù tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà fi ọjà wọn sílẹ̀, gbogbo wọn sì ń fìbínú rọ́ wọnú gbọ̀ngàn ìwòran ńlá tó wà nílùú náà, èyí tó lè gba ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) èèyàn. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn náà ò tiẹ̀ mọ ohun tó fa wàhálà yìí, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí wọ́n rò pé ohun táwọn kan ń sọ nípa tẹ́ńpìlì wọn àti abo òrìṣà Átẹ́mísì tí wọ́n yàn láàyò ló fà á. Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo léraléra pé: “Títóbi ni Átẹ́mísì àwọn ará Éfésù!”—Ìṣe 19:34.
2 A tún rí bí Sátánì ṣe fẹ́ lo àwọn jàǹdùkú láti dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dúró. Àmọ́, kì í ṣe ìwà ipá nìkan ni Sátánì máa ń lò láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú orí yìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí Sátánì lò láti dá iṣẹ́ ìwàásù dúró ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àtohun tó ṣe kó lè ba ìṣọ̀kan àwọn Kristẹni jẹ́. Ní pàtàkì, a máa rí i pé gbogbo ọgbọ́n rẹ̀ ló ti kùnà, torí pé “Ọ̀rọ̀ Jèhófà ń gbilẹ̀ nìṣó, ó sì ń borí lọ́nà tó lágbára.” (Ìṣe 19:20) Kí ló jẹ́ káwọn Kristẹni yẹn borí Sátánì? Ohun tó ń jẹ́ káwa náà borí ẹ̀ lónìí náà ni. Jèhófà ló ń ṣẹ́gun fún wa, kì í ṣe agbára wa. Àmọ́ bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ó láwọn ohun táwa náà gbọ́dọ̀ ṣe. Ẹ̀mí Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní àwọn ìwà táá mú ká ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyọrí. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo àpẹẹrẹ Àpólò.
‘Ó Mọ Ìwé Mímọ́ Dunjú’ (Ìṣe 18:24-28)
3, 4. Kí ni Ákúílà àti Pírísílà kíyè sí pé Àpólò ò mọ̀, báwo ni wọ́n sì ṣe ràn án lọ́wọ́?
3 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń lọ sí Éfésù nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta, Júù kan tó ń jẹ́ Àpólò dé sílùú náà. Ìlú Alẹkisáńdíríà tó lókìkí lórílẹ̀-èdè Íjíbítì ló ti wá. Àpólò láwọn ànímọ́ mélòó kan tó ta yọ. Ọ̀rọ̀ dá lẹ́nu ẹ̀. Yàtọ̀ sí pé ó mọ ọ̀rọ̀ sọ dáadáa, ó “mọ Ìwé Mímọ́ dunjú.” “Iná ẹ̀mí sì ń jó nínú rẹ̀.” Àpólò nítara, èyí jẹ́ kó lè fìgboyà sọ̀rọ̀ níwájú àwọn Júù tó kóra jọ sínú sínágọ́gù.—Ìṣe 18:24, 25.
4 Ákúílà àti Pírísílà gbọ́ ọ̀rọ̀ Àpólò. Ó dájú pé inú wọn dùn láti gbọ́ bó ṣe ń “kọ́ni ní àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Jésù lọ́nà tó péye.” Òótọ́ pọ́ńbélé ni gbogbo ohun tó sọ nípa Jésù. Àmọ́ nígbà tó yá, tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni yìí kíyè sí pé àwọn nǹkan kan wà tí Àpólò ò mọ̀. “Ìrìbọmi Jòhánù nìkan ló mọ̀.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ ni iṣẹ́ àgọ́ pípa tí tọkọtaya yìí ń ṣe, wọn ò torí pé Àpólò kàwé tó sì mọ ọ̀rọ̀ sọ dáadáa kí wọ́n wá máa bẹ̀rù láti ràn án lọ́wọ́. Dípò ìyẹn, “wọ́n mú un wọ àwùjọ wọn, wọ́n sì ṣàlàyé ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tó túbọ̀ péye.” (Ìṣe 18:25, 26) Báwo ni ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣe rí lára Àpólò tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé, tó sì mọ ọ̀rọ̀ sọ dáadáa? Ó dájú pé ó fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ohun tí wọ́n sọ, ìyẹn sì jẹ́ ọ̀kan lára ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ káwa Kristẹni ní.
5, 6. Kí ló mú kí Àpólò túbọ̀ wúlò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kí la sì rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀?
5 Torí pé Àpólò gba ìrànlọ́wọ́ tí Ákúílà àti Pírísílà fún un, ó túbọ̀ wúlò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nígbà tó yá, ó lọ sí Ákáyà, ó sì “ṣèrànwọ́ púpọ̀” fáwọn onígbàgbọ́. Ó tún wàásù fáwọn Júù tó wà lágbègbè yẹn tí wọ́n ń sọ pé Jésù kọ́ ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Lúùkù sọ pé: “Ó ń sọ̀rọ̀ . . . pẹ̀lú ìtara, bó ṣe ń fi ẹ̀rí hàn kedere pé àwọn Júù kò tọ̀nà, tó sì ń fi hàn nínú Ìwé Mímọ́ pé Jésù ni Kristi náà.” (Ìṣe 18:27, 28) Ẹ ò rí i pé ìrànlọ́wọ́ ńlá ni Àpólò jẹ́ fún ìjọ! Kódà, òun náà wà lára àwọn tó mú kí “ọ̀rọ̀ Jèhófà” máa gbilẹ̀. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Àpólò?
6 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwa Kristẹni nírẹ̀lẹ̀. Gbogbo wa la ní oríṣiríṣi nǹkan tá a mọ̀ ọ́n ṣe, ó lè jẹ́ ẹ̀bùn àbínibí, àwọn ìrírí tá a ní, tàbí àwọn ohun tá a ti mọ̀. Àmọ́, ìrẹ̀lẹ̀ wa gbọ́dọ̀ ju àwọn ẹ̀bùn tá a ní lọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ẹ̀bùn tá a ní máa kó sí wa lórí, ìyẹn sì lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. (1 Kọ́r. 4:7; Jém. 4:6) Tá a bá nírẹ̀lẹ̀ lóòótọ́, a máa gbà pé àwọn ẹlòmíì sàn jù wá lọ. (Fílí. 2:3) A ò ní máa bínú táwọn ẹlòmíì bá tọ́ wa sọ́nà, àá sì múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. A ò ní máa rin kinkin mọ́ èrò tiwa tá a bá rí i pé Jèhófà ti fi ẹ̀mí mímọ́ darí ètò ẹ̀ láti ṣàtúnṣe òye tá a ní tẹ́lẹ̀. Tá a bá ṣáà ti ń bá a nìṣó láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, àá máa wúlò fún Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀.—Lúùkù 1:51, 52.
7. Báwo ni Pọ́ọ̀lù àti Àpólò ṣe fi hàn pé àwọn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?
7 Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a ò ní máa bá àwọn míì díje. Sátánì gbìyànjú gan-an láti dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Ó dájú pé ṣe ni Sátánì á máa yọ̀ ṣìnkìn tó bá rí i tí àwọn alábòójútó táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún bí Àpólò àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bára wọn fà á, bóyá tí wọ́n ń jowú ara wọn, tí wọ́n sì ń wá bí wọ́n ṣe máa dẹni táwọn èèyàn ń kan sárá sí nínú ìjọ! Kò sì lè ṣòro fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Torí pé ní Kọ́ríńtì, àwọn Kristẹni kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé, “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,” àwọn míì sì ń sọ pé, “Èmi jẹ́ ti Àpólò.” Ṣé Pọ́ọ̀lù àti Àpólò fara mọ́ èrò tó ń fa ìyapa yìí? Rárá o! Torí pé Pọ́ọ̀lù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó gbà pé Àpólò wúlò gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n jọ ń ṣe, torí náà ó fún un ní ọ̀pọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Àpólò náà ò sì kọ ọ̀rọ̀ sí Pọ́ọ̀lù lẹ́nu. (1 Kọ́r. 1:10-12; 3:6, 9; Títù 3:12, 13) Àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fún wa lónìí. Ó yẹ káwa náà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká sì máa yẹra fún ohunkóhun tó lè dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ.
Ó Ń “Fèròwérò Nípa Ìjọba Ọlọ́run Lọ́nà Tó Ń Yíni Lérò Pa Dà” (Ìṣe 18:23; 19:1-10)
8. Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà pa dà sí Éfésù, kí sì nìdí?
8 Pọ́ọ̀lù ti ṣèlérí pé òun máa pa dà lọ sí Éfésù, ó sì mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. a (Ìṣe 18:20, 21) Àmọ́, kíyè sí ọ̀nà tó gbà pa dà lọ. Áńtíókù ti Síríà la gbúròó ẹ̀ sí gbẹ̀yìn. Kó tó dé Éfésù, ó ṣeé ṣe kó kọ́kọ́ lọ sí Sìlúṣíà tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìn, kó wá tibẹ̀ wọkọ̀ ojú omi tó máa gbé e débi tó ń lọ. Àmọ́, “àwọn agbègbè tó jìnnà sí òkun” ló gbà. Àwọn kan fojú bù ú pé ìrìn àjò tí Ìṣe 18:23 àti 19:1 sọ pé Pọ́ọ̀lù rìn tó nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ (1,600) kìlómítà! Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi yàn láti rìnrìn àjò tó jìn tó sì nira tó bẹ́ẹ̀? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè “fún gbogbo ọmọ ẹ̀yìn lókun.” (Ìṣe 18:23) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kẹta yẹn ò ní rọrùn bí méjì àkọ́kọ́ náà ò ṣe rọrùn. Amọ́, kò kà á sí àṣedànù. Báwọn alábòójútó àyíká àtàwọn ìyàwó wọn náà ṣe máa ń ṣe lónìí nìyẹn. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká mọrírì àwọn ará wa yìí tí wọ́n fi àwọn nǹkan du ara wọn torí àwọn ẹlòmíì!
9. Kí nìdí táwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n ti ṣèrìbọmi tẹ́lẹ̀ fi tún ìrìbọmi ṣe, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́ lára wọn?
9 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé Éfésù, ó rí àwọn ọkùnrin tí wọ́n tó méjìlá tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù Onírìbọmi. Òótọ́ ni pé Jòhánù ti ṣèrìbọmi fún wọn tẹ́lẹ̀, àmọ́ ìrìbọmi tí wọ́n ṣe yẹn kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ mọ́. Bákan náà, ó jọ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn tí wọ́n bá tiẹ̀ mọ̀ nípa ẹ̀ rárá. Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn batisí wọn lórúkọ Jésù. Wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Àpólò, wọ́n sì ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn tí wọ́n ti batisí wọn lórúkọ Jésù, wọ́n rí ẹ̀mí mímọ́ gbà, wọ́n sì tún láǹfààní láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu kan. Èyí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn tí wọ́n bá ṣe tán láti ṣe ohun tí ètò rẹ̀ bá sọ.—Ìṣe 19:1-7.
10. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kúrò ní sínágọ́gù tó sì lọ sí gbọ̀ngàn àpéjọ ilé ẹ̀kọ́, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀ tá a bá ń wàásù?
10 Nǹkan míì tún ṣẹlẹ̀ tó mú kí ìhìn rere tẹ̀ síwájú. Pọ́ọ̀lù fìgboyà wàásù fóṣù mẹ́ta nínú sínágọ́gù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ń “fèròwérò nípa Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tó ń yíni lérò pa dà,” àwọn kan ò gbọ́ wọ́n sì ta kò ó. Dípò tí Pọ́ọ̀lù á fi máa fàkókò ṣòfò lọ́dọ̀ àwọn tó “ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa Ọ̀nà Náà,” ó ṣètò láti bá wọn sọ̀rọ̀ nínú gbọ̀ngàn àpéjọ ilé ẹ̀kọ. (Ìṣe 19:8, 9) Ó wá pọn dandan pé káwọn tó bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run kúrò ní sínágọ́gù kí wọ́n sì lọ sínú gbọ̀ngàn àpéjọ náà. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, tá a bá rí i pé ẹni tá à ń wàásù fún ò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa tàbí pé ó kàn fẹ́ bá wa jiyàn, ṣe ló yẹ ká dá ìjíròrò náà dúró, torí ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ló ṣì wà tó yẹ kí wọ́n gbọ́ ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run.
11, 12. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣiṣẹ́ kára ká sì mú ọ̀rọ̀ wa bá àwọn tá à ń wàásù fún mu? (b) Kí ló fi hàn pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣiṣẹ́ kára, tá a sì ń mu ọ̀rọ̀ wa bá àwọn tá à ń wàásù fún mu?
11 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni Pọ́ọ̀lù máa ń kọ́ni nínú gbọ̀ngàn àpéjọ ilé ẹ̀kọ́ yẹn láti nǹkan bí aago mọ́kànlá àárọ̀ títí di aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́. (Ìṣe 19:9) Ó sì lè jẹ́ pé ìgbà tó parọ́rọ́ tó sì móoru jù lọ nìyẹn, táwọn èèyàn máa ń ṣíwọ́ iṣẹ́ láti jẹun kí wọ́n sì sinmi. Tó bá jẹ́ pé bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń fìtara wàásù fún odindi ọdún méjì nìyẹn, a jẹ́ pé á ti lò ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) wákàtí láti fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. b Ìdí míì nìyẹn tí ọ̀rọ̀ Jèhófà fi ń gbilẹ̀ nìṣó. Òṣìṣẹ́ kára ni Pọ́ọ̀lù, ó sì mọ bó ṣe lè mú ara ẹ̀ bá ipò àwọn tó ń wàásù fún mu. Ó ṣe tán láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kó lè rí àwọn èèyàn tó pọ̀ sí i bá sọ̀rọ̀. Kí wá lèyí yọrí sí? “Gbogbo àwọn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Éṣíà. . . gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, àti Júù àti Gíríìkì.” (Ìṣe 19:10) Ẹ ò rí i pé Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí kúnnákúnná lóòótọ́!
12 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní náà ń ṣiṣẹ́ kára, a sì mọ bá a ṣe lè mú ọ̀rọ̀ wa bá àwọn èèyàn tá à ń wàásù fún mu. À ń sapá láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn níbikíbi tá a bá ti lè rí wọn àti lásìkò tá a lè bá wọn. A máa ń wàásù ní òpópónà, láwọn ibi ìtajà àti láwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí. A lè fi fóònù wàásù fáwọn èèyàn tàbí ká kọ lẹ́tà. Tó bá sì kan pé ká wàásù láti ilé dé ilé, a máa ń gbìyànjú láti lọ nígbà tó ṣeé ṣe ká bá ọ̀pọ̀ èèyàn nílé.
Ìṣe 19:11-22)
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “Ń Gbilẹ̀ Nìṣó, Ó sì Ń Borí” Báwọn Ẹ̀mí Èṣù Tiẹ̀ Ń Ṣàtakò (13, 14. (a) Kí ni Jèhófà fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti ṣe? (b) Àṣìṣe wo làwọn ọmọkùnrin Síkéfà ṣe, irú èrò wo sì lọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ní lónìí?
13 Lúùkù jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà kan wà tí Jèhófà fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti ṣe “àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀.” Kódà, wọ́n mú aṣọ àti épírọ́ọ̀nù rẹ̀ lọ bá àwọn tó ń ṣàìsàn, ara wọn sì yá. Wọ́n tún lò ó láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. c (Ìṣe 19:11, 12) Inú ọ̀pọ̀ èèyàn dùn nígbà tí wọ́n rí i bí ẹ̀mí èṣù ṣe ń jáde lára àwọn èèyàn, síbẹ̀ inú àwọn kan ò dùn.
14 Àwọn kan lára “àwọn Júù tó ń rìnrìn àjò kiri, tí wọ́n ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde” gbìyànjú láti ṣe irú iṣẹ́ ìyanu tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe. Àwọn kan nínú wọn gbìyànjú láti lo orúkọ Jésù àti ti Pọ́ọ̀lù láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Bí àpẹẹrẹ, Lúùkù sọ pé àwọn ọmọkùnrin méje kan wà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Síkéfà, ọ̀kan lára àwọn olórí àlùfáà Júù. Nígbà tí wọ́n fẹ́ lé ẹ̀mí èṣù jáde, ẹ̀mí èṣù náà sọ fún wọn pé: “Mo mọ Jésù, mo sì mọ Pọ́ọ̀lù; àmọ́ ta lẹ̀yin?” Ni ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù wà lára ẹ̀ bá bẹ́ mọ́ àwọn afàwọ̀rajà yẹn bí ẹranko ẹhànnà, débi pé wọ́n sá lọ kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀ ní ìhòòhò pẹ̀lú ọgbẹ́ lára. (Ìṣe 19:13-16) Bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ṣẹ́gun àwọn afàwọ̀rajà yìí jẹ́ ká rí agbára “ọ̀rọ̀ Jèhófà,” èyí tó fún Pọ́ọ̀lù láti ṣe iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ táwọn ẹlẹ́sìn èké ò lè ṣe. Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé táwọn bá ṣáà ti ń pe orúkọ Jésù tàbí táwọn bá ń pe ara àwọn ní “Kristẹni,” àbùṣe ti bùṣe. Àmọ́, bí Jésù ṣe sọ, àwọn tó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ nìkan ló nírètì ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú.—Mát. 7:21-23.
15. Tó bá dọ̀rọ̀ ìbẹ́mìílò àtàwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ará Éfésù?
15 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọkùnrin Síkéfà jẹ́ káwọn èèyàn bẹ̀rù Ọlọ́run, èyí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn di onígbàgbọ́, wọn ò sì lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò mọ́. Àwọn ará ìlú Éfésù máa ń pidán gan-an, ó ti wà nínú àṣà wọn. Wọ́n sábà máa ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, wọ́n máa ń lo ońdè, kódà wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìwé tí wọ́n kọ ọfọ̀ sí. Àmọ́ ní báyìí tí ọ̀pọ̀ àwọn ará Éfésù ti di onígbàgbọ́, wọ́n kó àwọn ìwé tí wọ́n fi ń pidán jáde wọ́n sì dáná sun ún ní gbangba, tá a bá sì ní ká ṣírò iye owó táwọn ìwé náà máa jẹ́ lóde òní, ó máa tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là. d Lúùkù sọ pé: “Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ Jèhófà ń gbilẹ̀ nìṣó, ó sì ń borí lọ́nà tó lágbára.” (Ìṣe 19:17-20) Àbí ẹ ò rí i bí Jèhófà ṣe ṣẹ́gun ìjọsìn èké àtàwọn ẹ̀mí èṣù! Àpẹẹrẹ tó dáa làwọn olóòótọ́ èèyàn yẹn jẹ́ fún wa lónìí. Àwa náà ń gbé nínú ayé tí ìbẹ́mìílò ti wọ́pọ̀ gan-an. Torí náà, tá a bá ní ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò, á dáa ká ṣe bíi tàwọn ará Éfésù, ká tètè kó wọn dà nù! Ohun yòówù kó ná wa, ẹ jẹ́ ká jìnnà pátápátá sí ìbẹ́mìílò torí ohun ìríra ni.
“Àwọn Èèyàn Dá Rògbòdìyàn Púpọ̀ Sílẹ̀” (Ìṣe 19:23-41)
16, 17. (a) Ṣàlàyé bí Dímẹ́tíríù ṣe dá wàhálà sílẹ̀ ní Éfésù. (b) Báwo làwọn ará Éfésù ṣe fi hàn pé agbawèrèmẹ́sìn làwọn?
16 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Sátánì tí Lúùkù mẹ́nu kàn nígbà tó sọ pé “àwọn èèyàn dá rògbòdìyàn púpọ̀ sílẹ̀ nípa Ọ̀nà Náà.” Lúùkù ò sọ àsọdùn rárá. e (Ìṣe 19:23) Ọkùnrin alágbẹ̀dẹ fàdákà kan tó ń jẹ́ Dímẹ́tíríù ló dá wàhálà náà sílẹ̀. Òun ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ náà létí àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà bíi tiẹ̀, ó rán wọn létí pé ère tí wọ́n ń tà ló sọ wọ́n di ọlọ́rọ̀. Ó sọ pé ìwàásù tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe ń kó bá ọrọ̀ ajé àwọn, torí pé àwọn Kristẹni kì í bọ̀rìṣà. Ó wá sọ fún wọn pé bí ọmọ orílẹ̀-èdè rere, kò yẹ káwọn lajú àwọn sílẹ̀ kí tàlùbọ̀ kó wọ̀ ọ́, kí Pọ́ọ̀lù wá sọ abo òrìṣà Átẹ́mísì àti tẹ́ńpìlì wọn tó lókìkí di ohun táwọn èèyàn ò ‘kà sí’ mọ́.—Ìṣe 19:24-27.
17 Ohun tí Dímẹ́tíríù fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ náà ló pa dà ṣẹlẹ̀. Inú bí àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé “Títóbi ni Átẹ́mísì àwọn ará Éfésù!” Làwọn jàǹdùkú bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìlú náà bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí. f Pọ́ọ̀lù ò kọ ikú nítorí ìhìn rere, torí náà, ó fẹ́ wọ inú gbọ̀ngàn ìwòran ńlá kó lè bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ò jẹ́ kó lọ torí ó léwu. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Alẹkisáńdà dìde dúró láàárín àwọn èèyàn náà ó sì gbìyànjú láti sọ̀rọ̀. Torí pé Júù lòun náà, ó ṣeé ṣe kó wù ú láti ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn Júù àtàwọn Kristẹni yìí. Àmọ́, àlàyé ẹ̀ ò lè já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn èèyàn yẹn. Gbàrà tí wọ́n ti rí i pé Júù lòun náà, wọ́n ké mọ́ ọn pé kó jókòó ara ẹ̀, wọ́n sì ń pariwo fún nǹkan bíi wákàtí méjì, wọ́n ń sọ pé “Títóbi ni Átẹ́mísì àwọn ará Éfésù!” Títí dòní, àwọn èèyàn kan ṣì wà tó jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn bíi tìgbà yẹn, tí wọ́n ń hùwà bí ẹni tí kò nírònú.—Ìṣe 19:28-34.
18, 19. (a) Báwo ni akọ̀wé ìlú tó wà ní Éfésù ṣe pa àwọn èèyàn náà lẹ́nu mọ́? (b) Báwo làwọn aláṣẹ ṣe máa ń dáàbò bo àwa èèyàn Jèhófà nígbà míì, kí ló sì yẹ ká ṣe?
18 Nígbà tó yá, akọ̀wé ìlú yẹn pa àwọn jàǹdùkú náà lẹ́nu mọ́. Ẹnì kan tórí ẹ̀ pé ni akọ̀wé ìlú yìí, ó fi àwọn èèyàn tínú ń bí náà lọ́kàn balẹ̀ pé kò sóhun táwọn Kristẹni lè fi tẹ́ńpìlì àti abo òrìṣà wọn ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ fún wọn pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń wàásù ò hùwà ọ̀daràn kankan lòdì sí tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì, àti pé tí wọn ò bá fara mọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ń ṣe, ṣe ló yẹ kí wọ́n fẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èyí tó wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn jù lọ ni bó ṣe rán wọn létí pé bí wọ́n ṣe kóra jọ, tí wọ́n sì ń dàlú rú kò bófin ìlú Róòmù mu. Lẹ́yìn náà, ó ní káwọn èèyàn náà máa lọ. Láìka bínú ṣe ń bí wọn sí, ṣe lara wọn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí akọ̀wé ìlú náà sọ.—Ìṣe 19:35-41.
19 Èyí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ táwọn èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ àti aláròjinlẹ̀ tó wà nípò àṣẹ máa gbèjà àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, kò sì ní jẹ́ ìgbà ìkẹyìn. Kódà, àpọ́sítélì Jòhánù ti rí i tẹ́lẹ̀ nínú ìran kan pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, “ilẹ̀” tó ṣàpẹẹrẹ àwọn aláṣẹ ayé yìí máa gbé odò náà mì, ìyẹn inúnibíni tí Sátánì ń ṣe sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. (Ìfi. 12:15, 16) Ohun tó sì máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn adájọ́ tó lọ́kàn rere máa ń ràn wá lọ́wọ́ wọ́n sì máa ń dáàbò bo ẹ̀tọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti máa jọ́sìn Jèhófà, ká sì tún máa wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. Àmọ́ ṣá o, tá a bá máa ṣàṣeyọrí, ìwà tá à ń hù ṣe pàtàkì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé Pọ́ọ̀lù níwà tó dáa làwọn aláṣẹ tó wà nílùú Éfésù fi bọ̀wọ̀ fún un, tó sì ń wù wọ́n pé kí wọ́n gbà á sílẹ̀. (Ìṣe 19:31) Torí náà, tá a bá jẹ́ olóòótọ́ tá a sì níwà tó dáa, ìyẹn á jẹ́ káwọn èèyàn tá à ń bá pàdé ní èrò tó dáa nípa wa.
20. (a) Báwo ni ọ̀nà tí ọ̀rọ̀ Jèhófà gbà gbilẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti lónìí ṣe rí lára ẹ? (b) Kí lo pinnu pé wàá ṣe bó o ṣe ń rí i tí Jèhófà ń lò wá láti ṣàṣeyọrí tá a sì ń ṣẹ́gun Sátánì àti ètò burúkú rẹ̀?
20 Inú wa dùn láti rí i pé “ọ̀rọ̀ Jèhófà ń gbilẹ̀ nìṣó, ó sì ń borí” ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Bákan náà lónìí, à ń láyọ̀ bá a ṣe ń rí i tí Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣàṣeyọrí. Ó dájú pé ìwọ náà á fẹ́ kópa díẹ̀, bó ti wù kó kéré mọ, nínú irú ìjagunmólú bẹ́ẹ̀? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tá a ti sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú orí yìí. Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tètè máa ṣe ohun tí ètò Jèhófà bá sọ, máa ṣiṣẹ́ kára, kọ ìbẹ́mìílò sílẹ̀ pátápátá, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí ìwà àti ìṣe rẹ lè máa jẹ́rìí fáwọn èèyàn.
a Wo àpótí náà, “ Éfésù—Olú Ìlú Éṣíà.”
b Pọ́ọ̀lù tún kọ ìwé 1 Kọ́ríńtì nígbà tó wà ní Éfésù.
c Aṣọ náà lè jẹ́ aṣọ tí Pọ́ọ̀lù máa ń so mọ́ orí kí òógùn má bàa ṣàn wọnú ojú ẹ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe wọ épírọ́ọ̀nù lákòókò yìí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó máa ṣe iṣẹ́ àgọ́ pípa lọ́wọ́ àárọ̀, nígbà tọ́wọ́ ẹ̀ bá dilẹ̀, kó lè rí owó táá fi gbọ́ bùkátà ara ẹ̀.—Ìṣe 20:34, 35.
d Lúùkù sọ pé gbogbo rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000) ẹyọ owó fàdákà. Tó bá jẹ́ owó dínárì ló ní lọ́kàn, ó máa gba òṣìṣẹ́ kan láyé ìgbà yẹn ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000) ọjọ́, tàbí nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlógóje (137), kó tó lè rí owó yẹn kó jọ, ìyẹn tó bá ń fi gbogbo ọjọ́ méje tó wà lọ́sẹ̀ ṣiṣẹ́.
e Àwọn kan sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí nígbà tó sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì pé “a ò . . . mọ̀ pé ẹ̀mí wa ò ní bọ́.” (2 Kọ́r. 1:8) Àmọ́, ó lè jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó burú jùyẹn lọ ló ní lọ́kàn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé òun “bá àwọn ẹranko jà ní Éfésù,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tó kojú àwọn ẹranko ẹhànnà ní gbọ̀ngàn ìwòran ló ń sọ tàbí báwọn èèyàn ṣe ṣenúnibíni sí i. (1 Kọ́r. 15:32) Àlàyé méjèèjì yìí ló bá ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ mu.
f Ẹgbẹ́ àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ bí irú èyí máa ń lágbára gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ìyẹn, ẹgbẹ́ oníbúrẹ́dì dá irú wàhálà bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ nílùú Éfésù.