Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
Ẹ̀yin Akéde Ìjọba Ọlọ́run Ọ̀wọ́n:
Jẹ́ ká sọ pé o wà lára àwọn àpọ́sítélì tó dúró lórí Òkè Ólífì, tí Jésù sì dúró síwájú yín. Bó ṣe kù díẹ̀ kó lọ sọ́run, ó wá sọ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe máa rí lára ẹ?
Ó ṣeé ṣe kó o ronú nípa bí iṣẹ́ tí Jésù gbé fún yín ṣe máa gbòòrò tó, kíyẹn sì máa bà ẹ́ lẹ́rù. O lè máa rò ó pé, ‘Báwo làwa ọmọ ẹ̀yìn tá ò tó nǹkan yìí ṣe máa wàásù “dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé”?’ Ó ṣeé ṣe kó o rántí ìkìlọ̀ Jésù ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, pé: “Ẹrú ò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Tí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n máa ṣe inúnibíni sí ẹ̀yin náà; tí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n máa pa ọ̀rọ̀ yín náà mọ́. Àmọ́ wọ́n máa ṣe gbogbo nǹkan yìí sí yín nítorí orúkọ mi, torí pé wọn ò mọ ẹni tó rán mi.” (Jòh. 15:20, 21) Bó o ṣe ń ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ yẹn, o lè máa bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè jẹ́rìí kúnnákúnná lójú àtakò àti inúnibíni?’
Ìbéèrè yìí kan àwa náà lónìí. Iṣẹ́ pàtàkì tí Jésù gbé fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé ká jẹ́rìí kúnnákúnná fún “àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè” títí dé “ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Mát. 28:19, 20) Báwo la ṣe lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyọrí, ní pàtàkì táwọn èèyàn bá ń ta kò wá?
A rí àkọ́sílẹ̀ tó ń mórí ẹni wú nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. Ńṣe la dìídì ṣe ìwé tó ò ń kà yìí kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ṣe ń ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ náà. Á jẹ́ kó dà bíi pé o wà níbẹ̀ nígbà táwọn nǹkan náà ṣẹlẹ̀, èyí á sì mú kó túbọ̀ wọ̀ ẹ́ lọ́kàn. Ó máa yà ẹ́ lẹ́nu láti rí i pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà lọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti tóde òní gbà jọra. Wàá rí i pé iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ṣe nígbà yẹn làwa náà ń ṣe lóde òní, wàá tún rí i pé ọ̀nà kan náà ni Jèhófà ń gbà ṣètò iṣẹ́ yìí. Bó o sì ṣe ń ronú lórí àwọn ọ̀nà tọ́rọ̀ wa gbà jọra yìí, bẹ́ẹ̀ láá túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà ṣì ń bá a lọ láti máa darí apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀.
Bó o ṣe ń ṣàyẹ̀wò ìwé Ìṣe, àdúrà wa ni pé kí Jèhófà mú kí ìgbàgbọ́ tó o ní pé òun máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ túbọ̀ lágbára, kí agbára ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sì máa gbé ẹ ró. Bó o ṣe ń fi ohun tó o kọ́ nínú ìwé yìí sílò, ó máa wù ẹ́ pé kó o túbọ̀ máa “jẹ́rìí kúnnákúnná” nípa Ìjọba Ọlọ́run, wàá sì máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá mọ Jèhófà, kí wọ́n sì nírètí pé àwọn máa wà láàyè títí láé.—Ìṣe 28:23; 1 Tím. 4:16.
Àwa arákùnrin yín,
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà