APÁ 2
Àníyàn Ìgbésí Ayé—“A Há Wa Gádígádí ní Gbogbo Ọ̀nà”
“Ó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tí mo fi wà nílé ọkọ, àmọ́ ọ̀sán kan òru kan lọkọ mi yarí pé òun ò ṣe mọ. Làwọn ọmọ wa bá fi ètò Jèhófà sílẹ̀. Ẹnu ìyẹn ni mo wà tí oríṣiríṣi àìsàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mi. Ayé wá sú mi gbáà, ó sì dà bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ kankan fún mi. Nígbà tó yá, mi ò lọ sípàdé mọ́, bí mo ṣe dẹni tó fà sẹ́yìn nìyẹn.”—June.
KÒ SẸ́NI tó bọ́ lọ́wọ́ àníyàn tàbí ìṣòro nínú ayé yìí, títí kan àwa èèyàn Ọlọ́run pàápàá. Onísáàmù kan tiẹ̀ sọ pé àníyàn bo òun mọ́lẹ̀. (Sáàmù 94:19) Jésù gan-an sọ pé ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn féèyàn láti jọ́sìn Jèhófà béèyàn ṣe fẹ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn nítorí “àwọn àníyàn ìgbésí ayé.” (Lúùkù 21:34) Ṣé bó ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn? Ṣé àtijẹ àtimu lò ń kó ìdààmú bá ẹ, àbí bó o ṣe fẹ́ bójú tó ìdílé rẹ ló ń kó àníyàn bá ẹ àbí ọ̀rọ̀ àìlera rẹ ló tojú sú ẹ? Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Jèhófà ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́? Lọ́nà wo?
“Agbára tí Ó Ré Kọjá Ìwọ̀n Ti Ẹ̀dá”
A ò lè dá yanjú àníyàn tàbí ìṣòro wa fúnra wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà jẹ́rìí sí i nígbà tó sọ pé: “A há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà. . . . Ọkàn wa dàrú . . . ; a gbé wa ṣánlẹ̀.” Síbẹ̀ ó tún sọ pé a kò “há wa ré kọjá yíyíra,” “kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbájáde rárá,” àti pé “a kò pa wá run.” Kí ló mú ká lè máa fara da àwọn ìṣòro yìí? “Agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” ni, ìyẹn agbára tí Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ń fún wa.—2 Kọ́ríńtì 4:7-9.
Ronú ná nípa bí Jèhófà ṣe fi “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” ran ìwọ náà lọ́wọ́. Ǹjẹ́ o rántí bí àsọyé tó o gbọ́ nígbà kan ṣe gbé ọ ró tó sì mú kó o túbọ̀ mọrírì ìfẹ́ Jèhófà? Ó ṣeé ṣe kó o kíyè sí i pé ìgbàgbọ́ rẹ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run túbọ̀ ń lágbára bó o ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Párádísè. Ó ṣe kedere pé bá a ṣe ń lọ sáwọn ìpàdé wa, tá a sì ń sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn èèyàn, à ń rí okùn tó ń mú ká lè máa fara da àwọn ìṣòro ìgbésí ayé, a sì ń ní ìbàlẹ̀ ọkàn bá a ṣe ń fayọ̀ sin Jèhófà.
“Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí Pé Jèhófà Jẹ́ Ẹni Rere”
Nígbà míì, ó lè ṣe ẹ́ bíi pé àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe ti pọ̀ jù. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ni ká kọ́kọ́ máa wá ìjọba òun ká sì tún máa ṣe déédéé nínú ìjọsìn wa. (Mátíù 6:33; Lúùkù 13:24) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó lè jẹ́ pé inúnibíni, ọ̀rọ̀ ìdílé tàbí àìlera kò jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́. Ó sì lè jẹ́ pé iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ń tán ẹ lókun, ó sì ń gbà gbogbo àkókò tó yẹ kó o lò pẹ̀lú àwọn ará ní ìpàdé ìjọ. Bó o bá wá rí i pé o ò fi bẹ́ẹ̀ ní àyè àti okun tó o lè fi ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nǹkan lè tojú sú ẹ. Ó tiẹ̀ lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ohun tágbára rẹ ò gbé ni Jèhófà ń fẹ́ kó o ṣe.
Fọkàn balẹ̀, gbogbo rẹ̀ ló yé Jèhófà. Ó mọ ibi tágbára wa mọ, torí bẹ́ẹ̀ kì í béèrè ju ohun tágbára wa gbé lọ. Ó sì mọ̀ pé tí ara bá wóni tàbí téèyàn ní ìdààmú ọkàn, ó máa ń ṣe díẹ̀ kéèyàn tó pa dà bọ̀ sípò.—Sáàmù 103:13, 14.
Àpẹẹrẹ kan ni bí Jèhófà ṣe gba ti wòlíì Èlíjà rò. Nígbà tí ìdààmú bá Èlíjà tí ẹ̀rù sì bà á, ó sá lọ sínú aginjù. Ǹjẹ́ Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ burúkú sí wòlíì náà kó tún wá pàṣẹ fún un pé kó pa dà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà rán áńgẹ́lì pé kó rọra jí Èlíjà lójú oorun kó sì fún un lóúnjẹ. Síbẹ̀, ogójì [40] ọjọ́ lẹ́yìn náà, 1 Àwọn Ọba 19:1-19) Kí lèyí kọ́ wa? Nígbà tí àníyàn bo Èlíjà mọ́lẹ̀, Jèhófà mú sùúrù fún un, ó sì gba tiẹ̀ rò. Jèhófà ò yí pa dà. Ó ń bójú tó wa ó sì ń gba tiwa rò gẹ́lẹ́ bó ti ṣe fún Èlíjà.
ẹ̀rù ṣì ń ba Èlíjà, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀. Kí ni Jèhófà tún wá ṣe láti ràn án lọ́wọ́? Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà fi agbára rẹ̀ han Èlíjà kó lè mọ̀ pé Òun lágbára láti dáàbò bò ó. Lẹ́yìn náà, Jèhófà tù ú nínú ó sì bá a sọ̀rọ̀ lóhùn pẹ̀lẹ́. Níkẹyìn, Jèhófà jẹ́ kó mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn bíi tiẹ̀ ṣì wà tí wọ́n ń fòótọ́ jọ́sìn òun. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí Èlíjà fi pa dà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ tó sì ń fìtara kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Tó o bá ń ronú nípa ohun tó o máa ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, máa fi sọ́kàn pé ó níbi tágbára rẹ mọ. Má rò pé bó o ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ náà ni wàá lè ṣe nísinsìnyí. Ọ̀rọ̀ náà dà bíi ti sárésáré kan tó fi eré sísá sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọdún. Kì í ṣe ọjọ́ tó bá pa dà sídìí eré sísá lá bẹ̀rẹ̀ sí í sáré bíi ti tẹ́lẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀ títí tó máa fi lágbára àtisáré bíi ti tẹ́lẹ̀. Àwa Kristẹni náà ò yàtọ̀ sáwọn sárésáré. Àwa náà ní ohun tá à ń lé. (1 Kọ́ríńtì 9:24-27) Ohun tó máa dáa kíwọ náà kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o ní ohun kan tí wàá máa lépa tọ́wọ́ rẹ á tètè tẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè ní in lọ́kàn pé wàá máa lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìpàdé ìjọ. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó o ní lọ́kàn. Bí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà ti ń lágbára sí i, wàá rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé ‘tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.’ (Sáàmù 34:8) Mọ̀ dájú pé Jèhófà mọyì ohunkóhun tó o bá ṣe láti fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, bó ti wù kó kéré mọ.—Lúùkù 21:1-4.
‘Mo Rí Ìrànlọ́wọ́ Tí Mò Ń Wá Látọjọ́ Yìí’
Báwo ni Jèhófà ṣe ran June lọ́wọ́ kó lè pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀? Obìnrin náà sọ pé: “Mi ò dákẹ́ àdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ìyàwó ọmọ mi sọ fún mi nípa àpéjọ kan tí wọ́n fẹ́ ṣe nílùú wa. Mo da ọ̀rọ̀ náà rò mo sì pinnu láti bá wọn ṣe ọjọ́ kan. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó pé mo pa dà sáàárín àwọn èèyàn Jèhófà! Àpéjọ yẹn ni mo ti rí ìrànlọ́wọ́ tí mò ń wá látọjọ́ yìí. Mo ti wá ń fayọ̀ sin Jèhófà báyìí, ọkàn mi sì balẹ̀ gan-an. Ó wá yé mi pé mo nílò àwọn ará mi lọ́kùnrin àti lóbìnrin torí pé igi kan ò lè dá igbó ṣe. Mo mà dúpẹ́ o pé mo pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.”