Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
Ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n:
Bí ìwọ náà ṣe mọ̀, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ọ̀pọ̀ nínú wọn jẹ́ olóòótọ́, síbẹ̀ wọ́n ní irú àwọn ìṣòro tí àwa náà ní. Ká má sì gbàgbé pé ẹlẹ́ran ara bíi tiwa làwọn náà. (Jákọ́bù 5:17) Ìṣòro àti ìdààmú kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn kan lára wọn. Ìbànújẹ́ bá àwọn míì nítorí ohun tí mọ̀lẹ́bí tàbí onígbàgbọ́ ẹlẹ́gbẹ́ wọn ṣe sí wọn. A sì tún rí àwọn kàn tí ọkàn wọn gbọgbẹ́ nítorí àṣìṣe tiwọn fúnra wọn.
Ǹjẹ́ a lè sọ pé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti fi Jèhófà sílẹ̀ pátápátá? Rárá o. Ọ̀rọ̀ wọn dà bíi ti onísáàmù kan tó gbàdúrà pé: “Mo ti rìn gbéregbère bí àgùntàn tí ó sọnù. Wá ìránṣẹ́ rẹ, nítorí pé èmi kò gbàgbé àwọn àṣẹ rẹ.” (Sáàmù 119:176) Ṣé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn?
Mọ̀ dájú pé Jèhófà ò gbàgbé àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tó kúrò láàárín agbo. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń lo àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láti mú kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni bí Jèhófà ṣe ran Jóòbù ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí ìṣòro rọ́ lù ú. Ṣàdédé ló pàdánù àwọn ohun tó ní, àwọn ọmọ rẹ̀ kú mọ́ ọn lójú, àìsàn burúkú sì tún dá a gúnlẹ̀. Àwọn tó yẹ kó tù ú nínú tún sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i. Àwọn nǹkan yìí mú kó ṣi inú rò, síbẹ̀ kò fi Jèhófà sílẹ̀. (Jóòbù 1:22; 2:10) Báwo ni Jèhófà ṣe wá ran Jóòbù lọ́wọ́ tó fi pe orí rẹ̀ wálé?
Jèhófà ran Jóòbù lọ́wọ́ nípasẹ̀ Élíhù tóun náà jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. Nígbà tí Jóòbù ń sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀, Élíhù fara balẹ̀ tẹ́tí sí i kó tó gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í nu Jóòbù lọ́rọ̀ tàbí dá a lẹ́bi tàbí dójú tì í? Ǹjẹ́ Élíhù sọ̀rọ̀ bí ẹni pé òun sàn ju Jóòbù lọ? Kò ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Kí wá ni Élíhù sọ? Ẹ̀mí Ọlọ́run mú kó sọ pé: “Bákan náà ni èmi pẹlu rẹ rí lójú Ọlọrun, amọ̀ ni a fi mọ èmi náà.” Ó wá fi Jóòbù lọ́kàn balẹ̀ pé: ‘Má jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní le koko mọ́ ọ.’ (Jóòbù 33:6, 7, Bíbélì Mímọ́) Élíhù ò dá kún ìnira Jóòbù, ńṣe ló fìfẹ́ gbà á nímọ̀ràn tó sì tún fún un níṣìírí. Ohun tí Jóòbù sì nílò gan-an nìyẹn.
A fẹ́ kó o mọ̀ pé irú ìfẹ́ táwa náà ní sí ẹ nìyẹn, ìyẹn ló mú wa ṣe ìwé yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, a tẹ́tí sí àwọn mélòó kan tó fi ètò Jèhófà sílẹ̀, a fara balẹ̀ kíyè sí ohun tó fà á tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀, a sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. (Òwe 18:13) Lẹ́yìn náà, a wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, a gbàdúrà, a sì ka ìtàn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ayé àtijọ́ tó ní irú ìṣòro tó o ní àti bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́. A wá kó àwọn ìtàn yìí jọ, a sì fi àwọn ìrírí òde òní kún un. A fìfẹ́ rọ̀ ẹ́ pé kó o fara balẹ̀ ka ìwé yìí. A fẹ́ kó o mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ gidigidi.
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà