Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìparí

Ìparí

Ǹjẹ́ o máa ń rántí àwọn àkókò alárinrin tó o ní pẹ̀lú àwọn èèyàn Jèhófà? Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kó o rántí àwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn àpéjọ tó gbé ẹ ró, ìrírí alárinrin tó o ní lóde ẹ̀rí tàbí ọ̀rọ̀ tíwọ àti Kristẹni kan jọ sọ tó múnú rẹ dùn. Àwọn nǹkan tó ò ń rántí yẹn fi hàn pé o ò gbàgbé Jèhófà, òun náà ò sì gbàgbé rẹ. Ó máa ń rántí bó o ṣe fòótọ́ inú jọ́sìn òun, inú rẹ̀ sì máa ń dùn. Ó fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀.

Gbọ́ ohun tí Jèhófà sọ, ó ní ‘Èmi yóò wá àwọn àgùntàn mi, èmi yóò sì bójú tó wọn.’ Jèhófà fi ara rẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn tó máa ń wá àwọn àgùntàn rẹ̀ tó fọ́n ká ní àwárí tó sì máa ń bọ́ wọn. Ó wá sọ pé “èmi yóò bójú tó àwọn àgùntàn mi; ṣe ni èmi yóò dá wọn nídè kúrò ní gbogbo ibi tí a tú wọn ká sí.”—Ìsíkíẹ́lì 34:11, 12.