ORÍ 8
Àwọn Kan Wà Nípò Tó Ga Ju Tiwa Lọ
ÓDÁ mi lójú pé wàá gbà pé àwọn kan wà tí ipò wọn ga, tàbí pé wọ́n tóbi lọ́lá tí wọ́n sì lágbára ju ìwọ àti èmi lọ. Ta ni wàá sọ pé ó wà nípò yẹn?— Jèhófà Ọlọ́run ni. Ọmọ rẹ̀ Olùkọ́ Ńlá ńkọ́? Ǹjẹ́ ó wà ní ipò tó ga ju tiwa lọ?— Bẹ́ẹ̀ ni o.
Jésù ti kọ́kọ́ ń gbé ní ọ̀run pẹ̀lú Ọlọ́run tẹ́lẹ̀. Ní ìgbà náà, áńgẹ́lì tàbí ẹ̀dá ẹ̀mí tí a kò lè fojú rí, tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run ni. Ǹjẹ́ Ọlọ́run tún dá àwọn áńgẹ́lì, tàbí àwọn ọmọ mìíràn tí a kò lè fojú rí láti wà pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run? Bẹ́ẹ̀ ni, ó dá àwọn tó pọ̀ rẹpẹtẹ gan-an. Àwọn áńgẹ́lì yìí pẹ̀lú wà nípò tó ga wọ́n sì lágbára jù wá lọ.—Sáàmù 104:4; Dáníẹ́lì 7:10.
Ǹjẹ́ o rántí orúkọ áńgẹ́lì tó bá Màríà sọ̀rọ̀?— Gébúrẹ́lì ni. Ó sọ fún Màríà pé Ọmọ Ọlọ́run ni ọmọ tó máa bí. Ọlọ́run fi ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí ní ọ̀run tẹ́lẹ̀ sínú Màríà kí ó lè bí Jésù gẹ́gẹ́ bí ọmọ sí ayé.—Lúùkù 1:26, 27.
Ǹjẹ́ o rò pé iṣẹ́ ìyanu yẹn ṣẹlẹ̀ lóòótọ́? Ǹjẹ́ o gbà pé lóòótọ́ ni Jésù ti ń gbé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ní ọ̀run tẹ́lẹ̀ kó tó wá sí ayé?— Jésù sọ pé òun ti gbé ibẹ̀ rí. Báwo ni Jésù ṣe mọ̀ nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀? Ṣé o rí i, nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé, ó ṣeé ṣe kí Màríà ti sọ ohun tí Gébúrẹ́lì wí fún un. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí Jósẹ́fù ti sọ fún Jésù pé Ọlọ́run ni Bàbá rẹ̀ gangan.
Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, Ọlọ́run pàápàá sọ̀rọ̀ Mátíù 3:17) Ní òru ọjọ́ tó ku ọ̀la kí Jésù kú, Jésù gbàdúrà pé: “Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.” (Jòhánù 17:5) Ṣé o rí i báyìí, Jésù sọ pé kí Ọlọ́run mú òun padà sí ọ̀run kí òun máa bá a gbé bíi ti tẹ́lẹ̀. Báwo ló ṣe máa lè gbé níbẹ̀?— Àyàfi kí Jèhófà Ọlọ́run tún padà sọ ọ́ di ẹni ẹ̀mí tí a kò lè fojú rí, tàbí áńgẹ́lì kan.
láti ọ̀run pé: “Èyí ni Ọmọ mi.” (Jẹ́ kí n wá bi ọ́ ní ìbéèrè pàtàkì kan. Ṣé gbogbo áńgẹ́lì ló jẹ́ áńgẹ́lì rere? Kí lèrò rẹ?— Lóòótọ́, nígbà kan rí gbogbo áńgẹ́lì ló ń ṣe rere. Ìdí ni pé Jèhófà ló dá wọn, gbogbo ohun tó sì dá ló dára. Ṣùgbọ́n, ọ̀kan nínú àwọn áńgẹ́lì yìí wá di ẹni burúkú. Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?
Kí á tó lè mọ bí ó ṣe ṣẹlẹ̀, a óò ní láti ronú padà sí ìgbà tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àkọ́kọ́ àti obìnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà. Àwọn èèyàn kan sọ pé ìtàn nípa Ádámù àti Éfà jẹ́ ìtàn àlọ́, tí kò ṣẹlẹ̀ rárá. Ṣùgbọ́n Olùkọ́ Ńlá náà mọ̀ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ni.
Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, ó fi wọ́n sínú ọgbà ẹlẹ́wà kan tó wà ní ibì kan tó ń jẹ́ Édẹ́nì. Ọgbà ìtura ni, ìyẹn Párádísè. Wọn ì bá bí àwọn ọmọ tó pọ̀ níbẹ̀, kí wọ́n di agbo ilé ńlá gan-an, kí wọ́n sì máa gbé inú Párádísè títí láé. Àmọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan wà tó yẹ kí wọ́n kọ́. Ẹ̀kọ́ tá a ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni. Jẹ́ ká wò ó bóyá a rántí rẹ̀.
Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ẹ̀kọ́ wo ló wá yẹ kí Ádámù àti Éfà kọ́?—
Jèhófà sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n máa jẹ nínú gbogbo èso igi tó bá wù wọ́n nínú ọ̀gbà náà. Ṣùgbọ́n igi kan ṣoṣo ni wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ èso rẹ̀. Ọlọ́run sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn bí wọ́n bá jẹ ẹ́. Ó ní: “Dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Ẹ̀kọ́ nípa ṣíṣe ìgbọràn ni. Bẹ́ẹ̀ ni o, kí á lè máa wà láàyè nìṣó, a ní láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run! Tí Ádámù àti Éfà bá kàn sọ ọ́ lẹ́nu lásán pé àwọn yóò ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ìyẹn nìkan ò tó. Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohun tí wọ́n ń ṣe fi hàn pé wọ́n á gbọ́ràn lóòótọ́. Bí wọ́n bá ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run, a jẹ́ pé wọ́n ń fi hàn pé àwọn fẹ́ràn rẹ̀ àti pé àwọn fẹ́ kí ó jẹ́ Ẹni tí yóò máa ṣàkóso àwọn. Nígbà náà, wọ́n á lè máa gbé inú Párádísè títí láé. Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá jẹ èso igi yẹn, kí ni ìyẹn yóò fi hàn?—
Yóò fi hàn pé wọn kò mọrírì oore tí Ọlọ́run ṣe fún wọn. Ká sọ pé o wà níbẹ̀ nígbà yẹn, ǹjẹ́ wàá ṣe ìgbọràn sí Jèhófà?— Ádámù àti Éfà kọ́kọ́ ṣègbọràn. Àmọ́ nígbà tó yá, ẹnì kan tó wà nípò tó ga jù wọ́n lọ tan Éfà jẹ. Ó mú kó ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Ta ni ẹni náà?—
Bíbélì sọ pé ejò bá Éfà sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n o sáà mọ̀ pé ejò kò lè sọ̀rọ̀ rárá. Báwo ló ṣe wá sọ̀rọ̀ nígbà náà?— Áńgẹ́lì kan ló ṣe é tó fi dà bí ẹni pé ejò ló ń sọ̀rọ̀. Àmọ́ áńgẹ́lì yẹn ló ń sọ̀rọ̀ o. Èrò burúkú ti wà lọ́kàn áńgẹ́lì náà tẹ́lẹ̀. Ó fẹ́ kí Ádámù àti Éfà máa sin òun bí Ọlọ́run. Ó fẹ́ kí wọ́n máa ṣe ohun tí òun bá fẹ́. Ó fẹ́ gba ipò Ọlọ́run.
Bí áńgẹ́lì burúkú náà ṣe mú kí Éfà máa ro èrò tí kò dára nìyẹn. Ó lo ejò láti sọ fún un pé: ‘Irọ́ ni Ọlọ́run ń pa fún yín jàre. Ẹ ò ní kú rárá tẹ́ ẹ bá jẹ èso igi yẹn. Ńṣe ni ẹ máa gbọ́n bí Ọlọ́run.’ Tó bá jẹ́ ìwọ ni, ṣé wàá gba nǹkan tí ohùn yẹn sọ gbọ́?—
Éfà bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa bó ṣe máa jẹ ohun tí Ọlọ́run kò fún un. Bó ṣe lọ jẹ èso igi tí Ọlọ́run sọ pé kò gbọ́dọ̀ jẹ nìyẹn o. Lẹ́yìn náà ó wá fún Ádámù nínú rẹ̀. Ádámù mọ̀ pé irọ́ ni ejò ń pa o, ṣùgbọ́n kò fẹ́ fi Éfà sílẹ̀. Ó fẹ́ràn Éfà ju Ọlọ́run lọ. Nítorí náà, òun náà jẹ lára èso igi yẹn pẹ̀lú.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; 1 Tímótì 2:14.
Kí ló wá ṣẹlẹ̀?— Ádámù àti Éfà di aláìpé, wọ́n di arúgbó, wọ́n sì kú. Nítorí pé wọ́n di aláìpé, gbogbo ọmọ tí wọ́n bí di aláìpé pẹ̀lú, wọ́n ń darúgbó, wọ́n sì Róòmù 5:12) Bíbélì sọ fún wa pé áńgẹ́lì tó purọ́ fún Éfà là ń pè ní Sátánì Èṣù, pé àwọn áńgẹ́lì yòókù tó di áńgẹ́lì burúkú là ń pè ní ẹ̀mí èṣù.—Jákọ́bù 2:19; Ìṣípayá 12:9.
ń kú. Ọlọ́run kò purọ́ rárá! Lóòótọ́, téèyàn bá fẹ́ máa wà láàyè lọ ó gbọ́dọ̀ gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu. (Ṣé o ti wá mọ ohun tó jẹ́ kí áńgẹ́lì rere tí Ọlọ́run dá di áńgẹ́lì burúkú báyìí?— Ó jẹ́ nítorí pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í ro èrò burúkú. Ó fẹ́ jẹ́ ọ̀gá pátápátá ni ayé àti ọ̀run. Ó mọ̀ pé Ọlọ́run ti sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n máa bímọ, ó wá fẹ́ kí gbogbo wọn pátá máa sin òun. Èṣù fẹ́ mú kí gbogbo èèyàn ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Nítorí náà, ó máa ń gbìyànjú láti fi èrò tí kò dára sí wa lọ́kàn.—Jákọ́bù 1:13-15.
Èṣù sọ pé kò sí ẹnikẹ́ni tó fẹ́ràn Jèhófà láti ọkàn wá. Ó sọ pé ìwọ àti èmi kò fẹ́ràn Ọlọ́run, àti pé kò wù wá rárá ká máa ṣe ohun tí Ọlọ́run bá sọ. Ó ní kìkì ìgbà tí gbogbo nǹkan bá ń lọ bá a ṣe fẹ́ nìkan la máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà. Ṣé òótọ́ ni Èṣù sọ? Ṣé bí a ṣe ń ṣe nìyẹn?
Olùkọ́ Ńlá náà sọ pé òpùrọ́ ni Èṣù! Jésù ṣègbọràn sí Jèhófà láti fi hàn kedere pé òun fẹ́ràn Rẹ̀ ní tòótọ́. Ìgbà tí nǹkan rọrùn nìkan kọ́ ni Jésù ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ìgbà gbogbo ló ń ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run, kódà títí kan ìgbà tí àwọn èèyàn mú kó nira fún un láti ṣègbọràn sí I. Ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí tó fi kú. Èyí ló jẹ́ kí Ọlọ́run jí i dìde kó lè máa wà láàyè lọ títí láé.
Nígbà náà, ta lo máa sọ pé ó jẹ́ ọ̀tá wa burúkú jù lọ?— Ní tòótọ́, Sátánì Èṣù ni o. Ǹjẹ́ o lè fojú rí i?— Rárá o! Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ó wà, àti pé ipò rẹ̀ ga ju tiwa lọ àti pé ó lágbára jù wá lọ. Ṣùgbọ́n, ta ni ipò rẹ̀ ga ju ti Èṣù lọ?— Jèhófà Ọlọ́run ni o. Nítorí náà, a mọ̀ pé Ọlọ́run lè dáàbò bò wá.
Ka ohun tí Bíbélì sọ nípa Ẹni tó yẹ ká máa sìn: Diutarónómì 30:19, 20; Jóṣúà 24:14, 15; Òwe 27:11; àti Mátíù 4:10.