ORÍ 33
Jésù Lè Dáàbò Bò Wá
NÍGBÀ tí Jésù dàgbà tí ó sì gbọ́ nípa bí a ṣe dáàbò bo òun nígbà ọmọdé, ǹjẹ́ o rò pé ó gbàdúrà sí Jèhófà tí ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀?— Kí ni o rò pé ó ṣeé ṣe kí Jésù sọ fún Màríà àti Jósẹ́fù nígbà tí ó gbọ́ pé wọ́n gbé òun lọ sí Íjíbítì láti lè gba ẹ̀mí òun là?—
Àmọ́ ṣá o, Jésù kì í ṣe ọmọdé mọ́ báyìí. Kò tiẹ̀ gbé lórí ilẹ̀ ayé mọ́ bíi ti ìgbà àtijọ́. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní máa ń rò nípa Jésù ni pé ó kàn jẹ́ ọmọ kékeré jòjòló kan tó wà nínú ibùjẹ ẹran?— Ìgbà Kérésìmesì ni èyí sábà máa ń hàn jù lọ nítorí àwòrán Jésù tí wọ́n yà gẹ́gẹ́ bí ọmọ kékeré jòjòló sábà máa ń wà káàkiri.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò gbé lórí ilẹ̀ ayé mọ́, ǹjẹ́ o gbà pé ó ṣì wà láàyè?— Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run jí i dìde nígbà tí ó kú, ó sì ti di Ọba tí ó lágbára ní ọ̀run nísinsìnyí. Kí ni o rò pé ó lè ṣe láti fi dáàbò bo àwọn tó bá ń sìn ín?— Ṣé o rí i, nígbà tí Jésù wà ní ayé, ó fi hàn bí òun yóò ṣe dáàbò bo àwọn tó bá fẹ́ràn òun. Jẹ́ kí á wo bí ó ṣe ṣe é ní ọjọ́ kan tí òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jọ wọ ọkọ̀ ojú omi pa pọ̀.
Ó jẹ́ ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ kan. Jésù ti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà ní ẹ̀gbẹ́ Òkun Gálílì. Òkun yìí jẹ́ adágún omi tó gùn tó nǹkan bí ogún kìlómítà, ó sì fẹ̀ tó kìlómítà méjìlá. Wàyí o, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí a sọdá sí ìhà kejì adágún.” Nítorí náà, wọ́n wọnú ọkọ̀ ojú omi kan, wọ́n sì gbéra láti sọdá adágún náà sí ìhà kejì. Ó ti rẹ Jésù gan-an, nítorí náà ó bọ́ sí apá ẹ̀yìn ọkọ́ náà ó sì sùn sórí ìrọ̀rí kan. Láìpẹ́ ó sùn wọra.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò sùn ní tiwọn nítorí kí wọ́n lè máa darí ọkọ̀ náà. Gbogbo nǹkan lọ dáadáa fúngbà díẹ̀, àmọ́ lójijì, ìjì líle kan bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́. Ìjì náà wá ń fẹ́ lọ́nà tó lágbára gan-an, ìgbì òkun sì ń ga sí i. Ìgbì yìí bẹ̀rẹ̀ sí gbá omi sínú ọkọ̀, omi sì fẹ́ kún inú ọkọ̀ náà.
Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé ọkọ̀ wọn yóò rì. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù kò ba Jésù ní tiẹ̀ nítorí ó ṣì ń sùn ní ẹ̀yìn ọkọ̀. Níkẹyìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn jí i, wọ́n sọ pé: ‘Olùkọ́ni, Olùkọ́ni, a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú sínú ìjì yìí.’ Nítorí náà, Jésù dìde, ó bá ẹ̀fúùfù àti ìgbì náà wí. Ó sọ pé: “Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!”
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ẹ̀fúùfù náà Lúùkù 8:22-25; Máàkù 4:35-41.
dáwọ́ dúró, adágún náà sì pa rọ́rọ́. Ẹnu ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà. Wọn kò tíì rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ara wọn pé: ‘Ta nìyí ní ti gidi, nítorí ó ń pa àṣẹ fún ẹ̀fúùfù àti omi pàápàá, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i?’—Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí Jésù jẹ́?— Ǹjẹ́ o mọ ibi tí ó ti rí agbára ńlá tó ní?— Kò yẹ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn máa bẹ̀rù rárá nígbà tí Jésù wà pẹ̀lú wọn níbẹ̀, nítorí Jésù kì í ṣe èèyàn kan lásán. Ó lè ṣe àwọn ohun ìyanu tí ẹnikẹ́ni mìíràn kò lè ṣe. Jẹ́ kí ń sọ ohun mìíràn tí ó tún ṣe ní àkókò kan nínú òkun tí ń ru.
Ọjọ́ mìíràn lẹ́yìn èyí ni. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Jésù sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wọnú ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n sì sọdá sí apá kejì òkun náà ṣáájú òun. Lẹ́yìn náà Jésù gun orí òkè lọ ní òun nìkan. Ibi tó dákẹ́ rọ́rọ́ ni, tí ó ti lè gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọnú ọkọ̀ wọ́n sì gbéra láti sọdá òkun náà. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, ẹ̀fúùfù kan bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́. Ó ń fẹ́ lọ́nà tó lágbára
púpọ̀ gan-an. Ilẹ̀ ti ṣú ní gbogbo àkókò yìí. Àwọn ọkùnrin náà tú ìgbòkun ọkọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wa ọkọ̀ náà. Ṣùgbọ́n wọn kò lè lọ jìnnà nítorí ẹ̀fúùfù líle náà ń fẹ́ lù wọ́n. Ọkọ̀ náà ń bì síwá sẹ́yìn nínú ìgbì gíga náà, omi sì ń rọ́ sínú ọkọ̀. Àwọn ọkùnrin náà sapá gidigidi láti wa ọkọ̀ dé èbúté, ṣùgbọ́n kò ṣeé ṣe fún wọn.Jésù ṣì wà lórí òkè ní òun nìkan. Ó ti wà níbẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ó rí i pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wà nínú ewu láàárín ìgbì gíga náà. Nítorí náà, ó sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè wá sí etíkun. Jésù fẹ́ láti ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí rìn lọ lórí òkun tó ń ru láti lọ bá wọn!
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ tí o bá gbìyànjú láti rìn lórí omi?— Ìwọ yóò rì, o sì lè kú sínú omi. Ṣùgbọ́n Jésù yàtọ̀ ní tirẹ̀. Ó ní agbára àrà ọ̀tọ̀. Jésù rìn púpọ̀ gan-an kí ó tó dé ibi tí ọkọ̀ náà wà. Nítorí náà, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di àfẹ̀mọ́jú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó rí Jésù tó ń rìn bọ̀ lọ́dọ̀ wọn lórí omi. Ṣùgbọ́n wọn ò lè gba ohun tí wọ́n rí yẹn gbọ́. Ẹ̀rù bà wọ́n, nítorí náà wọ́n kígbe. Nígbà náà, Jésù sọ̀rọ̀ sí wọn ó ní: “Ẹ mọ́kànle, èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”
Gbàrà tí Jésù wọnú ọkọ̀ náà, òkun tó ń ru tẹ́lẹ̀ rọlẹ̀ . Ẹnu tún ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́ẹ̀kan sí i. Wọ́n wólẹ̀ níwájú Jésù wọ́n sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ jẹ́ ní ti tòótọ́.”—Mátíù 14:22-33; Jòhánù 6:16-21.
Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ohun tó dùn mọ́ni láti wà ní ayé ìgbà yẹn, kí á máa fojú wa rí bí Jésù ti ń ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀?— Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jésù fi ṣe ohun ìyanu wọ̀nyẹn?— Ó ṣe nǹkan wọ̀nyẹn nítorí pé ó fẹ́ràn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ó tún ṣe iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn láti fi agbára ńlá tí ó ní hàn, èyí tí yóò lò lọ́jọ́ iwájú gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run.
Lóde òní, Sátánì ń sapá láti dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù dúró Ìṣe 12:2; Ìṣípayá 1:9.
kí wọ́n má ṣe sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, àmọ́ Jésù sábà máa ń lo agbára rẹ̀ láti fi dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù kò lo agbára rẹ̀ láti fi dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n má ṣe ṣàìsàn, tàbí láti mú wọn lára dá tí wọ́n bá ṣàìsàn. Kódà gbogbo àwọn àpọ́sítélì Jésù kú ni níkẹyìn. Ṣe ni wọ́n pa Jákọ́bù ẹ̀gbọ́n Jòhánù, wọ́n sì fi Jòhánù fúnra rẹ̀ sínú ẹ̀wọ̀n.—Bákan náà ló ṣe ń ṣẹlẹ̀ lóde òní. Yálà àwọn èèyàn sin Jèhófà tàbí wọn kò sìn ín, gbogbo wọn ni ó lè ṣàìsàn kí wọ́n sì kú. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run, nǹkan máa yàtọ̀. Kò ní sí ẹnikẹ́ni tó máa bẹ̀rù mọ́ nígbà yẹn, nítorí pé Jésù á lo agbára rẹ̀ láti máa ṣe oore fún gbogbo àwọn tó bá ṣègbọràn sí i.—Aísáyà 9:6, 7.
Àwọn ẹsẹ Bíbélì mìíràn tó fi agbára ńlá tí Jésù ní hàn, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọ́run yàn ṣe Alákòóso nínú Ìjọba Ọlọ́run, ni Dáníẹ́lì 7:13, 14; Mátíù 28:18; àti Éfésù 1:20-22.