Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 2

Lẹ́tà Kan Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Fẹ́ràn Wa

Lẹ́tà Kan Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Fẹ́ràn Wa

SỌ FÚN mi, ìwé wo ló wù ọ́ jù lọ?— Àwọn ọmọ kan á mú ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko. Àwọn ọmọ mìíràn á sì mú ìwé tó ní ọ̀pọ̀ àwòrán nínú. Ó máa ń gbádùn mọ́ni láti ka irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀.

Àmọ́ àwọn ìwé tó dára jù lọ láyé yìí làwọn tó sọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run fún wa. Ọ̀kan wà lára irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ tó ṣe pàtàkì ju àwọn yòókù lọ. Ṣé o lè sọ orúkọ ìwé náà fún mi?— Bíbélì ni.

Kí nìdí tí Bíbélì fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?— Ìdí ni pé ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó sọ fún wa nípa Ọlọ́run, ó sì sọ fún wa nípa àwọn nǹkan dáadáa tí Ọlọ́run máa ṣe fún wa. Ó tún fi àwọn ohun tó yẹ kí á ṣe hàn wá kí inú Ọlọ́run lè dùn sí wa. Ó dà bíi lẹ́tà kan tí Ọlọ́run kọ sí wa.

Lóòótọ́, Ọlọ́run lè kọ Bíbélì ní ọ̀run kí ó sì fi fún àwa èèyàn lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé láti kọ apá tó pọ̀ jù lọ nínú Bíbélì, àmọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀ ti wá.

Báwo ni wọ́n ṣe rí ohun tí wọ́n kọ gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run?— Jẹ́ kí n fún ọ ní àpẹẹrẹ kan. Tá a bá gbọ́ ohùn ẹnì kan lórí rédíò, ó lè jẹ́ pé ibi tó jìnnà ni ẹni tá a gbọ́ ohùn rẹ̀ yìí wà. Tá a bá sì ń wo tẹlifíṣọ̀n, a lè rí àwòrán àwọn èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè mìíràn, a sì lè gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ.

Àwọn èèyàn lè wa ọkọ̀ òfuurufú lọ sínú òṣùpá, kí wọ́n sì máa fi ìròyìn nípa ohun tí wọ́n ń rí ránṣẹ́ sí wa ní ayé. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀?— Bí ènìyàn bá lè ṣe ìyẹn, Ọlọ́run ńkọ́? Ṣé ó lè fi ìsọfúnni ránṣẹ́ láti ọ̀run àbí kò lè ṣe bẹ́ẹ̀?— Ó lè ṣe bẹ́ẹ̀! Ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tipẹ́tipẹ́ kí àwọn èèyàn tó ní rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n.

Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run lè bá wa sọ̀rọ̀ láti ọ̀nà jíjìn?

Ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Mósè. Ó gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí. Kì í ṣe pé ó rí Ọlọ́run o, àmọ́ ó gbọ́ ohùn rẹ̀ ni. Àwọn èèyàn púpọ̀ wà níbẹ̀ nígbà tó gbọ́ ohùn yẹn. Kódà lọ́jọ́ tí à ń wí yìí, Ọlọ́run mú kí òkè ńlá kan mì tìtì, mànàmáná kọ yẹ̀rì, àrá sì sán. Àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ mọ̀ pé Ọlọ́run ló ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ̀rù bà wọ́n gan-an. Ni wọ́n bá sọ fún Mósè pé: “Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run bá wa sọ̀rọ̀ kí àwa má bàa kú.” Nígbà tó yá, Mósè kọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run sọ síbì kan. Inú Bíbélì làwọn ohun tí Mósè kọ wà.—Ẹ́kísódù 20:18-21.

Mósè ló kọ àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì. Àmọ́ òun nìkan kọ́ ló kọ gbogbo ìwé tó wà nínú Bíbélì o. Nǹkan bí ogójì ọkùnrin ni Ọlọ́run lò láti kọ àwọn ìwé inú Bíbélì. Ìgbà láéláé làwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti gbé lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni wọ́n sì fi kọ gbogbo ìwé tó wà nínú Bíbélì. Ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún! Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kò bára wọn pàdé rí. Síbẹ̀, kò sí ìkankan nínú ohun tí ẹnì kan kọ sílẹ̀ tó ta ko ti ẹnì kejì.

Kí ni orúkọ àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì wọ̀nyí?

Àwọn kan lára àwọn ọkùnrin tí Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì jẹ́ olókìkí èèyàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé olùṣọ́ àgùntàn ni Mósè tẹ́lẹ̀, ó di aṣáájú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà tó yá. Ọba ni Sólómọ́nì ní tirẹ̀, òun ló gbọ́n jù lọ òun ló sì ní ọrọ̀ jù lọ ní ayé ìgbà yẹn. Àmọ́ àwọn mìíràn lára àwọn tó kọ Bíbélì kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀. Igi ọ̀pọ̀tọ́ ni Ámósì ń bójú tó ní tirẹ̀.

Síwájú sí i, ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì jẹ́ oníṣègùn. Ǹjẹ́ o mọ orúkọ rẹ̀?— Lúùkù ni. Ẹnì kan tún wà lára àwọn tó kọ Bíbélì tó jẹ́ agbowó orí tẹ́lẹ̀. Mátíù lorúkọ rẹ̀. Òmíràn tiẹ̀ wà lára wọn tó jẹ́ amòfin, o mọ̀ nípa òfin ìsìn àwọn Júù gan-an. Òun ló kọ ìwé tó pọ̀ jù nínú gbogbo àwọn tó kọ Bíbélì. Ṣé o mọ orúkọ rẹ̀?— Pọ́ọ̀lù ni. Apẹja ni Pétérù àti Jòhánù. Ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni wọ́n, àwọn náà sì wà lára àwọn tó kọ Bíbélì.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kọ Bíbélì kọ àwọn ohun tí Ọlọ́run yóò ṣe lọ́jọ́ iwájú sílẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀?— Ọlọ́run ló fi hàn wọ́n. Òun ló sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún wọn.

Ní àkókò tí Jésù Olùkọ́ Ńlá náà wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n ti kọ apá tó pọ̀ jù lọ nínú Bíbélì. Àmọ́ o, rántí pé Olùkọ́ Ńlá náà gbé ní ọ̀run kí ó tó wá sí orí ilẹ̀ ayé. Ó mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe. Ṣé Olùkọ́ Ńlá náà gbà gbọ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá?— Bẹ́ẹ̀ ni.

Jésù máa ń ka ọ̀rọ̀ jáde látinú Bíbélì tó bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run. Nígbà mìíràn, orí ló ti máa ń sọ nǹkan tí Bíbélì wí fún àwọn èèyàn. Jésù tún sọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún wa. Jésù sọ pé: “Àwọn ohun náà tí mo sì gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mo ń sọ nínú ayé.” (Jòhánù 8:26) Àwọn ohun tí Jésù gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run pọ̀ gan-an, nítorí pé ó ti gbé lọ́dọ̀ Ọlọ́run rí. Inú ìwé wo ni àwọn ohun tí Jésù sọ wà?— Inú Bíbélì ni. Nítorí kí á lè máa rí ọ̀rọ̀ Jésù kà ni Ọlọ́run ṣe ní kí wọ́n kọ ọ́ sínú Bíbélì.

Nígbà tí Ọlọ́run lo àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì, èdè tí àwọn èèyàn ń sọ nígbà yẹn ni wọ́n fi kọ ọ́. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi kọ èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé Bíbélì ní èdè Hébérù, tí wọ́n kọ àwọn kan ní èdè Árámáíkì, tí wọ́n sì kọ àwọn púpọ̀ ní èdè Gíríìkì. Ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní ò lè ka àwọn èdè wọ̀nyẹn, ìdí nìyẹn tí a fi túmọ̀ Bíbélì sí àwọn èdè mìíràn. Lóde òní, a lè rí Bíbélì kà ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì, igba ó lé ọgọ́ta [2,260]. Àwọn èdè yẹn mà pọ̀ gan-an o! Bíbélì jẹ́ lẹ́tà kan tí Ọlọ́run kọ sí gbogbo èèyàn. Lóòótọ́ ni a túmọ̀ rẹ̀ sí èdè tó pọ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run lo ní ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀.

Àwọn ohun tí Bíbélì sọ ṣe pàtàkì gan-an fún wa. Wọ́n ti kọ Bíbélì tipẹ́tipẹ́. Síbẹ̀ ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí lórí ilẹ̀ ayé. Ó sì tún sọ ohun tí Ọlọ́run yóò ṣe láìpẹ́ fún wa. Ohun tí Bíbélì sọ máa ń gbádùn mọ́ni! Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ọjọ́ iwájú yóò dára.

Àwọn ohun wo lo lè rí kọ́ tó o bá ń ka Bíbélì?

Bíbélì tún sọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí á máa ṣe. Ó sọ ohun tí ó yẹ kí á máa ṣe àti èyí tí kò yẹ kí á máa ṣe. Ó yẹ kó o mọ àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ó sì yẹ kí èmi náà mọ̀ wọ́n. Bíbélì sọ ìtàn àwọn èèyàn tó ṣe nǹkan tí kò dára àti ìyà tó jẹ wọn. Bíbélì sọ ìtàn wọn fún wa kí a má bàa jẹ irú ìyà tí wọ́n jẹ. Bíbélì tún sọ fún wa nípa àwọn èèyàn tó ṣe ohun tó dára àti ohun rere tó yọrí sí fún wọn. Nítorí tiwa ni Ọlọ́run ṣe jẹ́ kí wọ́n kọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí sílẹ̀.

Kí Bíbélì lè yé wa dáadáa ìbéèrè kan wà tí a máa dáhùn. Ìbéèrè náà ni pé: Ta ló fún wa ní Bíbélì?— Ọlọ́run ni. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni Bíbélì ti wá. Nígbà náà, báwo la ṣe máa fi hàn pé a jẹ́ ọlọgbọ́n?— A ń fi hàn pé a jẹ́ ọlọgbọ́n tá a bá ń fetí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a sì ń ṣe ohun tó sọ.

Nítorí náà, ó yẹ ká máa wá àkókò láti máa ka Bíbélì pa pọ̀. Bí ọ̀rẹ́ wa kan tá a fẹ́ràn gan-an bá kọ lẹ́tà sí wa, a óò fẹ́ láti kà á léraléra. Ìdí ni pé lẹ́tà náà ṣe pàtàkì lójú wa. Bó ṣe yẹ kí Bíbélì jẹ́ sí wa nìyẹn nítorí pé láti ọ̀dọ̀ Ẹnì kan tó fẹ́ràn wa jù lọ ló ti wá. Lẹ́tà kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó fẹ́ràn wa ni.

Lo àkókò díẹ̀ sí i láti fi ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí tó fi hàn pé lóòótọ́ ni Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a kọ fún àǹfààní wa: Róòmù 15:4; 2 Tímótì 3:16, 17 àti 2 Pétérù 1:20, 21.