Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Yẹ Kí Àwọn Òbí Ṣe fún Àwọn Ọmọ Wọn

Ohun Tó Yẹ Kí Àwọn Òbí Ṣe fún Àwọn Ọmọ Wọn

GBOGBO bàbá àti ìyá tó ti bímọ rí ti kópa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó kọjá ohun tí èèyàn lè lóye lẹ́kún-únrẹ́rẹ́. Ohun kan láti ara bàbá àti ohun kan láti ara ìyá para pọ̀ di ẹyọ kan. Nípa bẹ́ẹ̀, odidi ọmọ èèyàn dàgbà nínú ìyà rẹ̀. Abájọ nígbà náà tí àwọn èèyàn fi máa ń ka ọmọ bíbí sí “iṣẹ́ ìyanu ńlá.”

Àmọ́ ṣá o, ńṣe ni bíbí ọmọ sáyé jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ẹrù iṣẹ́ fún àwọn òbí ọmọ ọ̀hún. Àwọn ìkókó kì í lè dá ohunkóhun ṣe fúnra wọn lákọ̀ọ́kọ́, àwọn òbí wọn tàbí àwọn àgbà mìíràn ló máa ń tọ́jú wọn. Bí wọ́n bá ti wá ń dàgbà sí i, wọn á nílò àbójútó mìíràn yàtọ̀ sí ìpèsè ìtọ́jú nípa tí ara. Wọ́n á nílò ìrànlọ́wọ́ kí làákàyè wọn, ìmí-ẹ̀dùn wọn, ìwà rere wọn àti ipò tẹ̀mí wọn tó lè dàgbà dáadáa.

Ní pàtàkì, àwọn ọmọ nílò ìfẹ́ àwọn òbí wọn láti lè dàgbà sókè bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Lóòótọ́, ó ṣe pàtàkì kí àwọn òbí máa sọ fún àwọn ọmọ pé àwọn fẹ́ràn wọn, àmọ́ ìyẹn ò tó, ìṣe wọn gbọ́dọ̀ fi hàn bẹ́ẹ̀. Dájúdájú, àwọn ọmọ ń fẹ́ àpẹẹrẹ rere láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn. Wọ́n nílò ẹ̀kọ́ ilé àti àwọn ìlànà ìwà rere tí wọn yóò máa tẹ̀ lé nígbèésí ayé. Láti kékeré jòjòló wọn ló sì yẹ kí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí gba èyí. Ó lè yọrí sí ohun ìbànújẹ́, àní ìbànújẹ́ tó tiẹ̀ ga pàápàá, tí àwọn ọmọ kò bá tètè rí ẹ̀kọ́ yìí gbà láti kékeré.

Àwọn ìlànà inú Bíbélì ló dára jù lọ nínú gbogbo àwọn ìlànà tí ń bẹ láyé yìí. Àwọn ìtọ́sọ́nà tí a bá fà yọ látinú Bíbélì máa ń ṣàǹfààní lọ́nà tí kò lẹ́gbẹ́. Irú àwọn ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọ rí i pé ohun tí à ń bá àwọn sọ kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó kàn ti ẹnu àwọn èèyàn wá lásán, bí kò ṣe ohun tí Ẹlẹ́dàá wọn, Bàbá wọn ní ọ̀run wí. Èyí máa ń jẹ́ kí ìmọ̀ràn náà ní agbára tí kò lẹ́gbẹ́.

Bíbélì gba àwọn òbí níyànjú pé kí wọ́n sapá gidigidi láti rí i pé àwọn gbin àwọn ìlànà tó tọ́ àtèyí tó yẹ sí àwọn ọmọ wọn lọ́kàn. Àmọ́ bí àwọn ọmọ bá ti ń dàgbà, ó sábà máa ń ṣòro fún àwọn òbí láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé. A pilẹ̀ ṣe ìwé yìí, Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, gẹ́gẹ́ bí ohun ìrànlọ́wọ́ tí kò ní jẹ́ kí irú ipò bẹ́ẹ̀ wáyé. Ìwé yìí pèsè àwọn nǹkan tẹ̀mí àti ìlànà ìwà rere tí àwọn òbí àtàwọn ọmọ lè jùmọ̀ máa kà pa pọ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, yóò mú kí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lè bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ láàárín àwọn èwe àti àwọn ẹni tí wọ́n jọ ń ka ìwé yìí.

Ìwọ yóò ṣàkíyèsí pé ìwé yìí ń fẹ́ kí àwọn ọmọdé máa lóhùn sí ọ̀rọ̀ bí ẹ ṣe ń kà á lọ. A béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó yẹ nínú ìwé yìí. Ẹ óò rí àmì dáàṣì (—) níbi tí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ bá wà. A fi àmì yìí síbẹ̀ láti rán yín létí pé kẹ́ ẹ dánu dúró díẹ̀ kí ọmọ náà lè sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Àwọn ọmọ máa ń fẹ́ láti sọ̀rọ̀. Bí ọmọ kan kò bá sì ti rí àyè dá sí ọ̀rọ̀, ẹ̀kọ́ náà kò ní pẹ́ sú u.

Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, àwọn ìbéèrè yìí á jẹ́ kí o mọ èrò inú ọmọ náà. Lóòótọ́, ìdáhùn ọmọ náà lè má tọ̀nà o. Ṣùgbọ́n a ti ṣètò pé kí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé ìbéèrè náà mú kí àwọn ọmọ mọ bí a ṣe ń ronú lọ́nà tó dára.

Lára ohun àrà ọ̀tọ̀ inú ìwé yìí ni àwọn àwòrán rẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ́n [230] lọ. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn àwòrán yìí ní àkọlé tó ń gba ọmọ níyànjú láti sọ èrò ọkàn rẹ̀ nípa ohun tí ó rí àti ohun tí ó kà. Nítorí náà, kí ìwọ àti ọmọ náà jùmọ̀ ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn àwòrán yìí pọ. Wọ́n jẹ́ ohun akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àtàtà tó lè mú kí ọmọ náà túbọ̀ rí bí ẹ̀kọ́ tí à ń kọ́ òun ti ṣe pàtàkì tó.

Tí ọmọ náà bá ti mọ ìwé kà, kí o fún un ní ìṣírí láti máa kà á sí ọ létí, kí ó sì máa dá a kà fúnra rẹ̀. Bí ó bá ṣe ń kà á tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìmọ̀ràn àtàtà inú rẹ̀ yóò ṣe túbọ̀ máa wọ̀ ọ́ lọ́kàn tó. Ṣùgbọ́n kí ìdè ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ láàárín ìwọ àti ọmọ náà lè túbọ̀ lágbára sí i, rí i dájú pé ẹ jùmọ̀ ń ka ìwé yìí pọ̀, kí ẹ sì máa kà á déédéé.

Ní báyìí, àwọn ọmọ ń bá ìwà ìṣekúṣe, ìbẹ́mìílò àti àwọn ìwà ìbàjẹ́ mìíràn pàdé lọ́nà kan tó jẹ́ pé ní nǹkan bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, a fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè gbà pé ó lè ṣẹlẹ̀. Nítorí náà wọ́n nílò ààbò, ìyẹn sì ni ohun tí ìwé yìí ń ṣèrànwọ́ láti pèsè lọ́nà tó buyì kúnni síbẹ̀ tó sọ ojú abẹ níkòó. Àmọ́ o, ó ṣe pàtàkì pé kí á darí àwọn ọmọ sọ́dọ̀ Orísun gbogbo ọgbọ́n, ìyẹn Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà Ọlọ́run. Ohun tí Jésù, Olùkọ́ Ńlá, máa ń ṣe nígbà gbogbo nìyẹn. Àdúrà wa ni pé kí ìwé yìí ran ìwọ àti ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé yín di èyí tó ń mú inú Jèhófà dùn, kí ẹ lè jèrè ìbùkún ayérayé.