Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 1

Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tó Dára

Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tó Dára

Ìṣe 17:22

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Ó yẹ kí ohun tó o máa sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ mú kó wu àwọn èèyàn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé, kó o sì jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ náà. Béèrè ìbéèrè kan, sọ ọ̀rọ̀ kan, sọ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ tàbí kó o sọ ohun kan tó o gbọ́ nínú ìròyìn tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn.

  • Sọ ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé. Rí i dájú pé ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí àti idí tó fi yẹ káwọn èèyàn gbọ́ nípa rẹ̀ ṣe kedere nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ.

  • Sọ ìdí tí ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fi ṣe pàtàkì. Rí i dájú pé ohun tó o fẹ́ sọ wúlò fún àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Ó yẹ kí wọ́n rí bí ohun tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́.