Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 11

Ìtara

Ìtara

Róòmù 12:11

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Máa fi ìtara sọ̀rọ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ á ta àwọn olùgbọ́ rẹ jí, á sì fún wọn níṣìírí láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tó ò ń sọ.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Bó o ṣe ń múra sílẹ̀ láti sọ ọ̀rọ̀ rẹ, ronú jinlẹ̀ nípa bí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe pàtàkì tó. Rí i dájú pé ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yé ẹ dáadáa débi tí wàá fi lè sọ̀rọ̀ látọkàn wá.

  • Ronú nípa àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Ronú nípa àǹfààní táwọn èèyàn máa rí nínú ohun tó o fẹ́ kà tàbí ohun tó o fẹ́ kọ́ wọn. Ronú nípa bó o ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀ lọ́nà tó máa mú kí wọ́n mọyì ohun tó o sọ.

  • Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tani jí. Fi ìtara sọ̀rọ̀. Fara ṣàpèjúwe, kó o sì túra ká, ńṣe ni ìyẹn á fi hàn pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán lò ń sọ.