Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 13

Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò

Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò

Òwe 3:21

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ rí bí ohun tó ò ń sọ ṣe kan ìgbésí ayé wọn, kó o sì sọ bí wọ́n ṣe máa lò ó.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Ronú nípa àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Ronú nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ, kó o sì ronú nípa apá tó máa ṣe wọ́n láǹfààní jù lọ lára ohun tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí.

  • Jálẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ ni kó o jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Látìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ ló ti yẹ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ti máa sọ lọ́kàn ara wọn pé, ‘Ọ̀rọ̀ yìí wúlò fún mi.’ Bó o ṣe ń ṣàlàyé kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan, máa sọ àwọn ọ̀nà pàtó tí wọ́n lè gbà lò ó. Má ṣe máa sọ̀rọ̀ lóréfèé.