Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 16

Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Gbéni Ró Kó sì Ṣàǹfààní

Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Gbéni Ró Kó sì Ṣàǹfààní

Jóòbù 16:5

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Sọ ohun tó máa yanjú ìṣòro, tó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Ní èrò tó dára nípa àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Gbà pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni àwọn onígbàgbọ́ bíi tìẹ fẹ́ ṣe. Tó o bá tiẹ̀ máa fún wọn ní ìmọ̀ràn, kọ́kọ́ gbóríyìn fún wọn látọkàn wá láwọn ìgbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.

  • Má sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa ohun tí kò dáa. Tó o bá fẹ́ fi ohun tí kò dáa ṣàlàyé nǹkan pàtàkì nìkan ni kó o sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ohun tó ṣàǹfààní ló yẹ kí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé.

  • Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bó ṣe yẹ. Sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe, àwọn nǹkan tó ń ṣe báyìí àtàwọn nǹkan tó máa ṣe fún aráyé lọ́jọ́ iwájú. Sọ ohun tó máa mú kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ní ìrètí àti ìgboyà.