Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 19

Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn

Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn

Òwe 3:1

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ rí bí ohun tí ò ń sọ ṣe wúlò tó, kí wọ́n sì ṣe ohun tó yẹ.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Sọ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n yẹ ara wọn wò. Béèrè àwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ tó máa jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ronú nípa ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan.

  • Sọ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n ní èrò tó dára. Rọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ pé kí wọ́n máa ronú jinlẹ̀ nípa ìdí tí wọ́n fi ń ṣe àwọn nǹkan tó dára. Jẹ́ kó yé wọn pé ohun tó dára jù lọ tó yẹ kó wà lọ́kàn wa tá a bá fẹ́ ṣe ohunkóhun ni ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà, àwọn èèyàn àti ẹ̀kọ́ Bíbélì. Sọ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì bọ́gbọ́n mu, kì í ṣe pé kó o kàn máa rọ̀jò ọ̀rọ̀ lé wọn lórí. Dípò tí wàá fi kàn wọ́n lábùkù, ohun tó dára ni pé nígbà tó o bá fi máa parí ọ̀rọ̀ rẹ kí wọ́n ti gba ìṣírí táá mú kí wọ́n sa gbogbo ipá wọn láti túbọ̀ máa ṣe dáadáa.

  • Jẹ́ kí àwọn èèyàn mọyì Jèhófà. Sọ bí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, àwọn ìlànà Bíbélì, àtàwọn àṣẹ tó wà nínú Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti bí wọ́n ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Sọ ohun tó máa jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ máa ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, kí wọ́n sì máa sapá láti ṣe ohun tó wù ú.