Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 20

Ìparí Ọ̀rọ̀ Tó Dára

Ìparí Ọ̀rọ̀ Tó Dára

Oníwàásù 12:13, 14

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Nígbà tí o bá ń parí ọ̀rọ̀ rẹ, rọ àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ pé kí wọ́n fi ohun tí wọ́n gbọ́ sọ́kàn, kí wọ́n sì ṣe ohun tó yẹ.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Jẹ́ kí ìparí ọ̀rọ̀ rẹ bá ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé mu. Tún àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ sọ, tàbí ko o gba ọ̀nà míì ṣàlàyé àwọn kókó náà àti àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ.

  • Fún àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ní ìṣírí. Sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, kó o sì sọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kó hàn pé ohun tí ò ń sọ dá ẹ lójú, kó o sì sọ̀rọ̀ látọkàn wá.

  • Jẹ́ kí ìparí ọ̀rọ̀ rẹ rọrùn, kó sì ṣe ṣókí. Má ṣe mú kókó túntun wọlé ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ṣókí, kó o sì gba àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ níyànjú láti ṣe ohun tó yẹ.