Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 4

Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ

Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ

Mátíù 22:41-45

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Kọ́kọ́ múra ọkàn àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ sílẹ̀ kó o tó ka Ìwé Mímọ́.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Ronú nípa ìdí tó o fi fẹ́ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ kà lọ́nà tó máa pe àfíyèsí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ sí kókó pàtàkì tó o fẹ́ mú jáde níbẹ̀.

  • Jẹ́ kó ṣe kedere pé ohun tí Bíbélì bá sọ la gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé. Tó bá jẹ́ pé àwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ lò ń bá sọ̀rọ̀, sọ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, inú rẹ̀ la sì ti lè rí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó ga jù lọ.

  • Sọ ohun tó máa jẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Béèrè ọ̀rọ̀ kan tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà máa dáhùn, sọ ìṣòro kan tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà máa yanjú tàbí kó o sọ ìlànà kan tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà máa mú kó ṣe kedere.