Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 9

Lo Ohun Tá A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Dára

Lo Ohun Tá A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Dára

Jẹ́nẹ́sísì 15:5

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Lo àwọn ohun tó ṣeé fojú rí lati mú kí kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ ṣe kedere.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Lo àwọn ohun tó ṣeé fojú rí tó máa mú kí ohun tó o fẹ́ kọ́ni túbọ̀ yéni. Lo fọ́tò, àwòrán tá a fọwọ́ yà, máàpù, àtẹ ìsọfúnni tàbí àwọn ohun míì tó ṣeé fojú rí láti ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì, má ṣe lò ó fún àwọn ohun tí kò pọn dandan. Fi sọ́kàn pé kò yẹ kó jẹ́ pé ohun tó ṣeé fojú rí tó o lò nìkan ni àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ máa rántí, ó tún yẹ kí wọ́n rántí ẹ̀kọ́ pàtàkì tó o kọ́ wọn.

  • Rí i dájú pé àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ rí ohun tó o fẹ́ fi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ náà.