Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

“Ó yẹ kí ẹ ti di olùkọ́.” (Héb. 5:12) Àbẹ́ ò rí nǹkan! Jèhófà tó jẹ́ Olùkọ́ tó dára jù lọ láyé àtọ̀run gbéṣẹ́ fún wa pé ká máa kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ nípa òun! Nígbàkigbà tí wọ́n bá ní ká kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà, bóyá nínú ìdílé, nínú ìjọ, tàbí lóde ẹ̀rí, àǹfààní ńlá ló jẹ́, ojúṣe pàtàkì sì ni. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́?

A lè rí ìdáhùn nínú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó ní: “Máa tẹra mọ́ kíkàwé fún ìjọ, máa gbani níyànjú, kí o sì máa kọ́ni.” Pọ́ọ̀lù tún fi kún un pé: “Tí o bá ń ṣe é, wàá lè gba ara rẹ àti àwọn tó ń fetí sí ọ là.” (1 Tím. 4:​13, 16) Ohun tó máa gbẹ̀mí àwọn èèyàn là lo fẹ́ sọ fún wọn. Torí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó o máa sunwọ̀n sí i nínú bó o ṣe ń kàwé àti bó o ṣe ń kọ́ni. Ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Díẹ̀ rèé lára ohun tó wà níbẹ̀.

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lójú ìwé kọ̀ọ̀kan lè jẹ́ ìlànà Bíbélì tó bá ẹ̀kọ́ tá à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mu tàbí kó jẹ́ àpẹẹrẹ bá a ṣe lè lo ẹ̀kọ́ náà

Jèhófà ni ‘Olùkọ́ Atóbilọ́lá.’ (Àìsá. 30:20) Òótọ́ ni pé ìwé yìí á mú kó o túbọ̀ mọ ìwé kà, ó sì máa jẹ́ kó o túbọ̀ mọ èèyàn kọ́, àmọ́ má gbàgbé pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ohun tí à ń wàásù ti wá, òun ló sì ń fa àwọn èèyàn wá sínú òtítọ́. (Jòh. 6:44) Torí náà, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́. Máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Jèhófà ni kó o máa pe àfiyèsí àwọn èèyàn sí, kì í ṣe ara rẹ. Sapá gidigidi láti mú kí àwọn èèyàn ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí Jèhófà.

Àǹfààní ńlá ni Jèhófà fún ẹ pé kó o máa kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ọkàn wa balẹ̀ pé tó o bá gbára lé “okun tí Ọlọ́run ń fúnni,” wàá ṣàṣeyọrí.​—1 Pet. 4:11.

Àwa tá a jọ jẹ́ olùkọ́,

Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà