Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ 6

Dáfídì Kò Bẹ̀rù

Dáfídì Kò Bẹ̀rù

Kí lo máa ṣe tí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́?— O lè jẹ́ mọ́mì tàbí dádì ẹ lo máa lọ bá kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àmọ́, ẹnì kan tún wà tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kò sẹ́ni tó lágbára tó ẹni yẹn. Ǹjẹ́ o mọ ẹni náà?— Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run ni. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Dáfídì nínú Bíbélì. Ó mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ran òun lọ́wọ́, ìdí nìyẹn tí kò fi bẹ̀rù.

Látìgbà tí Dáfídì ti wà ní ọmọ ìkókó ni àwọn òbí rẹ̀ ti kọ́ ọ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Èyí ni kò jẹ́ kó bẹ̀rù nígbà tí àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù ṣẹlẹ̀ sí i. Ó mọ̀ pé ọ̀rẹ́ òun ni Jèhófà àti pé Ó máa ran òun lọ́wọ́. Nígbà kan, tí Dáfídì ń tọ́jú àwọn àgùntàn lọ́wọ́, kìnnìún ńlá kan wá, ó sì fi ẹnu gbé àgùntàn kan! Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Dáfídì ṣe? Ó sáré tẹ̀ lé kìnnìún náà, ó sì fi ọwọ́ lásán pa á! Ìgbà kan tún wà tí béárì kan fẹ́ pa àgùntàn rẹ̀, Dáfídì tún pa ìyẹn náà! Ta lo rò pé ó ran Dáfídì lọ́wọ́?— Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ni.

ìgbà míì tún wà tí Dáfídì fi hàn pé òun kò bẹ̀rù. Nígbà yẹn, ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bá àwọn kan tí wọ́n ń pè ní àwọn Filísínì jà. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun yẹn ga gan-an, òmìrán ni! Gòláyátì lorúkọ rẹ̀. Òmìrán yìí ń fi àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì àti Jèhófà ṣe yẹ̀yẹ́. Ó ní tí àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì bá lágbára, kí wọ́n wá bá òun jà. Àmọ́ ẹ̀rù ń ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti bá a jà. Nígbà tí Dáfídì gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó sọ fún Gòláyátì pé: ‘Màá bá ẹ jà! Jèhófà máa ràn mí lọ́wọ́, màá sì ṣẹ́gun rẹ!’ Ǹjẹ́ o rò pé Dáfídì ní ìgboyà?— Bẹ́ẹ̀ ni, ó ní ìgboyà. Ṣé wàá fẹ́ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

Dáfídì mú kànnàkànnà, ìyẹn rọ́bà tó lé lọ́wọ́ àti òkúta márùn ún, ó sì lọ bá òmìrán náà jà. Nígbà tí Gòláyátì rí i pé ọmọdé ni Dáfídì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́! Àmọ́ Dáfídì sọ fún un pé: ‘Ìwọ ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú idà, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà!’ Dáfídì fi òkúta sínú kànnàkànnà tó mú dání, ó sáré lọ bá Gòláyátì ó sì fi kànnàkànnà yẹn ta òkúta náà. Ńṣe ni òkúta náà wọ̀ iwájú orí Gòláyátì lọ tààràtà! Òmìrán náà bá ṣubú lulẹ̀, ó sì kú! Ẹ̀rù ba àwọn Filísínì yòókù, ni gbogbo wọn bá sá lọ. Báwo ni Dáfídì tó jẹ́ ọmọdékùnrin ṣe lè ṣẹ́gun òmìrán yẹn?— Jèhófà ló ràn án lọ́wọ́, àti pé Jèhófà lágbára ju òmìrán yẹn lọ!

Dáfídì kò bẹ̀rù torí ó mọ̀ pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́

Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú ìtàn Dáfídì?— ìtàn yìí kọ́ wa pé, kò sẹ́ni tó lágbára tó Jèhófà. Àti pé Dáfídì jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà. Torí náà, nígbà míì tí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́, rántí pé, Jèhófà lè mú kí o ní ìgboyà!

KÀ Á NÍNÚ BÍBÉLÌ RẸ