Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ 7

Ǹjẹ́ Ẹ̀rù Máa Ń Bà Ẹ́ Tó O Bá Dá Wà?

Ǹjẹ́ Ẹ̀rù Máa Ń Bà Ẹ́ Tó O Bá Dá Wà?

Wo ọmọkùnrin kékeré tó wà nínú àwòrán yìí. Òun nìkan ló dá wà, ẹ̀rù sì ń bà á, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣé ìwọ náà ti dá wà bẹ́ẹ̀ rí?— Bó ṣe máa ń ṣe gbogbo èèyàn nìyẹn nígbà míì. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, tí wọ́n rò pé àwọn dá wà, tí ẹ̀rù sì ń bà wọ́n. Èlíjà jẹ́ ọ̀kan nínú wọn. Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀.

Jésíbẹ́lì fẹ́ pa Èlíjà

Èlíjà ń gbé ní Ísírẹ́lì ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù. Áhábù tó jẹ́ ọba Ísírẹ́lì nígbà yẹn kò jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. Áhábù àti ìyàwó rẹ̀ Jésíbẹ́lì, ń sin òrìṣà tí wọ́n ń pè ní Báálì. Bó ṣe di pé ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Báálì nìyẹn. Jésíbẹ́lì burú gan-an, ó fẹ́ pa gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà, títí kan Èlíjà! Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Èlíjà ṣe?—

Ńṣe ló sá lọ! Ó lọ sọ́nà tó jìn nínú igbó tí kò sí èèyàn tó ń gbé ibẹ̀, ó wá sá pamọ́ sínú ihò kan. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?— Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀rù ló bà á. Àmọ́ kò yẹ kí ẹ̀rù ba Èlíjà. Kí nìdí? Ìdí ni pé, ó mọ̀ pé Jèhófà lè ran òun lọ́wọ́. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Jèhófà ti fi han Èlíjà pé òun ní agbára. Nígbà kan, Jèhófà dáhùn àdúrà Èlíjà, ó rán iná jáde láti ọ̀run. Torí náà, Jèhófà tún lè ran Èlíjà lọ́wọ́ nísìnyí!

Báwo ni Jèhófà ṣe ran Èlíjà lọ́wọ́?

Nígbà tí Èlíjà wà nínú ihò yẹn, Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Kí lò ń ṣe ní ibí yìí?’ Èlíjà dáhùn pé: ‘Èmi nìkan ló kù tí mo ń jọ́sìn rẹ. Èmi nìkan ni mo dá wà, àti pé ẹ̀rù ń bà mí pé wọ́n fẹ́ pa mí.’ Ohun tí Èlíjà rò ni pé gbogbo èèyàn yòókù tó ń jọ́sìn Jèhófà ni wọ́n ti pa. Àmọ́ Jèhófà sọ fún Èlíjà pé: ‘Rárá o, kò rí bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èèyàn ló ṣì wà tó ń jọ́sìn mi. Jẹ́ onígboyà. Mo ṣì ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí mo fẹ́ kó o ṣe!’ Ǹjẹ́ o rò pé inú Èlíjà dùn sí ohun tó gbọ́ yìí?—

Kí lo rí kọ́ lára Èlíjà?— Má ṣe rò pé o dá wà, má sì bẹ̀rù. Torí pé o ní àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ rẹ. Àti pé, Jèhófà lágbára gan-an, ìgbà gbogbo ni yóò máa ràn ẹ́ lọ́wọ́! Ṣé inú rẹ dùn láti mọ̀ pé ìwọ nìkan kọ́ lo dá wà?—