ÀFIKÚN A
Ohun Tá À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn
Jésù sọ pé táwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ bá gbọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́, wọ́n á mọ̀ pé òtítọ́ ni. (Jòh. 10:4, 27) Torí náà, nígbàkigbà tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn, ọ̀nà tó rọrùn ló yẹ ká gbà ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì. Tó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, o lè sọ pé: “Ṣó o mọ̀ pé . . . ?” tàbí “Ṣó o ti gbọ́ ọ rí pé . . . ?” Lẹ́yìn náà kó o lo ẹsẹ Bíbélì tó bá a mu láti ṣàlàyé ohun tó o fẹ́ kọ́ wọn. Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ṣókí látinú Bíbélì lo sọ fún ẹnì kan, o lè ti gbin irúgbìn òtítọ́ sọ́kàn ẹ̀, Jèhófà á sì mú kó dàgbà!—1 Kọ́r. 3:6, 7.
ỌJỌ́ Ọ̀LA
-
1. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé àti ìwà àwọn èèyàn fi hàn pé nǹkan máa tó yí pa dà.—Mát. 24:3, 7, 8; Lúùkù 21:10, 11; 2 Tím. 3:1-5.
-
2. Ayé yìí ò ní pa run láé.—Sm. 104:5; Oníw. 1:4.
-
3. Kò ní sáwọn nǹkan tó ń ba ayé jẹ́ mọ́, ayé máa di Párádísè.—Àìsá. 35:1, 2; Ìfi. 11:18.
-
4. Ara gbogbo èèyàn máa jí pépé.—Àìsá. 33:24; 35:5, 6.
-
5. Àwọn èèyàn á máa gbé ayé títí láé.—Sm. 37:29; Mát. 5:5.
ÌDÍLÉ
-
6. Ó yẹ kí ọkọ “nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.”—Éfé. 5:33; Kól. 3:19.
-
7. Ó yẹ kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ ẹ̀.—Éfé. 5:33; Kól. 3:18.
-
8. Ó yẹ kí tọkọtaya jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn.—Mál. 2:16; Mát. 19:4-6, 9; Héb. 13:4.
-
9. Táwọn ọmọ bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn tí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn, nǹkan á máa lọ dáadáa fún wọn.—Òwe 1:8, 9; Éfé. 6:1-3.
ỌLỌ́RUN
-
10. Ọlọ́run ní orúkọ.—Sm. 83:18; Jer. 10:10.
-
11. Ọlọ́run máa ń bá wa sọ̀rọ̀.—2 Tím. 3:16, 17; 2 Pét. 1:20, 21.
-
12. Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.—Diu. 10:17; Ìṣe 10:34, 35.
-
13. Ọlọ́run múra tán láti ràn wá lọ́wọ́.—Sm. 46:1; 145:18, 19.
ÀDÚRÀ
-
14. Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun.—Sm. 62:8; 65:2; 1 Pét. 5:7.
-
15. Bíbélì kọ́ wa bá a ṣe lè gbàdúrà.—Mát. 6:7-13; Lúùkù 11:1-4.
-
16. Ó yẹ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo.—Mát. 7:7, 8; 1 Tẹs. 5:17.
JÉSÙ
-
17. Olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ gan-an ni Jésù, àwọn ìmọ̀ràn ẹ̀ sì wúlò títí dòní.—Mát. 6:14, 15, 34; 7:12.
-
18. Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tá à ń rí tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí.—Mát. 24:3, 7, 8, 14; Lúùkù 21:10, 11.
-
19. Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù.—Mát. 16:16; Jòh. 3:16; 1 Jòh. 4:15.
-
20. Jésù kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè.—Jòh. 14:28; 1 Kọ́r. 11:3.
ÌJỌBA ỌLỌ́RUN
-
21. Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan tí Ọlọ́run fúnra ẹ̀ gbé kalẹ̀ ní ọ̀run.—Dán. 2:44; 7:13, 14; Mát. 6:9, 10; Ìfi. 11:15.
-
22. Ìjọba Ọlọ́run máa gbàkóso, ó sì máa pa ìjọba èèyàn run.—Sm. 2:7-9; Dán. 2:44.
-
23. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro àwa èèyàn.—Sm. 37:10, 11; 46:9; Àìsá. 65:21-23.
ÌYÀ
-
24. Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá.—Diu. 32:4; Jém. 1:13.
-
25. Sátánì ló ń ṣàkóso ayé yìí.—Lúùkù 4:5, 6; 1 Jòh. 5:19.
-
26. Ọlọ́run mọ̀ pé ìyà ń jẹ àwa èèyàn, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́.—Sm. 34:17-19; Àìsá. 41:10, 13.
-
27. Ọlọ́run máa tó fòpin sí ìyà tó ń jẹ wá.—Àìsá. 65:17; Ìfi. 21:3, 4.
IKÚ
-
28. Àwọn òkú ò mọ nǹkan kan; ìyà ò sì jẹ wọ́n.—Oníw. 9:5; Jòh. 11:11-14.
-
29. Àwọn òkú ò lè ràn wá lọ́wọ́, wọn ò sì lè pa wá lára.—Sm. 146:4; Oníw. 9:6, 10.
-
30. Àwọn èèyàn wa tó ti kú máa jí dìde.—Jóòbù 14:13-15; Jòh. 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
-
31. “Ikú ò ní sí mọ́.”—Ìfi. 21:3, 4; Àìsá. 25:8.
Ẹ̀SÌN
-
32. Kì í ṣe gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà.—Jer. 7:11; Mát. 7:13, 14, 21-23.
-
33. Ọlọ́run kórìíra àgàbàgebè.—Àìsá. 29:13; Míkà 3:11; Máàkù 7:6-8.
-
34. Àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn látọkàn.—Míkà 4:3; Jòh. 13:34, 35.