SỌ WỌ́N DỌMỌ Ẹ̀YÌN
Ẹ̀KỌ́ 11
Kọ́ni Lọ́nà Tó Rọrùn
Ìlànà: “Sọ ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti lóye.” —1 Kọ́r. 14:9.
Ohun Tí Jésù Ṣe
1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Mátíù 6:25-27. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
2. Tá a bá kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tó rọrùn, wọ́n á rántí ohun tá a kọ́ wọn, á sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
3. Má sọ̀rọ̀ jù. Dípò tí wàá fi sọ gbogbo ohun tó o mọ̀ nípa ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́, ohun tó wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́ ẹ̀ ń lò ni kó o fi àlàyé ẹ mọ sí. Tó o bá béèrè ìbéèrè kan, ní sùúrù kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ dáhùn. Tí kò bá mọ ìdáhùn tàbí tí ìdáhùn ẹ̀ ò bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu, o lè bi í láwọn ìbéèrè míì tó máa jẹ́ kó ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà. Tí kókó pàtàkì inú ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ bá ti yé e, ńṣe ni kẹ́ ẹ lọ sí kókó tó kàn.
4. So ohun tẹ́ ẹ ti kọ́ tẹ́lẹ̀ mọ́ èyí tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ kọ́. Bí àpẹẹrẹ, kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa àjíǹde, o lè sọ̀rọ̀ ṣókí nípa ohun tẹ́ ẹ ti kọ́ tẹ́lẹ̀ pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan.
5. Ronú jinlẹ̀ kó o tó lo àpèjúwe. Kó o tó lo àpèjúwe, bi ara ẹ pé:
-
d. ‘Ṣó máa jẹ́ kí ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ rántí kókó pàtàkì inú ohun tá à ń kọ́ àbí àpèjúwe yẹn nìkan láá kàn máa rántí?’