SỌ WỌ́N DỌMỌ Ẹ̀YÌN
Ẹ̀KỌ́ 12
Má Bẹ̀rù Láti Sọ Òótọ́ Ọ̀rọ̀
Ìlànà: “Òróró àti tùràrí máa ń mú ọkàn yọ̀; bẹ́ẹ̀ ni adùn ọ̀rẹ́ máa ń wá látinú ìmọ̀ràn àtọkànwá.”—Òwe 27:9.
Ohun Tí Jésù Ṣe
1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Máàkù 10:17-22. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
2. Ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ó tún yẹ ká máa bá wọn sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ tó máa jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
3. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ mọ ohun tó yẹ kó ṣe àti bó ṣe máa ṣe é.
-
a. Ẹ máa jíròrò apá tá a pè ní “Ohun tó yẹ kó o ṣe” ní ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!
-
b. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ mọ àwọn nǹkan pàtó tó yẹ kó ṣe, kọ́wọ́ ẹ̀ lè tẹ àwọn àfojúsùn ẹ̀ ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.
4. Mọ àwọn ohun tí kò jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ tẹ̀ síwájú, kó o sì ràn án lọ́wọ́ kó lè borí wọn.
-
-
‘Kí ló ń dí ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ tí kò fi gbé ìgbésẹ̀ láti ṣèrìbọmi?’
-
‘Kí ni mo lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́?’
-
-
Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fìfẹ́ tọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ẹ sọ́nà, kó o má sì bẹ̀rù láti bá a sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.
5. Tẹ́nì kan ò bá fẹ́ tẹ̀ síwájú, fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀.
-
Kó o lè mọ̀ bóyá ó yẹ kó o fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, bi ara ẹ pé:
-
‘Ṣé ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń fi ohun tó ń kọ́ sílò?’
-
‘Ṣó máa ń wá sípàdé, ṣó sì máa ń sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì?’
-
‘Lẹ́yìn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì débì kan, ṣó wù ú láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?’
-
-
Tí kò bá wu ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì tó máa jẹ́ kó tẹ̀ síwájú:
-
Ní kó ronú lórí ohun tí kò jẹ́ kó tẹ̀ síwájú.
-
Fìfẹ́ ṣàlàyé ìdí tó o fi fẹ́ fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.
-
Jẹ́ kó mọ àwọn ohun tó yẹ kó ṣe, kó tó lè pa dà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀.
-