BÁ A ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ WA
Ẹ̀KỌ́ 2
Máa Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ẹ Wẹ́rẹ́
Ìlànà: “Ọ̀rọ̀ tó bá . . . bọ́ sí àkókò mà dára o!”—Òwe 15:23.
Ohun Tí Fílípì Ṣe
1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Ìṣe 8:30, 31. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí La Rí Kọ́ Lára Fílípì?
2. Tó o bá ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ wẹ́rẹ́, ó ṣeé ṣe kí èyí mú kára tu àwọn èèyàn, kó wù wọ́n láti gbọ́rọ̀ ẹ, kí wọ́n sì bá ẹ sọ̀rọ̀.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Fílípì
3. Máa lákìíyèsí. Tó o bá ń kíyè sí bí ojú ẹnì kan ṣe rí àti ìṣesí ẹ̀, ó lè jẹ́ kó o mọ nǹkan tó pọ̀ nípa ẹni náà. Bí àpẹẹrẹ, wàá mọ̀ bóyá ó wu ẹni náà láti bá ẹ sọ̀rọ̀. Tó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò látinú Bíbélì, o lè béèrè pé, “Ṣó o tiẹ̀ mọ̀ pé . . . ?” Tó o bá kíyè sí pé kò wu ẹnì kan láti bá ẹ sọ̀rọ̀, má bá a sọ̀rọ̀ tipátipá.
4. Máa ní sùúrù. Má ṣe rò pé dandan ni kó o sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Dúró dìgbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, kí ọ̀rọ̀ náà lè wọlé wẹ́rẹ́. Nígbà míì, ó lè gba pé kó o ní sùúrù dìgbà míì tó o tún máa bá ẹni náà sọ̀rọ̀.
5. Múra láti yí ọ̀rọ̀ ẹ pa dà. Ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lè sọ ohun kan tó ò retí. Torí náà, múra láti sọ ohun kan látinú Bíbélì tó máa ṣe ẹni náà láǹfààní, tó bá tiẹ̀ gba pé kó o sọ ohun tó yàtọ̀ sí èyí tó o ti ní lọ́kàn.