Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
Ẹ̀yin Ará Wa Ọ̀wọ́n:
A nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn, ìdí nìyẹn tá a fi ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé: “Ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:19, 20; Máàkù 12:28-31) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn látọkàn wá, ó máa jẹ́ ká lè sọ̀rọ̀ tó máa wọ àwọn “olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” lọ́kàn.—Ìṣe 13:48.
Láwọn ìgbà kan, ọ̀rọ̀ tá a ti há sórí la máa ń sọ fáwọn èèyàn lóde ìwàásù, lẹ́yìn náà àá wá fún wọn ní ìwé. Àmọ́ ní báyìí, ó yẹ ká mú kí ọ̀nà tá à ń gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ dáa sí i. Ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ni pé ká bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. Èyí gba pé ká fara balẹ̀ kíyè sí ohun tó jẹ́ ìṣòro ẹnì kan àtohun tó nífẹ̀ẹ́ sí, ká sì múra tán láti yí ọ̀rọ̀ wa pa dà ká lè sọ ohun tó máa ṣe é láǹfààní. Báwo ni ìwé yìí ṣe máa ràn wá lọ́wọ́?
Ẹ̀kọ́ méjìlá (12) ló wà nínú ìwé yìí, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ tó yẹ ká ní ká lè fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, ká sì sọ wọ́n dọmọ ẹ̀yìn. Ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan dá lórí ìtàn kan nínú Bíbélì, nípa bí Jésù tàbí ọ̀kan lára àwọn ajíhìnrere ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe lo ànímọ́ pàtó kan lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A ò fẹ́ máa há ọ̀rọ̀ sórí mọ́ tá à ń bá ń wàásù fáwọn èèyàn, ńṣe la fẹ́ máa ṣe ohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi ànímọ́ la nílò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a máa rí àwọn ànímọ́ tá a nílò jù lọ tá a bá ń wàásù nígbà àkọ́kọ́, nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Bẹ́ ẹ ṣe ń ka ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan, ẹ máa fara balẹ̀ ronú nípa bẹ́ ẹ ṣe lè lo ànímọ́ tó wà níbẹ̀ tẹ́ ẹ bá ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn ládùúgbò yín. Máa ṣohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn. Òótọ́ ni pé a lè mọ oríṣiríṣi ọ̀nà tá a lè gbà wàásù fáwọn èèyàn, àmọ́ ó dìgbà tá a bá nífẹ̀ẹ́ wọn látọkàn wá, ká tó lè sọ wọ́n dọmọ ẹ̀yìn.
Inú wa dùn gan-an pé a láǹfààní láti jọ máa ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan. (Sef. 3:9) Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà bù kún yín lọ́pọ̀lọpọ̀ bẹ́ ẹ ṣe ń fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, tẹ́ ẹ sì ń sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn!
Àwa arákùnrin yín,
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà