Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú
Ẹnìkan tí ìwọ fẹ́ràn ha ti sùn nínú ikú bí?
Ìwọ ha ṣì ń kẹ́dùn bí?
Ìwọ ha ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ nínú kíkojú ẹ̀dùn-ọkàn rẹ bí?
Ìrètí ha wà fún àwọn òkú bí?
Bí ó bá wà, kí ni ó jẹ́?
Báwo ni ó ṣe lè dá wa lójú?
Nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí, irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ yóò rí ìdáhùn tí ń tuninínú láti inú Bibeli. A rọ̀ ọ́ láti kà á dáradára.