ÌBÉÈRÈ 5
Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Mi Níléèwé?
KÍ LO MÁA ṢE?
Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Thomas ò fẹ́ lọ sí ilé ìwé lónìí. Ó lè má lọ lọ́la pàápàá. Kò tiẹ̀ fẹ́ lọ mọ́. Ní oṣù mẹ́ta sẹ́yìn, àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í rojọ́ ẹ̀ kiri. Wọ́n tún ń pè é lórúkọ burúkú. Nígbà míì, ẹnì kan lè fọwọ́ gbá ìwé Thomas dà nù lọ́wọ́ ẹ̀, á wá ṣe bíi pé òun ò mọ̀ọ́mọ̀ tàbí kí ẹnì kan láàárín èrò ṣàdédé fọwọ́ tì í látẹ̀yìn, kó sì tó wẹ̀yìn, onítọ̀hún á ti ṣojú fúrú. Lánàá, ohun míì tún ṣẹlẹ̀ tó mú kí ọ̀rọ̀ ọ̀hún tún burú sí i. Ṣe làwọn kan halẹ̀ mọ́ Thomas látorí íńtánẹ́ẹ̀tì . . .
Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Thomas, kí lo máa ṣe?
RÒ Ó WÒ NÁ!
Má rò pé kò sóhun tó o lè ṣe! Ṣó o fẹ́ gbọ́, o lè borí ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ẹ láìbá a jà. Báwo lo ṣe lè ṣe é?
-
Òwe 29:11) Tó ò bá fún wọn lésì, tó ò sì jẹ́ kí wọn rí i lójú ẹ pé ó dùn ẹ́, àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ ẹ lè fi ẹ́ sílẹ̀.
MÁA WÒ Ó NÍRAN. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.” ( -
MÁ GBẸ̀SAN. Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” (Róòmù 12:17) Tó o bá gbẹ̀san, ṣe lo máa dá kún ọ̀ràn náà.
-
SÁ FÚN OHUN TÓ LÈ KÓ Ẹ SÍ WÀHÁLÀ. Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Máa yẹra fún àwọn tó lè dá wàhálà sílẹ̀ débi tó o bá lè ṣe é dé, má sì lọ síbi tí wọ́n ti lè halẹ̀ mọ́ ẹ.
-
SỌ OHUN TÍ WỌN Ò RETÍ. Bíbélì sọ pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.” (Òwe 15:1) O tiẹ̀ lè dàá sí àwàdà. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan bá ń bú ẹ pé o ti sanra jù, o lè fakọ sí i, kó o sọ pé, “Tí mo bá tiẹ̀ lè jò díẹ̀ sí i, màá yọ̀!”
-
KÚRÒ NÍBẸ̀. Nora, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], sọ pé: “Tó o bá dákẹ́, tó ò fún ẹni tó ń halẹ̀ mó ẹ lésì, ńṣe ló fi hàn pé o níwà àgbà, o sì lágbára ju ẹni yẹn lọ. Ó tún fi hàn pé o lè kó ara ẹ níjàánu, ohun tẹ́ni tó ń halẹ̀ mọ́ ẹ ò lè ṣe.”—2 Tímótì 2:24.
-
MÁ ṢE JẸ́ KÍ Ẹ̀RÙ MÁA BÀ Ẹ́. Àwọn tó máa ń halẹ̀ mọ́ni máa ń mọ̀ tẹ́rù bá ń ba ẹnì kan, tí kò sì ní lè gbèjà ara ẹ̀. Àmọ́, tí wọ́n bá ti rí i pé àwọn ò lágbára lórí ẹ, wọ́n á fi ẹ́ sílẹ̀.
-
WÁ ẸNÌ KAN SỌ FÚN. Ẹnì kan tó ti ṣiṣẹ́ olùkọ́ rí sọ pé: “Tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ ẹ, má bò ó mọ́ra, ṣe ni kó o sọ̀rọ̀ síta. Ohun tó yẹ kó o ṣe nìyẹn, ìyẹn á jẹ́ ká wá nǹkan ṣe sí i, wọn ò sì ní tún lè halẹ̀ mọ́ ẹlòmíì.”