Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 8

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìfipá-Báni-Lòpọ̀?

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìfipá-Báni-Lòpọ̀?

ÌDÍ TỌ́RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni wọ́n máa ń fipá bá lò pọ̀ tàbí fipá bá ṣèṣekúṣe, àwọn ọ̀dọ́ sì làwọn èèyànkéèyàn yìí ń dọdẹ.

LO MÁA ṢE?

Kí Annette tiẹ̀ tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ rárá, ẹni tó fẹ́ fipá bá a lò pọ̀ ti fẹ̀yìn ẹ balẹ̀. Annette sọ pé: “Mó ta gbogbo ọgbọ́n tí mo lè ta kí n lè bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Mo gbìyànjú láti pariwo, àmọ́ ohùn mi ò jáde. Mo tì í, mo ta á nípàá, mo fún un lẹ́ṣẹ̀ẹ́, mo sì ya á léèékánná. Ó wá fọ̀bẹ ya mí lára. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣe ló rẹ̀ mí wọ̀ọ̀.”

Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, kí lo máa ṣe?

RÒ Ó WÒ NÁ!

Tó o bá tiẹ̀ ń múra sílẹ̀, bóyá tó ò ń ṣọ́ra lójú méjèèjì tó o bá ń jáde lálẹ́, nǹkan burúkú ṣì lè ṣẹlẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára, bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti àwọn tí ó ní ìmọ̀ pàápàá, nítorí pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”​—Oníwàásù 9:⁠11.

Bó ṣe ṣẹlẹ̀ sí Annette, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló jẹ́ pé èèyàn tí wọn ò mọ̀ rí ló fipá bá wọn ṣèṣekúṣe. Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé èèyàn wọn kan tàbí mọ̀lẹ́bí wọn pàápàá ló fipá bá wọn ṣèṣekúṣe. Ọmọ ọdún mẹ́wàá péré ṣì ni Natalie nígbà tọ́mọkùnrin kan tí ò tíì pọ́mọ ogún ọdún fipá bá a lò pọ̀. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, wọ́n jọ ń gbé ládùúgbò ni o. Natalie sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí, ojú sì tì mí gan-an débi pé mi ò lè sọ fún ẹnikẹ́ni nígbà tó ṣẹlẹ̀.”

KÌ Í ṢE Ẹ̀BI Ẹ

Ọkàn Annette ṣì máa ń dá a lẹ́bi nígbàkigbà tó bá rántí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò jà fitafita tó láti gba ara mi lọ́wọ́ àwé yẹn. Ohun tó sì fà á ni pé, gbàrà tó ti gún mi lọ́bẹ lẹ̀rù ti ń bà mí. Kò sì sóhun tí mo tún lè ṣe mọ́, àmọ́ mo máa ń rò ó pé ó ṣì yẹ kí n ṣe nǹkan kan.”

Ọkàn Natalie tún máa ń dá a lẹ́bi. Ó sọ pé: “Mo ti máa ń fọkàn tán àwọn èèyàn jù. Àwọn òbí mi ti sọ fún èmi àti àbúrò mi pé ṣe ni ká jọ máa wà pa pọ̀ tá a bá ń ṣeré níta, àmọ́ mi ò gbọ́. Mo gbà pé èmi ni mo jẹ́ kí aládùúgbò wa yìí rí mi mú. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ká ìdílé wa lára, mo sì gbà pé èmi ni mo fa ẹ̀dùn ọkàn tó bá wọn. Ohun tó sì máa ń dùn mí jù nìyẹn ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀.”

Tóhun tó ṣẹlẹ̀ sí Annette àti Natalie bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, tọ́kàn ẹ sì ń dá ẹ lẹ́bi, fi sọ́kàn pé kò wu ẹni tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ láti ṣèṣekúṣe. Àwọn kan máa ń fojú kéré ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n á ní ìran ọkùnrin ló ń ṣe irú ẹ̀, pé àwọn tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ ló fà á tí wọ́n fi fipá bá wọn lò pọ̀. Àmọ́, kò sẹ́nì tó tọ́ sí kí wọ́n fipá bá lò pọ̀. Bí wọ́n bá ti hùwà ìkà yìí sí ẹ rí, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé kì í ṣẹ̀bi ẹ rárá!

Lóòótọ́, ó rọrùn láti ka ohun tá a sọ yìí pé “kì í ṣẹ̀bi ẹ rárá,” àmọ́ ó lè má rọrùn fún ẹ láti gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Ṣe làwọn kan máa ń bo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn mọ́ra, tí ọkàn wọn á wá máa dá wọn lẹ́bi, ọ̀rọ̀ yẹn á sì máa bà wọ́n nínú jẹ́. Àmọ́, tó o bá dákẹ́, tó ò sọ̀rọ̀, tá ni ọ̀rọ̀ náà máa dùn, ìwọ àbí ẹni tó fipá bá ẹ lò pọ̀? Dípò tí wàá kàn fi dákẹ́, ohun míì wà tó o lè ṣe táá jẹ́ kọ́rọ̀ ọ̀hún fúyẹ́ lọ́kàn ẹ.

WÁ ẸNI SỌ̀RỌ̀ NÁÀ FÚN

Bíbélì sọ nípa Jóòbù ọkùnrin olódodo náà pé, nígbà tí ìṣòro tó dé bá a dójú ẹ̀ tán, ó sọ pé: “Èmi yóò sọ̀rọ̀ nínú ìkorò ọkàn mi!” (Jóòbù 10:⁠1) Ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tíwọ náà bá ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá lè sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ fún ẹnì kan tó o fọkàn tán, wàá rí i pé bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ọ̀rọ̀ náà á fúyẹ́ lọ́kàn ẹ, ara á sì tù ẹ́.

Ọ̀rọ̀ ọ̀hún lè wúwo lọ́kàn rẹ débi tágbára ẹ ò fi ní ká a mọ́. O ò ṣe wẹ́ni sọ fún kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

Ohun tó pa dà wá ṣẹlẹ̀ sí Annette nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo sọ ọ̀rọ̀ náà fún ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kan, ó sì gbà mí níyànjú pé kí n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn alàgbà kan nínú ìjọ wa. Inú mi dùn gan-an pé mo ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n pè mí jókòó tí wọ́n sì sọ àwọn ohun tó tù mí nínú, pé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà kì í ṣe ẹ̀bi mi. Wọ́n ní mi ò jẹ̀bi lọ́nàkọnà.”

Natalie sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i fáwọn òbí ẹ̀. Ó sọ pé: “Wọ́n ràn mí lọ́wọ́, wọ́n fún mi níṣìírí pé kí n sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí, ìyẹn ló jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà fúyẹ́ lọ́kàn mi, tí ìbínú mi sì rọ̀.”

Àdúrà tún ran Natalie lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ràn mí lọ́wọ́ gan-an, pàápàá láwọn ìgbà tí mi ò lè sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ẹnikẹ́ni. Tí mo bá ń gbàdúrà, mo máa ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi gan-an. Èyí máa ń jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀, ó sì máa ń mára tù mí.”

Ìwọ náà á rí i pé “ìgbà mímúláradá” wà lóòótọ́. (Oníwàásù 3:3) Torí náà, máa tọ́jú ara rẹ dáadáa, kó o sì rí i pé ò ń ṣe ohun táá máa múnú rẹ dùn. Máa sùn dáadáa. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.​—2 Kọ́ríńtì 1:​3, 4.

TÓ O BÁ TI DÀGBÀ TẸ́NI TÓ Ń NÍ ÀFẸ́SỌ́NÀ

Tó bá jẹ́ pé obìnrin ni ẹ́, tẹ́nì kan sì ń yọ ẹ́ lẹ́nu pé kẹ́ ẹ jọ ṣèṣekúṣe, kò sóhun tó burú nínú kó o pariwo mọ́ ẹni náà pé, “Má dán an wò!” tàbí kó o sọ pé, “Gbọ́wọ́ ẹ kúrò lára mi!” Má bẹ̀rù pé ẹni tó ò ń fẹ́ yẹn lè bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́ kó o wá torí ìyẹn gbà fún un. Tó bá lóun ò fẹ́ ẹ mọ́ torí pé o ò gbà fún òun, a jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tó yẹ́ kó o fẹ́ nìyẹn! Ó ṣe tán, ọkùnrin tó jẹ́ èèyàn dáadáa lo máa fẹ́ fẹ́, ìyẹn ẹni tó máa fọ̀wọ̀ ẹ wọ̀ ẹ́, táá sì fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà ìwà rere tó ò ń tẹ̀ lé.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ ÌFIPÁ-BÁNI-TAGE

“Nígbà tí mo ṣì wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama, àwọn ọmọkùnrin máa ń wá fa bùrèsíà mi látẹ̀yìn, wọ́n á wá máa sọ̀rọ̀ rírùn sí mi létí, bíi kí wọ́n máa sọ pé màá gbádùn ẹ̀ gan-an tí n bá gbà káwọn bá mi sùn.”​—Coretta.

Ṣó o rò pé ṣe làwọn ọmọkùnrin yẹn ń

  1. Mú un ṣeré?

  2. Bá a tage?

  3. Fi ọ̀ranyàn bá a tage?

“A wà nínú bọ́ọ̀sì lọ́jọ́ kan, lọmọkùnrin kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi sọ ìsọkúsọ, ó sì ń fọwọ́ pa mí lára. Mo bá gbá ọwọ́ ẹ̀ dà nù, mo sì ní kó kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Ó yà á lẹ́nu pé mo lè ṣe irú ẹ̀.”​—Candice.

Kí lo rò pé ọmọkùnrin yìí ń ṣe sí Candice, ṣó ń

  1. Mú un ṣeré?

  2. Bá a tage?

  3. Fi ọ̀ranyàn bá a tage?

“Lọ́dún tó kọjá, ọmọkùnrin kan ṣáà ń dà mí láàmú pé òun fẹ́ràn mí, òun sí fẹ́ ká máa fẹ́ra, mò sì ti sọ fún un láìmọye ìgbà pé mi ò lè fẹ́ ẹ, síbẹ̀ kò fi mí lọ́rùn sílẹ̀. Ó tiẹ̀ máa ń fọwọ́ pa mí léjìká nígbà míì. Tí mo bá sì sọ fún un pé kó yéé ṣe bẹ́ẹ̀, kì í dá mi lóhùn. Lọ́jọ́ kan, mo bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, mò ń so okùn bàtà mi, ló bá gbá mi nídìí.”​—Bethany.

Kí lo rò pé ọmọkùnrin yẹn ń ṣe, ṣó ń

  1. Mú un ṣeré?

  2. Bá a tage?

  3. Fi ọ̀ranyàn bá a tage?

C ni ìdáhùn tó tọ̀nà sí ìbéèrè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí.

Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú fífi ọ̀ranyàn báni tage àti kí wọ́n kàn máa báni tage tàbí múni ṣeré?

Bí ẹni tó ń báni tage lọ́ranyàn ṣe máa tẹ́ ìfẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn ló ń wá. Bí onítọ̀hún bá tiẹ̀ ní kó má ṣe bẹ́ẹ̀ sóun mọ́, kò ní gbọ́.

Fífipá-báni-tage léwu gan-an, ó sì lè yọrí sí ìfipá-báni-lòpọ̀.