Ìparí
“Ẹ jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.”—HÉBÉRÙ 6:12.
1, 2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ní báyìí pé ká ní ìgbàgbọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.
ÌGBÀGBỌ́. Ọ̀rọ̀ yìí dára, orúkọ ànímọ́ kan tó fani mọ́ra gan-an sì ni. Àmọ́, nígbà tá a bá rí ọ̀rọ̀ yìí, ó dára ká tún rántí ọ̀rọ̀ míì, ìyẹn ni: “Kánjúkánjú!” Ó ṣe tán, bí a kò bá ní ìgbàgbọ́, ó ti di kánjúkánjú pé ká ní in. Tá a bá sì ní ìgbàgbọ́, ó ti di kánjúkánjú pé ká máa pa á mọ́, ká sì jẹ́ kó túbọ̀ máa lágbára. Kí nìdí?
2 Jẹ́ ká sọ pé ò ń rìn gba àárín aṣálẹ̀ kan tó lọ salalu kọjá. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé o nílò omi lójú méjèèjì. Tó o bá jàjà rí omi díẹ̀, o ò ní gbé e síbi tí oòrùn wà, kó má bàa gbẹ. Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o máa pọn kún omi náà kó má bàa tán títí tí wàá fi dé ibi tí ò ń lọ. Ńṣe ni ayé tá à ń gbé yìí dà bí aṣálẹ̀ tẹ̀mí. Bí omi ṣe máa ń ṣọ̀wọ́n nínú aṣálẹ̀ ni ojúlówó ìgbàgbọ́ ṣe ṣọ̀wọ́n nínú ayé yìí. Tá ò bá sì dáàbò bo ojúlówó ìgbàgbọ́ yìí ká sì túbọ̀ máa fún un lágbára, ó lè yara gbẹ dà nù bí omi. Kò yẹ ká fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ rárá, torí pé bí ẹni tí kò bá rí omi mu ò ṣe ní pẹ́ kó tó kú, bẹ́ẹ̀ náà la ò ṣe lè wà láàyè nípa tẹ̀mí tá ò bá ní ìgbàgbọ́.—Róòmù 1:17.
3. Kí ni Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ torí ká lè ní ìgbàgbọ́? Ohun méjì wo ló sì yẹ ká máa rántí?
3 Jèhófà mọ̀ pé ó jẹ́ kánjúkánjú fún wa láti ní ìgbàgbọ́, ó sì tún mọ bó ṣe nira tó lóde òní láti ní ìgbàgbọ́ ká sì jẹ́ kó máa lágbára sí i. Ó dájú pé ohun tó fà á nìyẹn tó fi jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn èèyàn tá a lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Jèhófà mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.” (Heb. 6:12) Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí ètò Jèhófà fi gbà wá níyànjú pé ká sa gbogbo ipá wa ká lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ní ìgbàgbọ́, bí àwọn tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn nínú ìwé yìí. Kí ló wá yẹ ká ṣe báyìí? A gbọ́dọ̀ máa rántí àwọn ohun méjì: (1) Ó pọn dandan pé ká máa mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára; (2) a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìrètí tá a ní dá wa lójú hán-únhán-ún.
4. Kí ni Sátánì ṣe tó fi hàn pé ó jẹ́ ọ̀tá ìgbàgbọ́, síbẹ̀ kí nìdí tí kò fi yẹ ká sọ̀rètí nù?
4 Mú kí ìgbàgbọ́ rẹ máa lágbára. Ìgbàgbọ́ ní ọ̀tá ńlá kan, Sátánì sì ni ọ̀tá náà. Sátánì ni alákòóso ayé, ó sì ti sọ ètò àwọn nǹkan yìí di aṣálẹ̀ tẹ̀mí tí kò ti rọrùn láti ní ìgbàgbọ́. Ó lágbára jù wá lọ fíìfíì. Ṣó wá yẹ ká torí èyí sọ̀rètí nù, ká máa rò pé a ò lè ní ìgbàgbọ́ tàbí pé a kò lè mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i? Rárá o! Ọ̀rẹ́ tó ju ọ̀rẹ́ lọ ni Jèhófà jẹ́ fún gbogbo àwọn tó ń wá bí wọ́n ṣe máa ní ojúlówó ìgbàgbọ́. Ó mú kó dá wa lójú pé níwọ̀n ìgbà tí òun bá ń tì wá lẹ́yìn, a lè dojú ìjà kọ Èṣù ká sì lé e jìnnà sí wa. (Ják. 4:7) Bá a ṣe lè dojú ìjà kọ Èṣù ni pé ká máa wá àyè lójoojúmọ́ láti mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, ká sì mú kó máa pọ̀ sí i. Lọ́nà wo?
5. Báwo ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin adúróṣinṣin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn ṣe ní ìgbàgbọ́? Ṣàlàyé bí àwa náà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.
Gál. 5:22, 23) Wọ́n gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún àwọn ní ìgbàgbọ́. Jèhófà dáhùn àdúrà wọn, ó sì mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Ẹ jẹ́ kí àwa náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, ká má sì ṣe gbàgbé láé pé tá a bá ń gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tá a sì ń ṣe ohun tó bá àdúrà wa mu, ó máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ní fàlàlà. (Lúùkù 11:13) Ǹjẹ́ nǹkan míì wà tá a tún lè ṣe?
5 A ti rí i pé wọn ò bí ìgbàgbọ́ mọ́ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tá a kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn nínú Bíbélì pé wọ́n ní ìgbàgbọ́. Àwọn ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n wà láyé fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ló máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìgbàgbọ́. (6. Ká bàa lè jàǹfààní tó pọ̀ jù lọ látinú àwọn ìtàn inú Bíbélì, báwo ló ṣe yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ wọn?
6 Nínú ìwé yìí, a ti jíròrò díẹ̀ lára àwọn tó lo ìgbàgbọ́ lọ́nà tó ta yọ. Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ló ṣì wà. (Ka Hébérù 11:32.) Tá a bá ń kún fún àdúrà, tó sì ń ti ọkàn wa wá láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn, ọ̀pọ̀ nǹkan la ṣì máa mọ̀. Tó bá jẹ́ pé ńṣe là ń kánjú ka ohun tí Bíbélì sọ, ohun tá a kà náà kò ní lè fún ìgbàgbọ́ wa lágbára. Kí ohun tá a bá kà tó lè ṣe wá láǹfààní dáadáa, a gbọ́dọ̀ wá àkókò láti ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀ nípa bí nǹkan ṣe rí ní àsìkò tí ìtàn náà ṣẹlẹ̀ àti àwọn ohun mìíràn tó tan mọ́ ọn. Tá a bá ń fi sọ́kàn ní gbogbo ìgbà pé èèyàn tó ní “ìmọ̀lára bí tiwa” ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin yìí, a óò túbọ̀ rí i pé a lè jàǹfààní nínú àpẹẹrẹ wọn. (Ják 5:17) Bá a ṣe ń fi ọ̀rọ̀ wọn ro ara wa wò, a lè wá fòye mọ bó ṣe rí lára wọn nígbà tí wọ́n dojú kọ irú àwọn ìṣòro àti ipò tí kò bára dé tí àwa náà ń dojú kọ lónìí.
7-9. (a) Báwo ni ì bá ṣe rí lára àwọn kan tí Bíbélì sọ pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ ká ní wọ́n láǹfààní láti jọ́sìn Jèhófà bá a ti ń ṣe lónìí? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára nípa ṣíṣe àwọn ohun tó fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́?
7 Ọ̀nà míì tá a lè gbà mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára ni pé ká máa ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́. Ó ṣe tán, “ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Ják. 2:26) Ká ní irú iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́ lóde òní ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn yìí láǹfààní láti ṣe, ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí inú wọn á ṣe dùn tó?
8 Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù jọ́sìn Jèhófà nídìí àwọn pẹpẹ tó fi òkúta ṣe nínú aginjù. Ká ní Ọlọ́run ní kó wá sin òun láàárín àwọn olùjọsìn tó wà létòlétò nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó fani mọ́ra àti ní àwọn àpéjọ ńláńlá ńkọ́? Ká ní ó láǹfààní láti gbọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé tó wúni lórí nípa àwọn ìlérí tó rí “lókèèrè réré” nínú àwọn ìpàdé yìí ńkọ́, báwo ni ì bá ṣe rí lára rẹ̀? (Ka Hébérù 11:13.) Tún wo tí Èlíjà tó jẹ́ pé àsìkò tí ọba búburú tó jẹ́ apẹ̀yìndà ń ṣàkóso ló sin Jèhófà. Ká ní dípò tí Ọlọ́run fi sọ fún un pé kó pa àwọn wòlíì búburú tó ń jọ́sìn Báálì, ńṣe ló ní kó máa mú ìhìn rere àlàáfíà tọ àwọn èèyàn lọ kí wọ́n lè rí ìtùnú àti ìrètí ńkọ́? Ìdí wà láti gbà pé àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Bíbélì sọ pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ yìí máa kà á sí àǹfààní ńlá láti jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tá à ń gbà jọ́sìn rẹ̀ lóde òní.
9 Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára nípa ṣíṣe àwọn ohun tó fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, a ó lè máa fi ohun tá a rí kọ́ lára àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ sílò lọ́nà tó gbéṣẹ́. A ó sì lè túbọ̀ máa wò wọ́n bí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́, gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú. Àmọ́ ṣá o, a lè di ọ̀rẹ́ wọn láìpẹ́.
10. Kí ló máa fún wa láyọ̀ nínú Párádísè?
10 Jẹ́ kí ìrètí tó o ní dá ẹ lójú hán-únhán-ún. Ìrètí tí àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó lo ìgbàgbọ́ ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run ló máa ń fún wọn lókun. Ṣé ìwọ náà ní irú ìrètí yẹn? Bí àpẹẹrẹ, fojú inú wo bó o ṣe máa láyọ̀ tó láti rí àwọn adúróṣinṣin tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá pa dà wà láàyè nígbà “àjíǹde àwọn olódodo.” (Ka Ìṣe 24:15.) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí wàá fẹ́ bi wọ́n?
11, 12. Nínú ayé tuntun, àwọn ìbéèrè wo lo máa fẹ́ láti béèrè lọ́wọ́ (a) Ébẹ́lì? (b) Nóà? (d) Ábúráhámù? (e) Rúùtù? (ẹ) Ábígẹ́lì? (f) Ẹ́sítérì?
11 Tó o bá ní àǹfààní láti bá Ébẹ́lì sọ̀rọ̀, ṣé wàá fẹ́ kó sọ bí àwọn òbí rẹ̀ ṣe rí fún ẹ? O sì lè bi í pé: “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ bá àwọn kérúbù tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ọgbà Édẹ́nì sọ̀rọ̀ rárá? Ṣé wọ́n dá ẹ lóhùn?” Tó bá jẹ́ Nóà ńkọ́? O lè bi í pé: “Ǹjẹ́ ẹ̀rù àwọn Néfílímù yẹn tiẹ̀ bà ẹ́ rí? Báwo lo ṣe tọ́jú gbogbo àwọn ẹranko yẹn ní gbogbo àkókò tẹ́ ẹ fi wà nínú áàkì?” Tó bá sì jẹ́ Ábúráhámù lo bá pàdé, o lè bi í pé: “Ǹjẹ́ ìwọ àti Ṣémù tilẹ̀ fojú kanra? Ta ló kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà? Ǹjẹ́ ó nira fún ẹ láti fi ìlú Úrì sílẹ̀?”
12 Bákan náà, ronú nípa àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó o fẹ́ láti béèrè lọ́wọ́ àwọn obìnrin tó fi ìgbàgbọ́ sin Jèhófà nígbà tí wọ́n bá jí dìde. “Rúùtù, kí ló mú kó o di olùjọsìn Jèhófà?” “Ábígẹ́lì, ṣé ẹ̀rù bà ẹ́ láti sọ fún Nábálì pé o ran Dáfídì lọ́wọ́?” “Ẹ́sítérì, kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìwọ àti Módékáì lẹ́yìn ibi tí Bíbélì sọ ìtàn yín dé?”
13. (a) Àwọn ìbéèrè wo ló ṣeé ṣe kí àwọn tó bá jíǹde béèrè lọ́wọ́ rẹ? (b) Bó o ṣe ń fi ojú sọ́nà láti rí àwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbà àtijọ́ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, kí lò ń fẹ́ láti máa ṣe nísinsìnyí?
13 Àmọ́ ṣá, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó lo ìgbàgbọ́ yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè tí wọ́n máa fẹ́ bi àwa náà o! Tayọ̀tayọ̀ la máa fi ròyìn àwọn ohun tójú rí ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó ṣáájú òpin ètò Sátánì yìí fún wọn àti bí Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láwọn ìgbà tí nǹkan nira. Ó dájú pé inú wọn máa dùn gan-an nígbà tí wọ́n bá kẹ́kọ̀ọ́ bí Jèhófà ṣe mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nígbà yẹn, a kò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fojú inú wo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tá a kà nípa wọn nínú Bíbélì pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Ìdí ni pé àwọn fúnra wọn máa wà pẹ̀lú wa nínú Párádísè. Torí náà, máa ṣe gbogbo ohun tó bá gbà nísinsìnyí kó o lè máa wo àwọn èèyàn yìí bí ẹni tó gbé ayé rí lóòótọ́. Máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn. Àdúrà wa ni pé kí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ ọ̀wọ́n, kẹ́ ẹ sì jọ máa gbádùn ìjọsìn Jèhófà títí láé!