Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú
“Ẹ jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.”—HÉBÉRÙ 6:12.
1, 2. Ojú wo ni alábòójútó arìnrìn-àjò kan fi wo àwọn adúróṣinṣin tí Bíbélì sọ ìtàn wọn? Kí nìdí tí wọ́n fi máa jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà?
LẸ́YÌN tí arábìnrin kan gbọ́ àsọyé tí alábòójútó arìnrìn-àjò kan tó jẹ́ àgbàlagbà sọ, ó ní: “Ó ń sọ̀rọ̀ àwọn tí Bíbélì sọ ìtàn wọn bí ẹni pé ó ti ń bá wọn ṣọ̀rẹ́ tipẹ́tipẹ́.” Òótọ́ ni ohun tí arábìnrin yìí kíyè sí, torí pé arákùnrin náà ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ọ̀pọ̀ ọdún ó sì ti fi kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Tó bá wá ń sọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Bíbélì fi hàn pé wọ́n lo ìgbàgbọ́, ńṣe ló máa ń dà bíi pé ọ̀rọ̀ àwọn tó ti ń bá ṣọ̀rẹ́ láti kékeré ló ń sọ.
2 Tó o bá ní ọ̀pọ̀ lára àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn yẹn lọ́rẹ̀ẹ́, ó dájú pé àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà lo ní yẹn. Ṣó o mọ̀ wọ́n débi pé o lè máa wò wọ́n bí ọ̀rẹ́ rẹ? Wo bó ṣe máa rí ká ní o lè bá wọn rìn, kó o bá wọn sọ̀rọ̀, kó o máa wà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin àti obìnrin bíi Nóà, Ábúráhámù, Rúùtù, Èlíjà àti Ẹ́sítérì kó o lè túbọ̀ mọ̀ wọ́n! Ronú nípa bí ayé rẹ ṣe máa rí ká ní wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ. Sì wá wo bí wàá ṣe mọyì ìmọ̀ràn àti ìṣírí tí wọ́n máa fún ẹ tó!—Ka Òwe 13:20.
3. (a) Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Bíbélì sọ pé wọ́n lo ìgbàgbọ́, báwo ló ṣe lè ṣe wá láǹfààní? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
3 Nígbà “àjíǹde àwọn olódodo,” a máa ní irú àjọṣe yẹn pẹ̀lú wọn, ìyẹn sì máa ṣe wá láǹfààní tó pọ̀. (Ìṣe 24:15) Àmọ́ ní báyìí, tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Bíbélì sọ pé wọ́n lo ìgbàgbọ́, ó ṣì lè ṣe wá láǹfààní. Lọ́nà wo? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa ní ìdáhùn tó lè ràn wá lọ́wọ́, ó ní: “Ẹ jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.” (Héb. 6:12) Bá a ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ yìí, ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ìbéèrè tí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù lè mú kó sọ sí wa lọ́kàn: Kí ni ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí gan-an? Kí nìdí tá a fi nílò ìgbàgbọ́? Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó lo ìgbàgbọ́ láyé àtijọ́?
Ohun Tí Ìgbàgbọ́ Jẹ́ àti Ìdí Tá A Fi Nílò Rẹ̀
4. Kí ni àwọn èèyàn sábà máa ń rò pé ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí? Kí nìdí tí èrò wọn kò fi tọ̀nà?
4 Ìgbàgbọ́ jẹ́ ànímọ́ tó fani lọ́kàn mọ́ra. Ọwọ́ tó ṣe pàtàkì gan-an ni àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn nínú ìwé yìí fi mú ìgbàgbọ́. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fojú kéré ìgbàgbọ́. Wọ́n rò pé ohun tó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn kàn gbà pé ohun kan jẹ́ òótọ́ láìsí ẹ̀rí kankan. Àmọ́, èrò wọn kò tọ̀nà. Tá a bá sọ pé ẹnì kan ní ìgbàgbọ́, kò túmọ̀ sí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ rọrùn láti tàn jẹ, torí pé inú ewu ni ẹni tó bá rọrùn láti tàn jẹ wà. Ìgbàgbọ́ kì í kàn ṣe bí nǹkan ṣe rí lára Ják. 2:19.
ẹni, torí pé bí nǹkan ṣe rí lára ẹni máa ń yí pa dà. Ìgbàgbọ́ sì kọjá pé kéèyàn gbà pé òótọ́ ni nǹkan, torí pé kò tó láti wulẹ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà. Kódà, “àwọn ẹ̀mí èṣù . . . gbà gbọ́, wọ́n sì fi ẹ̀rù wárìrì.”—5, 6. (a) Àwọn nǹkan méjì tí a kò lè rí wo ni ìgbàgbọ́ wa dá lé? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí ìgbàgbọ́ wa fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó? Sọ àpẹẹrẹ kan.
5 Ojúlówó ìgbàgbọ́ ju ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ nípa rẹ̀ lọ. Ǹjẹ́ o rántí ohun tí Bíbélì sọ pé ó jẹ́? (Ka Hébérù 11:1.) Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ohun méjì tí a kò lè rí ni ìgbàgbọ́ dá lé. Lákọ̀ọ́kọ́, ó dá lórí àwọn ohun gidi tó wà nísinsìnyí tí ‘a kò rí.’ Bí àpẹẹrẹ, a kò lè fi ojú wa rí Jèhófà Ọlọ́run, Ọmọ rẹ̀ tàbí Ìjọba Ọlọ́run tó ti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀run báyìí. Àmọ́, ó dájú pé wọ́n wà. Nǹkan kejì tí ìgbàgbọ́ wa dá lé ni “àwọn ohun tí a ń retí,” ìyẹn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò tíì wáyé. Ní báyìí, a kò tíì lè rí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ó máa wà lábẹ́ Ìjọba òun. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ìgbàgbọ́ tá a ní nínú irú àwọn ohun gidi bẹ́ẹ̀ àti nínú àwọn ohun tá à ń retí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀?
6 Rárá o! Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ojúlówó ìgbàgbọ́ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Nígbà tó sọ pé ìgbàgbọ́ ni “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú,” ó lo ọ̀rọ̀ tó tún lè túmọ̀ sí “ìwé ẹ̀rí jíjẹ́ oníǹkan.” Jẹ́ ká sọ pé ẹnì kan fẹ́ fún ẹ ní ilé kan. Ó lè fi ìwé ilé náà lé ẹ lọ́wọ́, kó wá sọ pé, “Ilé rẹ tuntun rèé o.” Ó dájú pé kì í ṣe orí ìwé yẹn ló retí pé kó o máa gbé; ohun tó ní lọ́kàn ni pé níwọ̀n ìgbà tí ìwé ilé náà bá ti wà lọ́wọ́ rẹ, ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro ló jẹ́ lábẹ́ òfin pé ìwọ lo ni ilé náà; ìwé yẹn gan-an ló dúró fún ilé náà. Bákan náà, ìgbàgbọ́ tá a ní mú kó dá wa lójú pé gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ní ìmúṣẹ.
7. Kí ni ojúlówó ìgbàgbọ́?
7 Nítorí náà, ojúlówó ìgbàgbọ́ ni pé kí àwọn ohun tá a mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run dá wa lójú gbangba débi tí kò fi ní sí nǹkan tó lè mú ká ṣiyè méjì nípa wọn, torí pé ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ wà fún wọn. Ìgbàgbọ́ ń mú ká máa wo Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi Baba tó nífẹ̀ẹ́ wa, ká sì gbà pé gbogbo ìlérí rẹ̀ ló máa ní ìmúṣẹ. Ṣùgbọ́n ojúlówó ìgbàgbọ́ ò mọ síbẹ̀. Ńṣe ló dà bí ohun alààyè tá a gbọ́dọ̀ máa bọ́ kó lè máa wà láàyè nìṣó. A gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé a ní ojúlówó ìgbàgbọ́. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wa máa kú.—Ják. 2:26.
8. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká ní ìgbàgbọ́?
8 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká ní ìgbàgbọ́? Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ mú ká rí bó ṣe pọn dandan tó pé ká ní ìgbàgbọ́. (Ka Hébérù 11:6.) Tá ò bá ní ìgbàgbọ́, a kò lè sún mọ́ Jèhófà, a kò sì lè mú inú rẹ̀ dùn. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká ní ìgbàgbọ́ ká tó lè ṣe ojúṣe tó ṣe pàtàkì jù lọ, tó sì wuyì jù lọ fún ẹ̀dá olóye èyíkéyìí. Ìyẹn ni pé ká sún mọ́ Baba wa ọ̀run, Jèhófà, ká sì máa yìn ín lógo.
9. Kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ó mọ bá a ṣe nílò ìgbàgbọ́ tó?
9 Jèhófà mọ bá a ṣe nílò ìgbàgbọ́ tó. Heb. 13:7) Ó tún fún wa ní àpẹẹrẹ púpọ̀ sí i. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀,” ìyẹn àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó gbé ayé nígbà àtijọ́, tí wọ́n sì fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè máa lo ìgbàgbọ́. (Héb. 12:1) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó lo ìgbàgbọ́ ló ṣì wà tí Pọ́ọ̀lù ò dárúkọ wọn nínú Hébérù orí 11. Bíbélì kún fọ́fọ́ fún ojúlówó ìtàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin, lọ́mọdé lágbà, tí ipò wọn yàtọ̀ síra, àmọ́ tí wọ́n lo ìgbàgbọ́, tá a sì lè rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ lára wọn nínú ayé tí àwọn èèyàn ò ti ní ìgbàgbọ́ yìí.
Ìdí nìyẹn tó fi fún wa ní àwọn èèyàn tí àpẹẹrẹ wọn máa kọ́ wa láti ní ìgbàgbọ́, ká sì máa lò ó. Ó fi àwọn ọkùnrin tí ìgbàgbọ́ wọn jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ jíǹkí ìjọ, àwọn ló sì ń mú ipò iwájú. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé ká “máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn.” (Báwo La Ṣe Lè Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Míì Tó Lo Ìgbàgbọ́?
10. Báwo ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè mú ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Bíbélì sọ pé wọ́n lo ìgbàgbọ́?
10 A ò lè fìwà jọ ẹnì kan láìjẹ́ pé a kọ́kọ́ kíyè sí i dáadáa. Bó o ṣe ń ka ìwé yìí lọ, wàá rí i pé ọ̀pọ̀ ìwádìí la ti ṣe kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó lo ìgbàgbọ́ yìí. Ó máa dára gan-an tí ìwọ náà bá ṣe ìwádìí síwájú sí i. Nígbà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, fi àwọn ohun èlò ìwádìí tó o ní lọ́wọ́ walẹ̀ jìn nínú Bíbélì. Bó o ṣe ń ṣe àṣàrò lórí ohun tó o kọ́, gbìyànjú láti ronú nípa bí nǹkan ṣe rí nígbà tí ìtàn inú Bíbélì náà ṣẹlẹ̀ àti ibi tó ti ṣẹlẹ̀. Jẹ́ kó dà bíi pé o wà níbẹ̀, pé ò ń rí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ náà, o sì ń gbọ́ àwọn ìró àti òórùn tó wà níbẹ̀. Ní pàtàkì, fi òye mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn èèyàn tó wà nínú ìtàn náà. Bó o ṣe ń fi ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ní ìgbàgbọ́ yìí ro ara rẹ wò, ńṣe ló máa dà bíi pé o rí wọn sójú, wàá sì túbọ̀ mọ̀ wọ́n dáadáa. Kódà, díẹ̀ lára wọn lè wá dà bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ọ̀wọ́n tó pẹ́ tẹ́ ẹ ti ń bára yín bọ̀.
11, 12. (a) Kí ló lè mú kó o túbọ̀ mọ Ábúrámù àti Sáráì dunjú? (b) Báwo lo ṣe lè jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ Hánà, Èlíjà tàbí Sámúẹ́lì?
11 Tó bá ti wá di pé o mọ̀ wọ́n dunjú, wàá fẹ́ láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé ò ń ronú bóyá kó o gba iṣẹ́ àyànfúnni tuntun kan. Ká ní Jèhófà pè ẹ́ nípasẹ̀ ètò rẹ̀ pé kó o mú iṣẹ́ ìsìn rẹ gbòòrò sí i lọ́nà kan. Bóyá wọ́n ní kó o lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù kan tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ní kánjúkánjú, tàbí kí wọ́n sọ pé kó o gbìyànjú láti máa wàásù lọ́nà kan tó yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀ tàbí lọ́nà tó o rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Bó o ṣe ń ronú lórí iṣẹ́ àyànfúnni náà, tó o sì ń gbàdúrà nípa rẹ̀, ǹjẹ́ kò ní dáa kó o ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ Ábúrámù? Òun àti Sáráì múra tán láti fi ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ tó wà ní ìlú Úrì sílẹ̀, ìyẹn sì mú kí wọ́n rí ìbùkún gbà lọ́pọ̀lọpọ̀. Bó o bá ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, ìwọ náà á wá rí i pé o ti wá mọ̀ wọ́n dáadáa báyìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
12 Bákan náà, ká ní ẹnì kan tó mọ̀ ẹ́ dáadáa
hùwà àìdáa sí ẹ, tí ìyẹn sì mú kó o rẹ̀wẹ̀sì, kódà tó tún ṣe ẹ́ bíi pé kó o jókòó sílé kó o má lọ sí ìpàdé mọ́ ńkọ́? Tó o bá ronú lórí àpẹẹrẹ Hánà àti bí kò ṣe dẹ́kun láti máa sin Jèhófà torí ìwà ìkórìíra tí Pẹ̀nínà hù sí i, ìyẹn á jẹ́ kó o ṣe ìpinnu tó tọ́, ó sì tún lè mú kí Hánà wá dà bí ọ̀rẹ́ rẹ àtàtà. Bákan náà, tó o bá rò pé o kò já mọ́ nǹkan kan, tó o sì ń rẹ̀wẹ̀sì, o lè rí i pé ọ̀rọ̀ rẹ jọ ti Èlíjà bó o bá ṣe ń kà nípa ìṣòro tó ní àti bí Jèhófà ṣe tù ú nínú. Àwọn ọ̀dọ́ tí àwọn ọmọléèwé wọn tó jẹ́ oníwàkiwà ń fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ńkọ́? Àwọn náà lè rí i pé ńṣe ni ọ̀rọ̀ àwọn rí bíi ti Sámúẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó ṣe láìka gbogbo ìwà burúkú tí àwọn ọmọ Élì ń hù nínú àgọ́ ìjọsìn sí.13. Tó o bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹnì kan tí Bíbélì sọ pé ó ní ìgbàgbọ́, ṣé ìyẹn ti sọ ẹ́ di ẹni tí kò lè dá ìpinnu ṣe nìyẹn? Ṣàlàyé.
13 Tó o bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ yìí, ṣé o ti di ẹni tí kò lè dá ìpinnu ṣe nìyẹn? Rárá o! Má ṣe gbàgbé pé Jèhófà ló gbà wá níyànjú nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó ní ìgbàgbọ́. (1 Kọ́r. 4:16; 11:1; 2 Tẹs. 3:7, 9) Yàtọ̀ síyẹn, a rí lára àwọn tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn nínú ìwé yìí tó jẹ́ pé ńṣe ni àwọn náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn míì tó ti lo ìgbàgbọ́ ṣáájú ìgbà tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, a máa rí i ní Orí 17 nínú ìwé yìí pé Màríà fa àwọn ọ̀rọ̀ Hánà yọ nígbà tó ń sọ̀rọ̀. Èyí fi hàn kedere pé Màríà rí àpẹẹrẹ Hánà bí èyí tó yẹ kí òun tẹ̀ lé. Ṣé ìyẹn wá fi hàn pé ìgbàgbọ́ Màríà kò lágbára tó? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni àpẹẹrẹ Hánà ran Màríà lọ́wọ́ kí òun náà lè ní ìgbàgbọ́, kó sì ṣe orúkọ rere fún ara rẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run.
14, 15. Sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó wà nínú ìwé yìí. Báwo la ṣe lè lo ìwé yìí lọ́nà tó máa ṣe wá láǹfààní?
14 Ńṣe la kọ ìwé yìí kó bàa lè fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun. Ìwé yìí jẹ́ àkójọ ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn,” tá a gbé jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ láàárín ọdún 2008 sí ọdún 2013. Àmọ́ a ti ṣe àtúnṣe àwọn àpilẹ̀kọ náà, a sì ti fi àwọn nǹkan tuntun díẹ̀ kún wọn. Orí kọ̀ọ̀kan ní àwọn ìbéèrè tá a lè fi jíròrò rẹ̀, ká sì rí bá a ṣe lè fi àwọn kókó tó wà níbẹ̀ sílò. Ọ̀pọ̀ àwòrán mèremère tó pèsè ìsọfúnni kíkún la ṣẹ̀ṣẹ̀ yà sínú ìwé yìí. A ti ṣe àtúnṣe àwọn tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà tẹ́lẹ̀ kí wọ́n lè tóbi sí i, kí wọ́n sì túbọ̀ fani mọ́ra. A tún fi àwọn nǹkan míì tó máa wúlò kún un, irú bí àtẹ tó fi àwọn déètì pàtàkì hàn àti àwọn àwòrán ilẹ̀. A ṣe ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn lọ́nà tá a fi lè lò ó fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìdílé àti nínú ìjọ. Ó sì lè wu ọ̀pọ̀ àwọn onídìílé pé kí wọ́n jùmọ̀ máa ka àwọn ìtàn inú ìwé náà sókè ketekete.
15 Ǹjẹ́ kí ìwé yìí ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní ìgbàgbọ́ bíi ti àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin nígbà àtijọ́. Àdúrà wa sì ni pé kí ìgbàgbọ́ rẹ máa pọ̀ sí i bó o ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Baba rẹ ọ̀run, Jèhófà.