Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú
ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ ni Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Ọwọ́ rẹ̀ ni ìwàláàyè wa ìsinsìnyí àti ti ọjọ́ iwájú wà. Ó lágbára láti sanni lẹ́san rere, ó sì lágbára láti fìyà jẹni. Ó lágbára láti fúnni ní ìyè, ó sì lágbára láti gbà á. Bí a bá rí ojú rere rẹ̀, a ó ṣe àṣeyọrí sí rere; bí èèyàn ò bá rí ojú rere rẹ̀, a jẹ́ pé ó parí fónítọ̀hún nìyẹn. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí ìjọsìn wa ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀!
Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn ń gbà jọ́sìn. Bí ìsìn bá dà bí ọ̀nà, ǹjẹ́ gbogbo ọ̀nà ìjọsìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà? Rárá o, kì í ṣe gbogbo wọn. Jésù, tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run fi hàn pé ọ̀nà méjì péré ní gbogbo wọ́n pín sí. Ó sọ pé: “Aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.”—Mátíù 7:13, 14.
Oríṣi ìsìn méjì péré ló wà: ọ̀kan ń sinni lọ sí ìyè, èkejì sì ń sinni lọ sí ìparun. Ohun tí ìwé pẹlẹbẹ yìí wà fún ni pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.