Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 9

Ìsìn Tòótọ́ Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní Títí Láé!

Ìsìn Tòótọ́ Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní Títí Láé!

1. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí a bá “sún mọ́ Ọlọ́run”?

JÈHÓFÀ nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń sìn ín. Bí o bá ń sin Jèhófà, yóò bù kún ọ nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.

2. Báwo la ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run, báwo sì nìyẹn ṣe máa ní ipa lórí àdúrà wa?

2 Láti sún mọ́ Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí o sì máa fi í sílò. Nígbà tí o bá gbàdúrà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jèhófà, yóò fetí sí àwọn àdúrà rẹ yóò sì dáhùn wọn. Kristẹni àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí [Ọlọ́run], pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa. Síwájú sí i, bí a bá mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohun yòówù tí a ń béèrè, a mọ̀ pé dájúdájú a óò rí àwọn ohun tí a béèrè gbà níwọ̀n bí a ti béèrè wọn lọ́wọ́ rẹ̀.”—1 Jòhánù 5:14, 15.

3-7. Báwo la ṣe lè jèrè ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, báwo ló sì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

3 Síwájú sí i, bí o ṣe ń sún mọ́ Ọlọ́run, yóò fún ọ ní ọgbọ́n tó o fi máa bójú tó àwọn ìgbòkègbodò rẹ ojoojúmọ́. Bíbélì sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run.”—Jákọ́bù 1:5.

4 Báwo ni ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Lọ́nà kan, ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn nǹkan tí inú Jèhófà kò dùn sí. Wàá tún lè mọ ìdí tí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn kò fi tọ̀nà àti ohun tí o lè ṣe láti yàgò fún ṣíṣe wọ́n. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ lè pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń bá àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò fínra. Bí àpẹẹrẹ, ṣíṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run pé ká yẹra fún ìṣekúṣe ń pa àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ́ kúrò lọ́wọ́ oyún tí a kò fẹ́, àwọn àìsàn tí ìbálòpọ̀ ń kó ranni àti ìgbéyàwó aláìláyọ̀ tàbí ìgbéyàwó tí ó tú ká.

5 Kí tún ni ọgbọ́n tí Ọlọ́run ń fúnni lè ṣe fún ọ? Ó lè jẹ́ kí o gbádùn ìgbésí ayé dáadáa. Ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nínú àwọn ọ̀ràn pàtàkì, bí ìṣúnwóná. Wàá lè máa lépa àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe, wàá sì lè yàgò fún lílépa àwọn ohun tí kò ní tọ́jọ́.

6 Ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ìgbésí ayé ìdílé rẹ yóò túbọ̀ láyọ̀. Yóò ṣeé ṣe fún ọ láti bá àwọn ẹlòmíràn dọ́rẹ̀ẹ́ lọ́nà tó gbámúṣé tí yóò sì tọ́jọ́, yóò sì tún mú kí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún ọ, àní títí kan àwọn tí kì í sin Ọlọ́run pàápàá.

7 Síwájú sí i, níní ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run yóò mú kí èrò rẹ nípa ìgbésí ayé túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro àti ìjákulẹ̀ inú ìgbésí ayé. Wàá tún ní èrò rere tó gún régé nípa ọjọ́ ọ̀la. Èrò rere yìí ni yóò wá mú kí ìlera rẹ túbọ̀ sunwọ̀n sí i, kí ìrònú rẹ sì túbọ̀ jí pépé.—Òwe 14:30; Aísáyà 48:17.

8. Bí o bá ń sin Ọlọ́run, kí ni o ò ní máa bẹ̀rù?

8 Bí o bá ń sin Ọlọ́run tòótọ́, wàá bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀rù tó máa ń ba àwọn tí kò sìn ín. Nítorí pé o mọ̀ pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun nínú sàréè, o ò ní máa bẹ̀rù àwọn tó ti kú. Nítorí pé o ní ìgbọ́kànlé nínú ìlérí Ọlọ́run láti jí àwọn òkú dìde, o ò ní bẹ̀rù ikú. Níwọ̀n bí o sì ti mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ alágbára gbogbo, o ò ní bẹ̀rù àjẹ́ tàbí adáhunṣe.—Jòhánù 8:32.

Àwọn Olódodo Ni Yóò Ni Ilẹ̀ Ayé

9-11. Àwọn ta ni yóò máa gbé inú Párádísè, àwọn ta ni kò ní sí ńbẹ̀?

9 Bí o bá sún mọ́ Ọlọ́run, o ò ní máa bẹ̀rù nípa ọjọ́ ọ̀la. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ níṣàájú, Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀ ìṣòro tí à ń rí lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Jèhófà sọ fún wa pé ìgbà díẹ̀ làwọn nǹkan wọ̀nyí yóò fi wà; Ìjọba Ọlọ́run máa tó sọ ilẹ̀ ayé yìí di Párádísè.—Lúùkù 21:10, 11, 31; 23:43.

10 Kìkì àwọn tó bá sún mọ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń sìn ín ni yóò gbé inú Párádísè. Bíbélì sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

11 Àwọn tó bá ṣorí kunkun, tí wọ́n kọ̀ láti ṣègbọràn sí àwọn òfin òdodo Ọlọ́run yóò pàdánù ìwàláàyè wọn títí láé. (2 Tẹsalóníkà 1:8, 9) Wọn kò ní sí mọ́. Àwọn àti Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ni yóò pa pọ̀ kú ikú ayérayé. (Ìṣípayá 20:10, 14) Ṣùgbọ́n àwọn tó bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, tí wọ́n sì sìn ín yóò rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

Ọjọ́ Ọ̀la Àgbàyanu!

12. Kí ni Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la?

12 Jèhófà ní àwọn nǹkan àgbàyanu nípamọ́ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀! Ìwọ tiẹ̀ wo ohun tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ ná nípa bí ìwàláàyè ṣe máa rí nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé:

  • Ọ̀pọ̀ oúnjẹ yóò wà láti jẹ: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà [tàbí oúnjẹ] yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16.

  • Ilé tó bójú mu yóò wà: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn.”—Aísáyà 65:21.

  • Iṣẹ́ gbígbádùnmọ́ni yóò wà: “Iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò . . . lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán.”—Aísáyà 65:22, 23.

  • Kò ní sí àìsàn: “Kò sí . . . olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

  • Kò ní sí àbùkù ara: “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.”—Aísáyà 35:5, 6.

  • Kò ní sí ìrora, kò ní sí ìbànújẹ́, kò sì ní sí ikú: “[Ọlọ́run] yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.

  • Kò ní sí ogun: “[Ọlọ́run] mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 46:9.

  • Ìyè àìnípẹ̀kun yóò wà: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.

13. Ta ni ẹnì kan ṣoṣo tó lè sọ ayé yìí di Párádísè, kí sì nìdí?

13 Èèyàn ò lè mú irú nǹkan wọ̀nyí wá láé, ṣùgbọ́n Jèhófà lágbára láti ṣe ohunkóhun tó bá sọ pé òun máa ṣe. Kò sí ohunkóhun tó lè dá a dúró pé kí ó má ṣe ohun tó fẹ́ ṣe. Bíbélì sọ pé: “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.”—Lúùkù 1:37.

14. Báwo lo ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí rin ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun?

14 Jèhófà ń lo àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ láti fi fún àwọn èèyàn níbi gbogbo láǹfààní láti “gba ẹnubodè tóóró wọlé,” kí wọ́n sì máa rin ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ǹjẹ́ kí ìwọ pẹ̀lú wà lára àwọn èèyàn aláyọ̀ tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà. Ǹjẹ́ kí o máa ṣe ìsìn tòótọ́, kí o sì gbádùn ìbùkún Jèhófà títí láé!—Mátíù 7:13, 14.