Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 6

Ǹjẹ́ Gbogbo Ẹ̀sìn ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?

Ǹjẹ́ Gbogbo Ẹ̀sìn ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?

1. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí, oríṣi ìsìn méjì wo ló wà?

JÉSÙ sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:13, 14) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, oríṣi ìsìn méjì ló wà: ọ̀kan jẹ́ òótọ́, èkejì jẹ́ èké; ọ̀kan tọ̀nà, èkejì kò tọ̀nà; ọ̀kan lọ síbi ìyè, èkejì lọ síbi ìparun.

2. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé kì í ṣe gbogbo ìsìn ni inú Ọlọ́run dùn sí?

2 Àwọn èèyàn kan rò pé gbogbo ìsìn ni inú Ọlọ́run dùn sí. Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nísàlẹ̀ yìí fi hàn pé ìyẹn kì í ṣòótọ́:

  • “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sin àwọn Báálì àti àwọn ère Áṣítórétì àti àwọn ọlọ́run Síríà àti àwọn ọlọ́run Sídónì àti àwọn ọlọ́run Móábù àti àwọn ọlọ́run àwọn ọmọ Ámónì àti àwọn ọlọ́run àwọn Filísínì. Nítorí náà, wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, wọn kò sì sìn ín. Látàrí èyí, ìbínú Jèhófà ru sí Ísírẹ́lì.” (Àwọn Onídàájọ́ 10:6, 7) Bí a bá ń sin òrìṣà tàbí ọlọ́run èyíkéyìí mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà kò ní tẹ́wọ́ gbà wá.

  • “Àwọn ènìyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi [Ọlọ́run], ṣùgbọ́n ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí mi. Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́.” (Máàkù 7:6, 7) Bí àwọn èèyàn tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run bá ń fi èrò ti ara wọn kọ́ni dípò ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, asán ni ìjọsìn wọn. Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gbà á.

  • “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Ìjọsìn wa gbọ́dọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Èso Tí Ìsìn Èké Ń So

3. Kí ni ọ̀nà kan tí a lè gbà mọ ìsìn tòótọ́ yàtọ̀ sí ìsìn èké?

3 Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ìsìn kan dùn mọ́ Ọlọ́run nínú tàbí kò dùn mọ́ ọn? Jésù sọ pé: “Gbogbo igi rere a máa mú èso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde . . . Ní ti tòótọ́, nígbà náà, nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá àwọn ènìyàn wọnnì mọ̀.” Lọ́rọ̀ mìíràn, bí ìsìn kan bá ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, èso rere ni yóò máa so; ṣùgbọ́n bí ìsìn kan bá ti ọ̀dọ̀ Sátánì wá, èso búburú ni yóò máa so.—Mátíù 7:15-20.

4. Ànímọ́ wo ni àwọn olùjọsìn Jèhófà ní?

4 Ìsìn tòótọ́ máa ń jẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní kejì, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn. Ìdí èyí ni pé Jèhófà fúnra rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́. Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” Báwo ni ìsìn rẹ ṣe bá ọ̀pá ìdiwọ̀n tó wà fún ìsìn tòótọ́ yìí mu tó?—Jòhánù 13:35; Lúùkù 10:27; 1 Jòhánù 4:8.

5. Báwo ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan ṣe ṣàpèjúwe òwò ẹrú ní ilẹ̀ Áfíríkà?

5 Wo òwò ẹrú ní ilẹ̀ Áfíríkà bí àpẹẹrẹ. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The New Encyclopædia Britannica, sọ pé: “Nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìdínlógún [18,000,000 ] àwọn ará Áfíríkà ni wọ́n kó fún àwọn onísìn Ìsìláàmù tó ń ṣe òwò ẹrú láàárín ọdún 650 sí ọdún 1905. Àwọn olówò ẹrú wọ̀nyí wá láti apá ìhà Sàhárà àti Òkun Íńdíà. Ní abala kejì ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún, àwọn ará Yúróòpù bẹ̀rẹ̀ sí ṣòwò yìí ní etíkun ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, nígbà tó sì fi máa di ọdún 1867, wọ́n ti fi ọkọ̀ òkun kó nǹkan bíi mílíọ̀nù méje sí mílíọ̀nù mẹ́wàá àwọn ará Áfíríkà lọ gẹ́gẹ́ bí ẹrú sí Ilẹ̀ Òkèèrè.”

6. Báwo ni ìsìn ṣe lọ́wọ́ nínú òwò ẹrú?

6 Kí ni ìsìn ṣe lákòókò pákáǹleke yẹn ní ilẹ̀ Áfíríkà, nígbà tí wọ́n ń kó àwọn èèyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin àtàwọn ọmọ lọ kúrò ní ilé wọn àti kúrò lọ́dọ̀ ìdílé wọn, tí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè wọ́n, tí wọ́n fi irin gbígbóná sàmì sí wọn lára, tí wọ́n sì rà wọ́n, tí wọ́n tún tà wọ́n bí ẹní ta màlúù? Nínú ìwé ìròyìn Daily Nation ti Nairobi, ní Kẹ́ńyà, Bethwell Ogot kọ̀wé pé: “Àtàwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni àti ti Ìsìláàmù ló máa ń kọ́ni pé ó yẹ kí aráyé wà níṣọ̀kan, ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì ló dá àwùjọ tí wọ́n ti ń múni lẹ́rú tó kún fún ẹ̀tanú kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà sílẹ̀. . . . Ó yẹ ká gbà pé àwọn Mùsùlùmí àtàwọn Kristẹni, àwọn tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé àtàwọn tó wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé àti ayé ojú dúdú ló jọ jẹ̀bi ohun tó fa ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí àwọn ará Áfíríkà fi jìyà lọ́nà tí kò ṣeé fẹnu sọ.”

Ìsìn àti Ogun

7. Ipa wo ni àwọn aṣáájú ìsìn ti kó nínú ogun?

7 Ìsìn èké tún fi àwọn èso jíjẹrà rẹ̀ hàn láwọn ọ̀nà mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sọ pé “kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ,” àwọn aṣáájú ìsìn jákèjádò ayé ti gbárùkù ti ogun, wọ́n sì ti gbé e lárugẹ.—Mátíù 22:39.

Ìsìn èké ti lọ́wọ́ nínú ogun àti òwò ẹrú

8. (a) Báwo ni àwọn aṣáájú ìsìn ṣe dá kún ìpànìyàn nínú àwọn ìjà tó wáyé nílẹ̀ Áfíríkà? (b) Kí ni pásítọ̀ kan sọ nípa àwọn aṣáájú ìsìn lákòókò ogun abẹ́lé ní Nàìjíríà?

8 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé lọ́dún 1994, àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé àtàwọn àlùfáà kan lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn tó wáyé ní Rwanda. Ìsìn tún kó ipa pàtàkì nínú àwọn ìjà mìíràn tó wáyé nílẹ̀ Áfíríkà pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, lákòókò ogun abẹ́lé tí wọ́n ti pa ọ̀pọ̀ èèyàn ní Nàìjíríà, ìsìn níhà ìhín àti ìhà ọ̀hún rọ àwọn èèyàn láti jagun. Bí ogun yẹn ti ń bá a lọ, pásítọ̀ kan sọ pé àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ti “pa iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn tì.” Ó tún sọ pé: “Àwa tá a pe ara wa ní òjíṣẹ́ Ọlọ́run ti di òjíṣẹ́ Sátánì.”

9. Kí ni Bíbélì sọ nípa àwọn òjíṣẹ́ Sátánì?

9 Ohun tí Bíbélì sọ jọ ìyẹn, ó ní: “Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀. Nítorí náà, kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá ń pa ara wọn dà di òjíṣẹ́ òdodo.” (2 Kọ́ríńtì 11:14, 15) Bí ọ̀pọ̀ èèyàn burúkú ṣe máa ń díbọ́n pé ẹni rere ni àwọn, bẹ́ẹ̀ náà ni Sátánì ṣe máa ń díbọ́n, tó sì ń tan àwọn èèyàn jẹ nípa lílo àwọn òjíṣẹ́ tí wọ́n máa ń fara hàn bí olódodo ṣùgbọ́n tí iṣẹ́ burúkú kún ọwọ́ wọn, tó sì jẹ́ pé èso jíjẹrà ni wọ́n ń so.

10. Lọ́nà wo ni àwọn aṣáájú ìsìn ti gbà sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run?

10 Jákèjádò ayé, àwọn aṣáájú ìsìn máa ń wàásù ìfẹ́, àlàáfíà àti inú rere, ṣùgbọ́n ìkórìíra, ogun àti àìṣèfẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n ń hù níwà. Àpèjúwe tí Bíbélì ṣe nípa wọn bá a mu. Ó sọ pé: “Wọ́n polongo ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ wọn.”—Títù 1:16.

Ẹ Jáde Kúrò Nínú “Bábílónì Ńlá”

11. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ìsìn èké?

11 A lè mọ ohun tí Jèhófà rò nípa ìsìn èké tá a bá ka ìwé Ìṣípayá nínú Bíbélì. Níbẹ̀, Bíbélì fi ìsìn èké wé obìnrin ìṣàpẹẹrẹ kan, ìyẹn ni “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣípayá 17:5) Ṣàkíyèsí bí Ọlọ́run ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀:

  • “Aṣẹ́wó ńlá . . . ẹni tí àwọn ọba ilẹ̀ ayé bá ṣe àgbèrè.” (Ìṣípayá 17:1, 2) Dípò kí ìsìn èké jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, ìsìn èké ti tojú bọ ọ̀ràn ìṣèlú, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì ń sọ fún ìjọba pé ohun báyìí báyìí ni kí ó ṣe.

  • “Nínú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́ àti ti gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 18:24) Ìsìn èké ti ṣenúnibíni sí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ó sì ti ṣekú pa wọ́n, òun náà ló sì ń fa kíkú tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ń kú sínú ogun.

  • “Ó ṣe ara rẹ̀ lógo, . . . ó sì gbé nínú fàájì aláìnítìjú.” (Ìṣípayá 18:7) Ìsìn èké ní ọrọ̀ ńláǹlà, èyí tí àwọn aṣáájú rẹ̀ fi ń gbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì.

  • “A ti ṣi gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà nípasẹ̀ iṣẹ́ ìbẹ́mìílò rẹ̀.” (Ìṣípayá 18:23) Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ èké tí ìsìn èké fi ń kọ́ni pé ọkàn kì í kú, ó ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún onírúurú ìbẹ́mìílò àti iṣẹ́ òkùnkùn, ó sì ti dá kún ìbẹ̀rù òkú àti bíbọ àwọn baba ńlá.

12. Ìkìlọ̀ wo ni Bíbélì ṣe fúnni nípa ìsìn èké?

12 Nígbà tí Bíbélì ń kìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n kúrò nínú ìsìn èké, ó sọ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.”—Ìṣípayá 18:4, 5.

13. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ìsìn èké àtàwọn tó ń ṣe é?

13 Lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́, Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé yóò pa run pátápátá. Bíbélì sọ pé: “Ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀, ikú àti ọ̀fọ̀ àti ìyàn, yóò . . . dé ní ọjọ́ kan ṣoṣo, a ó sì fi iná sun ún pátápátá, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alágbára.” (Ìṣípayá 18:8) Láti yẹra fún gbígbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀, a gbọ́dọ̀ fòpin sí gbogbo àjọṣe tí a bá ní pẹ̀lú ìsìn èké, ká má ṣe lọ́wọ́ rárá nínú àwọn àṣà, ayẹyẹ àti ìgbàgbọ́ tí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Ọ̀ràn kánjúkánjú ni o. Ìwàláàyè wa wé mọ́ ọn o!—2 Kọ́ríńtì 6:14-18.