Ẹ̀kọ́ 9
Àwọn Wo Ni Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
Jésù Kristi jẹ́ Ọmọ Jèhófà, òun sì ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, tó nífẹ̀ẹ́ jù lọ. Kí Jésù tó wá gbé lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó ti gbé lọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára. (Jòhánù 17:5) Lẹ́yìn náà, ó wá sórí ilẹ̀ ayé láti kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (Jòhánù 18:37) Ó tún fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn lélẹ̀ láti gba àwọn èèyàn onígbọràn là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 6:23) Ní báyìí, Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ìṣàkóso ti ọ̀run tí yóò mú Párádísè wá sórí ilẹ̀ ayé yìí.—Ìṣípayá 19:16.
Àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Orí ilẹ̀ ayé yìí kọ́ ni àwọn áńgẹ́lì ti gòkè re ọ̀run. Ọlọ́run ti dá wọn sókè ọ̀run kí ó tó dá ilẹ̀ ayé. (Jóòbù 38:4-7) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ áńgẹ́lì ló wà. (Dáníẹ́lì 7:10) Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run wọ̀nyí, tí wọ́n ń bẹ lọ́run, fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Jèhófà.—Ìṣípayá 14:6, 7.
Ọlọ́run tún láwọn ọ̀rẹ́ lórí ilẹ̀ ayé; ẹlẹ́rìí rẹ̀ ló pè wọ́n. Bí ẹnì kan bá ń jẹ́rìí ní ilé ẹjọ́, á sọ ohun tó mọ̀ nípa ẹnì kan tàbí nípa ohun kan. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa Jèhófà àti ète rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. (Aísáyà 43:10) Gẹ́gẹ́ bíi àwọn áńgẹ́lì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Jèhófà. Wọ́n ń fẹ́ kí ìwọ pẹ̀lú jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.