Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ 10

Bí O Ṣe Lè Rí Ẹ̀sìn Tòótọ́

Bí O Ṣe Lè Rí Ẹ̀sìn Tòótọ́

Bí o bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ máa ṣe ẹ̀sìn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Jésù wí pé “àwọn olùjọsìn tòótọ́” yóò sin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú “òtítọ́.” (Jòhánù 4:23, 24) Ọ̀nà kan ṣoṣo tó tọ̀nà ló wà láti sin Ọlọ́run. (Éfésù 4:4-6) Ẹ̀sìn tòótọ́ ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, ẹ̀sìn èké sì ń sinni lọ sí ìparun.—Mátíù 7:13, 14.

O lè mọ ẹ̀sìn tòótọ́ nípa kíkíyè sí àwọn èèyàn tó ń ṣe é. Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ ẹni rere, àwọn olùjọsìn rẹ̀ tòótọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni rere. Gẹ́gẹ́ bí igi ọsàn rere ṣe máa ń so ọsàn àtàtà, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀sìn tòótọ́ ṣe máa ń mú àwọn èèyàn àtàtà jáde.—Mátíù 7:15-20.

Àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà máa ń bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Bíbélì. Wọ́n mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá. Wọ́n máa ń jẹ́ kí ohun tó sọ ṣamọ̀nà wọn, kí ó bá wọn yanjú ìṣòro, kí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:16) Wọ́n máa ń sapá láti fi ohun tí wọ́n ń wàásù rẹ̀ ṣèwà hù.

Àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Jésù fi ìfẹ́ hàn sí àwọn èèyàn nípa kíkọ́ wọn nípa Ọlọ́run, àti nípa mímú àwọn tí ń ṣàìsàn lára dá. Àwọn tí ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ tún máa ń fẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn. Gẹ́gẹ́ bíi ti Jésù, wọn kì í fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn tálákà tàbí àwọn tó wá láti ẹ̀yà mìíràn. Jésù sọ pé ìfẹ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ń fi hàn sí ara wọn làwọn èèyàn yóò fi mọ̀ wọ́n.—Jòhánù 13:35.

Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa ń bọlá fún orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn ni Jèhófà. Bí ẹnì kan bá kọ̀ láti lo orúkọ rẹ, ṣé ẹni yẹn lè jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́? Rárá o! Bí a bá ní ọ̀rẹ́ kan, a máa ń pe orúkọ rẹ̀, a sì máa ń sọ ohun tó dáa nípa ọ̀rẹ́ wa yẹn fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí náà, àwọn tó bá ń fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa lo orúkọ rẹ̀, kí wọ́n sì máa sọ nípa Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn. Jèhófà fẹ́ kí a máa ṣe bẹ́ẹ̀.—Mátíù 6:9; Róòmù 10:13, 14.

Bíi ti Jésù, àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìṣàkóso lókè ọ̀run, tí yóò sọ ilẹ̀ ayé di párádísè. Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa ń sọ ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn.—Mátíù 24:14.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún Bíbélì, wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn. Wọ́n tún máa ń lo orúkọ Ọlọ́run, wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún un, wọ́n sì máa ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé lónìí.