Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ 4

Bó O Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run

Bó O Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run

O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà nípa kíka Bíbélì. Nígbà àtijọ́, Ọlọ́run yan àwọn èèyàn kan pé kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ èrò òun. Ìwé tí wọ́n kọ yẹn la ń pè ní Bíbélì. Lónìí, a ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run nípa kíka Bíbélì. Nítorí pé ọ̀rọ̀, tàbí ìsọfúnni látọ̀dọ̀ Jèhófà ló wà nínú Bíbélì, a tún ń pè é ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A lè gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́ nítorí tí Jèhófà kì í purọ́. “Kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” (Hébérù 6:18) Òtítọ́ ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Jòhánù 17:17.

Bíbélì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye jù lọ tí Ọlọ́run fún wa. Ńṣe ló dà bí lẹ́tà tí bàbá onífẹ̀ẹ́ kọ sí àwọn ọmọ rẹ̀. Ó sọ fún wa nípa ìlérí Ọlọ́run láti yí ilẹ̀ ayé padà sí ibi àgbàyanu kan láti máa gbé—párádísè kan. Ó sọ fún wa nípa ohun tó ṣe nígbà àtijọ́, ohun tó ń ṣe báyìí, àti ohun tí yóò ṣe lọ́jọ́ ọ̀la fún àwọn ọmọ rẹ̀ olùṣòtítọ́. Ó tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro wa, kí a sì láyọ̀.—2 Tímótì 3:16, 17.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run; wọn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ohun tí Bíbélì fi ń kọ́ni. Ṣáà sọ fún wọn pé o fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọn kì í gbowó nítorí rẹ̀. (Mátíù 10:8) Ní àfikún sí i, o lè lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Àwọn ibi ìjọsìn tí a ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba la ti máa ń ṣe àwọn ìpàdé wọ̀nyí. Bí o bá ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, ìmọ̀ tí o ní nípa Ọlọ́run yóò tètè pọ̀ sí i.

O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run láti inú àwọn nǹkan tó dá. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì wí pé: “Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Nígbà tí Jèhófà dá “ọ̀run,” ó dá oòrùn. Kí nìyẹn wá ń sọ fún wa nípa Ọlọ́run? Ó ń sọ fún wa pé Jèhófà ní agbára ńlá. Bí oòrùn ṣe lágbára tóo nì, Òun nìkan ṣoṣo ló lè dá a. Ó tún ń sọ fún wa pé Jèhófà jẹ́ ọlọgbọ́n, nítorí nínú ọgbọ́n rẹ̀ ló fi lè dá oòrùn tí agbára rẹ̀ kì í tán, tó ń mú ooru jáde, tó sì ń pèsè ìmọ́lẹ̀.

Ohun tí Jèhófà dá ń fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ronú nípa gbogbo onírúurú èso tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti pèsè irú èso kan ṣoṣo péré fún wa, tàbí kó má tiẹ̀ pèsè èyíkéyìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà fún wa lónírúurú èso lọ́pọ̀ yanturu, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìrísí wọn, wọ́n tóbi ju ara wọn lọ, àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra, adùn wọn sì tún yàtọ̀ síra. Èyí ń fi hàn pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún jẹ́ ọ̀làwọ́ gan-an, ó ń gbọ́ tiwa, ó sì jẹ́ onínúure.—Sáàmù 104:24.