Ẹ̀kọ́ 11
Kọ Ẹ̀sìn Èké Sílẹ̀!
Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò fẹ́ kí o sin Ọlọ́run. Wọ́n fẹ́ láti yí gbogbo èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, bó bá ṣeé ṣe. Báwo ni wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti ṣe èyí? Ẹ̀sìn èké jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń lò. (2 Kọ́ríńtì 11:13-15) Ẹ̀sìn tí kò bá ti fi òtítọ́ inú Bíbélì kọ́ni jẹ́ èké. Ńṣe ni ẹ̀sìn èké dà bí ayédèrú owó—ó lè dà bí owó gidi, ṣùgbọ́n kò wúlò rárá. Ó lè kó wàhálà bá ọ.
Ẹ̀sìn èké kò lè tẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́, lọ́rùn láé. (Sáàmù 31:5) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, àwùjọ àwọn ẹlẹ́sìn kan wà tí wọ́n fẹ́ pa á. Wọ́n rò pé ọ̀nà tí àwọn ń gbà jọ́sìn ló tọ́. Wọ́n sọ pé: “Baba kan ni àwa ní, Ọlọ́run.” Ṣé Jésù gbà bẹ́ẹ̀? Rárá o! Ó sọ fún wọn pé: “Láti ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá.” (Jòhánù 8:41, 44) Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé Ọlọ́run làwọ́n ń jọ́sìn, ṣùgbọ́n ní ti gidi, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ni wọ́n ń sìn!—1 Kọ́ríńtì 10:20.
Gẹ́gẹ́ bí igi tó ti bàjẹ́ kò ti lè so èso tó dára, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀sìn èké ṣe máa ń mú àwọn èèyàn tó máa ń hùwà ibi jáde. Ìwà burúkú táwọn èèyàn ń hù ló mú kí ayé kún fún ìṣòro. Ìṣekúṣe, ìjà, olè jíjà, ìnilára, ìṣìkàpànìyàn, àti ìfipábánilòpọ̀ wà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe nǹkan búburú wọ̀nyí ló lẹ́sìn tí wọ́n ń ṣe, ṣùgbọ́n ẹ̀sìn wọn kò sún wọn láti máa ṣe rere. Wọn ò lè jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, àyàfi bí wọ́n bá jáwọ́ nínú ìwà búburú.—Ẹ̀sìn èké ń kọ́ àwọn èèyàn láti máa darí àdúrà sí ère. Ọlọ́run sọ pé a kò gbọdọ̀ darí àdúrà sí ère. Èyí bọ́gbọ́n mu. Ṣé inú ìwọ náà á dùn tó bá jẹ́ pé àwòrán rẹ nìkan lẹnì kan máa ń bá sọ̀rọ̀ tí kì í sì í bá ìwọ alára sọ̀rọ̀ rárá? Ṣé ẹni yẹn lè jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tòótọ́? Rárá, kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Jèhófà fẹ́ kí àwọn èèyàn máa bá òun sọ̀rọ̀, kì í ṣe pé kí wọ́n máa bá ère tàbí àwòrán, tí kò lẹ́mìí sọ̀rọ̀.—Ẹ́kísódù 20:4, 5.
Ẹ̀sìn èké ń kọ́ni pé kò burú láti pa àwọn ẹlòmíràn lákòókò ogun. Jésù sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run yóò fẹ́ràn ara wọn. A kì í pa àwọn èèyàn tí a bá fẹ́ràn. (Jòhánù 13:35) Kódà, kò tọ́ ká pa àwọn ẹni búburú pàápàá. Nígbà tí àwọn ọ̀tá Jésù wá mú un, kò jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun jà láti dáàbò bo òun.—Mátíù 26:51, 52.
Ẹ̀sìn èké ń kọ́ni pé a óò dá àwọn ẹni ibi lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Ṣùgbọ́n, Bíbélì kọni pé ikú lẹ̀ṣẹ̀ máa ń yọrí sí. (Róòmù 6:23) Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́. Ǹjẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ yóò wá máa dá àwọn èèyàn lóró títí láé? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ kọ́! Nínú Párádísè, ẹ̀sìn kan ṣoṣo ni yóò wà, ẹ̀sìn tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà. (Ìṣípayá 15:4) Gbogbo ẹ̀sìn táa gbé karí irọ́ Sátánì yóò ti pa rẹ́.