Ẹ̀kọ́ 3
Ó Yẹ Kí O Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run
Láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ mọ orúkọ rẹ, ǹjẹ́ wọ́n sì máa ń fi pè ọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run ń fẹ́ kí o mọ orúkọ òun pẹ̀lú, kí o sì máa fi pe òun. Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18; Mátíù 6:9) O tún gbọ́dọ̀ mọ ohun tó fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́. O gbọ́dọ̀ mọ àwọn ẹni tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run àti àwọn tó jẹ́ ọ̀tá rẹ̀. Ó máa ń gba àkókò, ká tó lè mọ ẹnì kan dáadáa. Bíbélì sọ pé, ó bọ́gbọ́n mu láti ya àkókò sọ́tọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà.—Éfésù 5:15, 16.
Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa ń ṣe ohun tó ń tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Ronú nípa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Bí o bá ń hùwà tí ò dáa sí wọn, tí o sì ń ṣe ohun tí wọn ò fẹ́, ṣé wọ́n á tún máa bá ẹ ṣọ̀rẹ́? Rárá o! Lọ́nà kan náà, bí o ba fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó ń dùn mọ́ Ọlọ́run nínú.—Jòhánù 4:24.
Kì í ṣe gbogbo ẹ̀sìn ní ń sọni di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Jésù, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ jù lọ fún Ọlọ́run, sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà méjì. Ọ̀nà kan fẹ̀, tìrítìrí sì làwọn èèyàn ń wọ́ lójú ọ̀nà náà. Ìparun lọ̀nà ọ̀hún sì lọ. Ọ̀nà kejì tóóró, ṣùgbọ́n kéréje làwọn èèyàn tí ń rìn ín. Ìyè àìnípẹ̀kun lọ̀nà yìí lọ. Èyí túmọ̀ sí pé bí o bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ mọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbà jọ́sìn rẹ̀.—Mátíù 7:13, 14.