Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ 2

Ọlọ́run Lọ̀rẹ́ Tó Dára Jù Lọ Tó O Lè Ní

Ọlọ́run Lọ̀rẹ́ Tó Dára Jù Lọ Tó O Lè Ní

Kò sóhun tó lè dáa tó pé kóo dọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ọlọ́run á kọ́ ẹ bí o ó ṣe di aláyọ̀, kí ayé rẹ sì tòrò; á sì gbà ọ́ lọ́wọ́ àìmọye ìgbàgbọ́ èké àti àwọn àṣà tí ń pani lára. Á máa tẹ́tí sí àdúrà rẹ. Á mú kí ọkàn rẹ balẹ̀ tí ẹ̀rù ò sì ní máa bà ọ́. (Sáàmù 71:5; 73:28) Ọlọ́run yóò tì ọ́ lẹ́yìn nígbà ìṣòro. (Sáàmù 18:18) Ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun ni Ọlọ́run sì nawọ́ rẹ̀ sí ọ.—Róòmù 6:23.

Bóo ṣe ń sún mọ́ Ọlọ́run ni wàá máa sún mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Àwọn pẹ̀lú á di ọ̀rẹ́ rẹ. Ní tòótọ́, ńṣe ni wọ́n máa dà bíi ọmọ ìyá àtọmọ bàbá rẹ. Inú wọ́n á dùn láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́, wọ́n á sì fún ẹ níṣìírí.

Ọlọ́run jù wá lọ. Bóo ṣe ń gbìyànjú láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ lóye kókó pàtàkì kan. Bíbá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́ kò jọ bí ìgbà táà ń bá ẹgbẹ́ ẹni ṣọ̀rẹ́. Ọlọrun kì í ṣe ẹgbẹ wa rárá. Ó gbọ́n jù wá lọ fíìfíì, agbára rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi ju tiwa lọ. Òun gan-an ni Olùṣàkóso wa. Nítorí náà, bí a bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ rẹ̀, a gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí i, kí a sì máa ṣe ohun tó bá sọ pé kí a ṣe. Ire-ire ni èyí yóò máa já sí fún wa nígbà gbogbo.—Aísáyà 48:18.