Ẹ̀kọ́ 17
Bó O Bá Fẹ́ Kẹ́nì Kan Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Rẹ, Ìwọ Náà Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Rẹ̀
Ìfẹ́ ni ìpìlẹ̀ ìbánidọ́rẹ̀ẹ́. Bóo bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà sí, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tí o ní sí i yóò máa pọ̀ sí i. Bí ìfẹ́ tí o ní sí Ọlọ́run ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ rẹ láti máa sìn ín yóò ṣe máa pọ̀ sí i. Èyí yóò sún ọ láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. (Mátíù 28:19) Nípa dídara pọ̀ mọ́ ìdílé aláyọ̀ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run títí láé. Kí lo gbọ́dọ̀ ṣe?
O gbọ́dọ̀ fi hàn pé o fẹ́ràn Ọlọ́run nípa ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀. “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 Jòhánù 5:3.
Máa fi ohun tí o ń kọ́ sílò. Jésù sọ ìtàn kan tó ṣàpèjúwe èyí. Ọlọgbọ́n ọkùnrin kan kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta. Òmùgọ̀ ọkùnrin kan kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. Nígbà tí ìjì líle dé, ilé tí wọ́n kọ́ sórí àpáta kò wó, ṣùgbọ́n ilé tí wọ́n kọ́ sórí iyanrìn wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ. Jésù sọ pé àwọn tí wọ́n ń gbọ́ ẹ̀kọ́ òun, tí wọ́n sì ń ṣe wọ́n, dà bí ọlọgbọ́n ọkùnrin yẹn tó kọ́lé sórí àpáta. Ṣùgbọ́n àwọn tó bá fetí sí àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, tí wọ́n ò sì ṣe wọ́n, dà bí òmùgọ̀ ọkùnrin yẹn tó kọ́lé sórí iyanrìn. Ta lo fẹ́ jọ nínú wọn?—Mátíù 7:24-27.
Ìbatisí. “Kí a batisí rẹ, kí o sì wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù nípa kíké tí o bá ń ké pe orúkọ rẹ̀.”—Ìṣe 22:16.
Máa jọ́sìn Ọlọ́run tọ́kàntara. “Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.”—Kólósè 3:23.